Itafaaji

Bobrisky tun ti ha o! Bọ́dà Sẹmẹ lọwọ ti tẹ ẹ


Bo ba jẹ awada lasan ni ọdọmọkunrin to ti fẹrẹ sọ ara ẹ di obinrin tan nni, Idris Ọlanrewaju Okunẹyẹ, n ṣe nigba to sọ lori ayelujara ni gẹrẹ to jade l’ẹwọn laipẹ yii, pe oun ṣi fẹẹ pada sọgba ẹwọn ọhun tori ibẹ ba oun lara mu, afaimọ ni ala ọkunrin bii obinrin to maa n pe ara ẹ ni Mummy of Lagos yii ko nii wa si imuṣẹ laipẹ, latari b’awọn agbofinro ṣe ni ọwọ wọn tun ti tẹ Bobrisky bayii, o si ti wa l’akolo awọn, wọn ni ibi to ti n dọgbọn lati gba ọna ẹburu sa kuro lorileede yii lo ti ko s’awọn lọwọ, lo ba wọ gbaga!

Awọn imigireṣọn, iyẹn ileeṣẹ to n ri si iwọle ati ijade niluu lorile-ede Naijiria, Nigeria Immigration Service, NIS, ni wọn kẹẹfin Idris Ọlanrewaju Okunẹyẹ, nibi to ti n pa kubẹkubẹ gba ẹnubode aala ilẹ Naijiria ati orile-ede Bẹnẹ to wa niluu Sẹmẹ, iyẹn Sẹmẹ border kọja, wọn lo fẹẹ sa lọ ni.

Loootọ kii ṣe pe awọn agbofinro kede pe awọn n wa Bobrisky tẹlẹ o, amọ gẹgẹ bi atẹjade kan ti ileeṣẹ imigireṣọn fi lede lori ikanni X wọn lọjọ Mọnde naa ṣe sọ, wọn ni ẹni ti ọrọ rẹ yoo wulo, ti yoo si ṣeranwọ ninu iwadii to lọọrin kan t’awọn aṣofin apapọ n ṣe lọwọ niluu Abuja ni Mummy of Lagos yii, ko si le dasiko ti wọn fẹẹ fọrọ wa a lẹnu wo waa dawati, nitori ẹ lawọn ṣe mu un, ati pe, lẹyẹ-o-sọka lawọn yoo taari rẹ sọdọ awọn agbofinro l’Abuja.

Bẹẹ, ṣaaju k’awọn imigireṣọn too ṣe ikede yii ni ọkunrin t’awọn eeyan gba tiẹ lori ayelujara kan, Ọgbẹni Martins Otse, ti inagijẹ rẹ n jẹ VeryDarkMan ti kọkọ gbe fidio kan jade lori ikanni rẹ, o ṣafihan Bobrisky l’akolo awọn ti wọn mu un, o si kede pe wọn ti mu un, bi ko ba si ri bẹẹ, o ni ko ja oun niyan rẹ.

Tẹẹ o ba gbagbe, VeryDarkMan yii lo tu aṣiri ọrọ kan ti wọn fẹsun rẹ kan Bobrisky pe o sọ nipa b’oun ṣe san obitibiti miliọnu naira f’awọn ọga kan nileeṣẹ ẹlẹwọn ilẹ wa, eyi to jẹ k’oun lanfaani lati gbe ile gidi, k’oun si jaye ọlọba ni gbogbo asiko toun n ṣẹwọn oṣu mẹfa tile-ẹjọ sọ ọ si nibẹrẹ ọdun yii.

Ofofo yii da awuyewuye silẹ, o si mu ki wọn jawee ‘lọọ rọọkun nile na’ fawọn ọga ileeṣẹ ẹwọn ti wọn Fura si. 

Lọgbọ-lọgbọ ọrọ yii lo mu k’awọn ọmọ ileegbimọ aṣoju-ṣofin pinnu lati tusu de’salẹ ikoko, wọn kọwe pe Bobrisky ati VeryDarkMan, amọ ni ọgbọnjọ oṣu Kẹsan-an, ọdun 2024 yii, l’ọjọ ti VeryDarkMan yoju sí wọn, Bobrisky ko wa, eyi lo si mu ki VeryDarkMan taku pe oun ko nii sọrọ laijẹ pe Idris Okunẹyẹ wa nijokoo. Ni wọn ba sun ọjọ iwadii siwaju.

Leave a Comment

Your email address will not be published.

Start typing and press Enter to search