Itafaaji

Ariya ṣiṣe nilẹ Yoruba

Maa jaye oni o,
Mi o m’ẹyin ọla o,
maa jaye oni o,
mi o m’ẹyin ọla o

Ẹsẹ orin ti gbaju-gbaja onkọrin Juju nni, Sunday Iṣọla Adegẹye, ti gbogbo aye mọ si King Sunny Ade, kọ yii wa lara ọgọọrọ orin ti wọn fi maa n side ariya nilẹ Yoruba.

O fẹrẹ ma si olorin kan nilẹ Yoruba ti ko ni i mẹnu kan ariya ninu orin tabi ilu rẹ. Koda awọn olorin ẹmi, tabi olorin ẹsin ati awọn orin ibilẹ maa n sọrọ nipa ariya ṣiṣe.

 

Bakan naa ni Yoruba ni ọkan-o-jọkan akanlo-ede, àpólà ọrọ ati aṣa to fihan bi wọn ti fẹran ariya to, bi ikun ṣe fẹran ẹpa, ti ọbọ ko le fi ọgẹdẹ ṣere, bẹẹ ni ariya ṣiṣe nilẹ Yoruba ṣe ri. Lara akanlo ede ati ọrọ bẹẹ ni ‘ode ariya’, pati, owanbẹ, faaji, faaji famia, faaji-n-ṣan, ariya-o-lopin, mo-gbọ-mo-ya, inawo, ayẹyẹ, oninawo, ṣabọ-jọ, pọpọ-ṣinṣin, abolode-fẹ-ẹ-loju, aṣọ-ẹbi, ankoo, aṣọ ẹgbẹjọda, oo-wọ-ankara-oo-jẹ-sẹmo, agbo ere, nawo felere, lẹ owo melere loju ati bẹẹ bẹẹ lọ. 

Oriṣiiriṣii nnkan lo maa n ṣokunfa ariya nilẹ Yoruba, o si pọ diẹ. Lara ariya ni ikomọjade ti wọn tun n pe ni isọmọlorukọ, oku ṣiṣe, igbeyawo, idana, mọ-mi-n-mọ-ọ, iṣile, didawọọ ọkọ tuntun, ṣiṣi ileeṣẹ tabi okoowo tuntun, fifi ipilẹ ile lelẹ, oye jijẹ, ọba jijẹ, ikẹkọọ-yege, ajọdun, ajọdun isin, ati bẹẹ bẹẹ lọ. Eyi lo fi jẹ pe bi ariya kekere ṣe wa, bẹẹ ni pati nla wa, ko si sigba ti ayẹyẹ ko le ṣẹlẹ nilẹ Yoruba, agaga lopin ọsẹ, iyẹn ọjọ Ẹti, Furaidee, ọjọ Abamẹta, Satide titi kan ọjọ Aiku, Sannde. Koda awọn kan máa n daṣa, wọn si tun n ṣẹfẹ pe ‘Satide lẹbọ n ṣẹlẹ’, tabi ‘Ọjọ gbogbo bii ọdun ni’.

Bawo ni Yoruba ṣe n mura ariya silẹ? Ki lo maa n ṣẹlẹ lagbo ariya kọọkan? Anfaani ati oore wo lo wa ninu ariya ṣiṣe nilẹ Yoruba?

Ipenija ati ewu wo lo máa n ba ariya ṣiṣe rin nilẹ Yoruba? Awọn iyatọ wo lo wa ninu ariya laye ọjọun ati lode-oni?

Ẹ pade wa ninu apa keji apilekọ yii bi a o ṣe maa ṣe atupalẹ ayẹyẹ ṣiṣe nilẹ kaarọ-o-jiire!

 

Leave a Comment

Your email address will not be published.

Start typing and press Enter to search