Bi wọn ba n wa idile taa le pe ni ‘iṣẹ tiata-diran’ nilẹ Yoruba, ọkan lara mọlẹbi bẹẹ ni ti awọn Afọlayan, iyẹn idile ti Kunle Afọlayan, Arẹmu Afọlayan, Gabriel Afọlayan ti jade wa, ọmọọya kan naa lawọn mẹtẹẹta yii, odu si ni wọn lagbo ere itage, wọn ki i saimọ f’oloko, amọ ni bayii, awọn irawọ oṣere naa ti di ọmọ orukan, iya to bi wọn ti jade laye, ọpọ awọn ololufẹ wọn at’awọn onitiata ẹlẹgbẹ wọn lo si n ṣedaro, ti wọn n kẹdun iku mama naa.
Kunle Afọlayan lo kede iku mama ẹni ọdun mọkanlelọgọrin (81) ọhun lori ikanni Instagiraamu lọjọ Abamẹta, Satide, ọjọ keji, oṣu Kọkanla, ọdun 2024.
O gbe diẹ lara awọn fọto ti mama rẹ ya lasiko ti wọn n ṣ’ayẹyẹ ọjọọbi ọgọrin ọdun rẹ lọdun to kọja sibẹ, agaga eyi ti awọn ọmọ naa ya pẹlu mama wọn ninu aṣọ ẹgbẹjọda alawọ buluu, ti wọn ṣi rọgba yi mama naa ka tẹrin-tẹyẹ.
Labẹ awọn fọto naa lo ti kede iku iya rẹ, o ni: “O ṣoro lati gba, amọ wọn gbe igbe aye rere.
Mama wa Ọmọladun Ayanladun Afọlayan ti lọọ sinmi (1943 si 2024). Ọpọ ọmọ ati ọmọ-ọmọ lo gbẹyin wọn.
Ẹ jọọ ẹ maa ranti wa ninu adura yin o. Ọmọ rere aa gbẹyin gbogbo wa. Ire o.”
Bi awọn oṣere tiata ẹlẹgbẹ wọn ṣe gbọ nipa iṣẹlẹ yii ni kaluku wọn ti n ba awọn ọmọ orukan naa kẹdun, ti wọn si n rọ wọn lati m’ọkanle.
Alagba Jide Kosọkọ, Alagba Adebayọ Salami ti ọpọ eeyan mọ si Ọga Bello, Toyin Afọlayan, ti wọn tun n pe ni Lọla Idijẹ, toun naa jẹ mọlẹbi Oloogbe, Fẹmi Adebayọ, Kunle Afod, Anthar Laniyan, Dele Odule ati bẹẹ bẹẹ lọ ni wọn ṣedaro iku Mama agbalagba yii, bẹẹ ni aka-i-ka-tan ọrọ ibanikẹdun rọ wọle lati ọdọ awọn ololufẹ awọn ọmọ oloogbe mẹtẹẹta ọhun.
Anthar Laniyan ni: Sun’re o Mama. Ki ọkan rẹ sun ni alaafia.
Mo ba yin kẹdun fun adanu yii o. A dupẹ lọwọ Ọlọrun fun igbe aye rere ti Mama lo. Ki Ọlọrun ninu aanu rẹ ti ko l’opin fun gbogbo mọlẹbi ni okun lati fara da adanu nla yii. Ẹyin mama aa daa.”
Ọga Bello kọ ọrọ tirẹ bayii: “Akinkanju obinrin lo rele yii o. Iya agba agboole Afọlayan ti lọ! Amọ o tu wa ninu pe igbe aye rere, to rẹwa, ni wọn gbe laye. Ẹ ṣọkan giri o, ẹyin ọmọ.”
Niṣe ni Ọmọọba Jide Kosọkọ figbe ta nigba to n sọrọ lori iṣẹlẹ yii, o ni: “Ooo, Ọlọrun o, Iya Gangan ti lọ! Wao, aya Afọlayan, Mama Kunle, Mama Arẹmu! Ẹ ti ṣe daadaa o, ẹ ṣe daadaa gidi ni. Sun’re o.”
Ronkẹ Ojo, ti wọn tun n pe ni Ronkẹ Oshodi Oke sọ pe: “Pẹlu ọkan to wuwo, mo ba ẹyin mọlẹbi Afọlayan kẹdun o. Maami Ọmọladun Ayanladun Afọlayan, obinrin atata to na’wọ aanu si ọpọlọpọ eeyan, titi lae la o maa ṣeranti yin. O nira lati gba pe mama yii ti lọ loootọ, amọ apẹẹrẹ ifẹ, okun ati oore-ọfẹ to fi silẹ yoo maa wa pẹlu wa titi. Apẹẹrẹ igbe aye to dara gan-an, to rẹwa ni wọn fi silẹ fawọn ọmọ ati ọmọ-ọmọ wọn. Ọmọ ire aa gbẹyin gbogbo wa o.
ITAFAAJI naa n ba mọlẹbi Afọlayan kẹdun ti Mama wọn yii, a si gbadura ki Ọlọrun tu gbogbo wọn ninu.