Ọrọ t’awọn eeyan maa n sọ pe ‘ọmọ ale nii ri’nu ti ko ni bí,’ ọrọ naa ti ṣẹ mọ, Laide Bakare, gbajumọ oṣere tiata to rẹwa daadaa yii lara, pẹlu bi ibinu ṣe ru bo o loju laipẹ yii, o yari patapata fawọn ọmọọṣẹ rẹ ni, bo ṣe n sọrọ fatafata, bẹẹ lo n ju’pa ju’sẹ, to n para gidi, gẹgẹ bii aṣa t’awọn ọdọ iwoyi n da, o ni oun ko le gba laye ki wọn f’ọbọ lọ oun, oun ko le jẹ k’ẹnikan gbe oun ni mugun, ko tiẹ wo ti pe wọn n ka fidio iṣẹlẹ naa silẹ.
Laide Bakare, to tun jẹ Oludamọran Pataki lori eto ariya si Gomina ipinlẹ Ọsun, Sẹnetọ Ademọla Adeleke, ni iṣẹlẹ naa waye lasiko toun n ya fiimu oun lọwọ, eyi to pe akọle rẹ ni Owo Epo, o lawọn bọisi kan ni wọn fẹẹ fi ìlọ̀kulọ̀ lọ oun, bẹẹ oun kii gba igbakugba ni toun.
Ninu fọran fidio surutu ohun eyi to gbe soju opo ayelujara rẹ, Laide Bakare n fi binu sọrọ fatafata ni, b’awọn kan ṣe n bẹ ẹ pe ko mu suuru, ko farabalẹ, bẹẹ lo n fesi pe ‘mi o farabalẹ, ma bẹ mi ki n farabalẹ rara, ṣe o mọ nnkan ti bọbọ yii ti ṣe fún mi? Ṣe o mọ nnkan ti bọbọ yii ṣe fun mi ṣa! Mi o gba,’ ati bẹẹ bẹẹ lọ.
Lẹyin ti oju rẹ walẹ diẹ to sí ti paarọ aṣọ lati lọọ bẹrẹ fiimu to n ya, Laide n rẹrin-in, o si n sọ fun obinrin ẹlẹgbẹ rẹ kan nipa iṣẹlẹ naa, o ni ‘awọn bọbọ yẹn aa maa wo o pe obinrin t’awọn n foju eeyan jẹẹjẹ wo, aṣe babanla taotu (tout) ni mi!’ Tout ni ede oyinbo fun ọmọọta tabi janduku.
Labẹ fidio naa, Laide Bakare kọ ọrọ diẹ sibẹ, ede adamọdi Gẹẹsi eyi ti wọn pe ni pidgin lo fi kọ ọ, o ni:
“Ori gbogbo eeyan lo n gbona ni Naija lasiko yii o. A bẹẹ ri bawọn kan ṣe fẹẹ f’ọbọ lọ mi lasiko ti mo n ya fiimu mi, Owo Epo, lọwọ. O maa jade laipẹ yii… O ya ẹ jẹ ka lọ!”
Niṣe lọpọ awọn ololufẹ Laide Bakare n bu sẹrin-in lori bo ṣe huwa naa. Awọn kan ni niṣe lo ṣe bii iyawo ṣọja, nigba t’awọn mi-in patẹwọ fun un, wọn lawọn nífẹẹ si bi ko ṣe gba gbẹrẹ yẹn. Ede oyinbo mọ Yoruba l’ẹnikan fi kọ tiẹ ni ṣoki, o ni: Hunm, action pọ!