Itafaaji

Ẹ wo bi Mo Bimpe ṣe bu ‘kinni’ ọkọ ẹ so ni gbangba

Ọrọ ọhun ti fẹẹ da ariyanjiyan silẹ, bawọn kan ṣe n sọ pe o mọ-ọn-mọ ni, bẹẹ lawọn kan n sọ pe o ṣeeṣi ni, ko mọ-ọn-ọn, awọn kan n sọ pe ko seyii to kan ẹnikankan nibẹ, oun lo ni kinni ọkọ ẹ, o si le gbe e jo bo ba ṣe wu u, bẹẹ lawọn kan n sọ pe oge aṣeju ni gbangba niru ẹ, wọn ni ko daa, n l’awuyewuye ba n lọ rẹkẹrẹkẹ lori ẹrọ ayelujara.

Ọrọ ọhun ko ṣẹyin fidio kan ti gbaju-gbaja oṣere tiata nni, Lateef Adedimeji, to ṣe fiimu Liṣabi laipẹ yii, gbe sori ẹrọ ayelujara lori ikanni Instagiraamu rẹ lọsẹ taa wa yii.

Ninu fidio naa, o jọ pe oko ere ti wọn ti lọọ ya fiimu kan ni wọn wa pẹlu awọn oṣere yooku, amọ gẹgẹ bii iṣe oun ati aya rere lọọdẹ ọkọ rẹ, Adebimpe Oyebade, ti ọpọ eeyan mọ si Mo Bimpe, niṣe ni tọkọtaya naa n tage, ti wọn n daraya, ti wọn si n mu inu ara wọn dun lode, gẹgẹ bawọn ololufẹ ṣe maa n tage.

 

Lateef lo lọọ ba Mo Bimpe nibi tọmọbinrin adumaadan naa jokoo si pẹlu aṣọ kaba alawọ pupa rẹsurẹsu to wọ, o ni ko jẹ kawọn ṣere ifẹ, kawọn tayo kan, o ni oun maa fi nnkan bii igi tẹẹrẹ ẹlẹnu ṣoṣoro toun mu dani kan an lara, bi o ba le ṣe yeeṣ, kawọn eeyan le ri i pe awọn n ṣere ifẹ, bẹẹ ni Iyawo rẹ n sọ fun un pe: “Aa, Ade ma fi nnkan gun mi o.”

Bi Lateef ṣe kọkọ fi igi naa kan an lẹgbẹ ọrun lojiji, Mo Bimpe pariwo “Aa!” o si fọwọ pa ibẹ. Lateef ni a ti yege niyẹn. Lateef tun ṣe bẹẹ lẹẹkeji, ni Mo Bimpe ba parọwa fun un pe ko ma fi nnkan gun oun nao.

Bi ọkọọyawo yii ṣe fẹẹ yisẹ pada ni iyawo rẹ beere pe ‘owo da, owo iṣẹ da’ o ni ko sanwo idije naa, amọ Lateef ni ko tii ya, ki i ṣe lẹsẹkẹsẹ, o ni later niyẹn, amọ Mo Bimpe loun ko gba, o si bẹrẹ si i fọwọ pa apo ṣokoto rẹ boya owo wa nibẹ. Bi Lateef tun ṣe fẹẹ yiṣẹ pada, niṣe ni Mo Bimpe bu u kinni rẹ so, ọgangan ibi ti ‘baba aburo’ ọkọ rẹ fori pamọ si lo da ọwọ bo, amọ ko pẹ to fi gbọwọ kuro nibẹ, tori ọkọ rẹ ọhun tadi mẹyin lojiji, o jọ pe ko reti ohun to ṣẹlẹ naa, lawọn mejeeji ba rẹrin-in lu ara wọn.

Fidio yii lawọn eeyan wo lori ikanni Lateef Adedimeji, ni wọn ba bẹrẹ si i ṣe ataretare rẹ, wọn si n kọ ero onikaluku sabẹ fidio naa bi wọn ṣe n pin in.

Mo Bimpe lo kọkọ kọ ọrọ sibẹ o ni, “wo o ọkunrin yii, oo nii pa mi lalẹ yii o, waa maa pada lọ si Eko too ti wa, biko. O si fi ami ẹrin keekee sibẹ.

Ẹniọla Ajao ni “Awọn eeyan yii ti fẹẹ ẹrin pa mi, mo ti rẹrin-in yo nibi yii o. Onijangbọn ẹda kan ni Lati yii,” oun naa si fi ami ẹrin keekee si i.

Ede Yoruba ni ẹnikan to pe orukọ ara ẹ ni Marley_Kween fi kọ ọrọ tiẹ, o ni: “Aunti Bimpe, ki lo de tẹyin naa fi ọwọ gbe kinni Bọọda Lateef nita gbangba.” Oun naa fi ami ẹrin pari ọrọ rẹ. Amọ loju-ẹsẹ ni Mo Bimpe ti fesi fun onitọhun, o ni: “Ṣe emi kọ ni mo ni kinni naa ni?” lo ba dawọ boju, o si tun rẹrin-in.

Awọn kan ti wọn tun sọrọ kin Mo Bimpe lẹyin, wọn ni oun lo ni kinni ọkọ ẹ, kinni ọkọ ẹ, tiẹ naa ni, ko si bo ṣe ṣe e ti ko daa.

Bẹẹ lẹnikan ni: Iwọ Ọlọrun to o n pin ọkọ, ọkọ temi da, pin temi fun mi o.”

Ẹnikan tun sọ pe: Aa, mo ṣẹṣẹ ri fidio yii ni ṣa. Mo fẹran ẹyin mejeeji yii o”, oun naa si gbe ami ẹrin ati idunnu si i.

Leave a Comment

Your email address will not be published.

Start typing and press Enter to search