Itafaaji

Rodri ni agbabọọlu to fakọyọ julọ lagbaye ni 2024!

Ni bayii, ajọ to n ṣakoso ere bọọlu alafẹsẹgba lágbayé, Fédération Internationale de Football Association, ti gbogbo eeyan mọ si FIFA, ti kede pe ẹni to jawe olubori gẹgẹ bii agbabọọlu ti mùṣèmúṣè rẹ dá múṣémúṣé julọ lagbaye l’ọdun 2024 yii, ẹni ti ìbò rẹ ku fọfọ julọ, to peregede, to si fi gbọrọ jẹ’ka laaarin awọn gende agbabọọlu ẹlẹgbẹ rẹ kari aye ni Ọgbẹni Rodri Hernández, to n gba bọọlu fun ẹgbẹ agbabọọlu Manchester City, wọn si ti fun un l’ami-ẹyẹ Balloon D’Or lati sami ijawe olubori rẹ.

Oru mọju ọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ọjọ kọkandinlọgbọn, oṣu Kẹwaa, ọdun 2024 yii layẹyẹ naa waye ni Théâtre du Châtelet to wa niluu Paris, lorileede France.

 

Ninu atẹjade kan ti ajọ FIFA ti kọkọ fi lede lọjọ kẹrindinlọgbọn, oṣu Kẹwaa yii nipa eto ọhun, orukọ awọn afi-bọọlu-dabira lori papa bii ọgbọn (30) lo wa lakọọlẹ wọn, kaakiri aye si ni wọn ti ṣa wọn jọ, bẹẹ ẹni kan ṣoṣo ni wọn maa mu.

Ninu awọn ọgbọn yii, agbabọọlu kan ṣoṣo lo wa lati ilẹ adulawọ, iyẹn ilẹ Africa, orukọ rẹ ni Ademọla Ayọọla Lookman, ọmọ Yoruba, ọmọ bibi orileede Naijiria ni, bo tilẹ jẹ pe orileede England ni wọn bi i si lọdun mẹtadinlọgbọn (27) sẹyin.

Ẹgbẹ agbabọọlu Serie A club ni Atalanta lo ti n gba bọọlu, o si wa lara ikọ agbabọọlu Super Eagles ti Naijiria.

Lasẹyinwa-asẹyinbọ, lẹyin ifori-kori, ifikun-lukun ati idibo abẹle, ipo kẹrinla ni Lookman bọ si, nigba ti Rodri wa nipo kinni.

Lookman sọrọ lẹyin ayẹyẹ ọjọ naa, o ni no tilẹ jẹ pe oun kọ ni ami-ẹyẹ naa ja mọ lọwọ, sibẹ inu oun dun dọba pe orukọ oun wa lara awọn ti wọn dabaa rẹ, ti wọn si gbe yẹwo lati fun lẹbun pataki naa. O ni nnkan iwuri mi-in tun ni pe bi awọn agbabọọlu ilẹ Africa ṣe pọ to, oun nikan ni wọn to orukọ rẹ mọ awọn to fẹẹ gba ami ẹyẹ naa.

Aarẹ orilẹ-ede Liberia, toun naa ti gba ami ẹyẹ ọhun ri lọdun 1995, lo kede orukọ Rodri, ti wọn si gbe ami-ẹyẹ ti wọn fi ohun ọṣọ iyebiye ṣe, bọọlu to n dan bii digi kan fun un.

Lati ọdun 1956 ni awọn agbabọọlu kari aye ti n gba ami ẹ̀yẹ yii lọdọọdun, amọ ẹẹkan ṣoṣo ni oriire naa ti wa silẹ Africa ri, George Yeah lo gba a lọdun 1995.

Ọdọbínrin kan, to n gba bọọlu fun ẹgbẹ agbabọọlu Barcelona lobinrin, Aitana Bonmati, lo gba ami-ẹyẹ agbabọọlu obinrin to tayọ lagbaye, wọn si fún Lamine Yamal ni ami ẹyẹ agbabọọlu to fakọyọ lojo-ori to kere. Ọmọ ọdún mẹtadinlogun pere ni.

 

Leave a Comment

Your email address will not be published.

Start typing and press Enter to search