Bobrisky sọ tuntun: Mo fẹẹ pada si ẹwọn Kirikiri yẹn!
Idris Okunẹyẹ, ọmọkunrin alafẹ to maa n ṣe bii obinrin nni, Bobrisky sọ ohun t’oju rẹ ri l’ẹwọn Kirikiri tile-ẹjọ ju u si fun oṣu mẹfa, latari ẹsun ṣiṣe owo Naira baṣubaṣu to jẹbi rẹ. Amọ o ni oun ko bẹru lati tun pada s’ẹwọn, oun ṣi fẹẹ pada.
Beeyan ba ro pe iṣẹlẹ to ṣẹlẹ si ilumọ-ọn-ka alafẹ ori ẹrọ ayelujara, ọmọkunrin to ti yi ara rẹ pada si obinrin nni, Idris Ọlanrewaju Okunẹyẹ, ti ọpọ eeyan mọ si Bobrisky, latari ẹwọn oṣu mẹfa to fi jura ni Kirikiri, pe boya ọrọ naa yoo ti kọ ọ lọgbọn, irọ ni o, ọkunrin to fẹran lati maa ṣe bii obinrin naa sọ pe kaka ki iṣẹlẹ ọhun ba oun lọkan jẹ, o ni iriri naa dun mọ oun daadaa, ati pe o tun wu oun lati pada s’ọgba ẹwọn, o ni loorekoore loun fẹ maa lọ sibẹ, tori ẹwọn toun lọ ṣe oun lanfaani.
Bobrisky, ẹni ọdun mẹtalelọgbọn (33) to tun maa n pe ara rẹ ni Mummy of Lagos, eyi to tumọ si Mama Eko, sọrọ ọhun lasiko ti oṣere ori ẹrọ ayelujara kan ti wọn n pe ni IsbaeU fọrọ wa a lẹnu wo lori ikanni rẹ lọsẹ to kọja yii.
Nigba ti wọn beere lọwọ Bobrisky pe pẹlu bi irisi rẹ ṣe ri, toju rẹ n dan, ti awọ rẹ si jọlọ nigba to pari ẹwọn rẹ, o jọ pe kinni naa ba a lara mu o, o fesi pe “bẹẹ ni, o ba mi lara mu o.”
Wọn ni ṣe o maa nifẹẹ lati tun pada sẹwọn, o ni “bẹẹ ni, o wu mi lati tun pada sibẹ, iru eyi ti mo lọ yii ni o, mi o fẹ ẹwọn fọpa-wọn o, ki i ṣe ki wọn da ẹwọn gigun fun mi o, amọ bo ba jẹ idajọ ẹwọn perete, mo nifẹẹ si, o wu mi.”
“Idi ti mo fi sọ pe o wu mi lati tun lọọ ṣẹwọn ni pe, ki i ṣe pe o wu mi bẹẹyẹn naa o, amọ mo ri i pe niṣe lawọn eeyan yii fẹẹ ba temi jẹ, tori ti ko ba jẹ bẹẹ ni, mi o tii ri ibi ti wọn ti maa ṣedajọ ẹwọn fun ẹnikan nitori pe o fọn owo ni pati, mi o gbọ iru ẹ ri. Bi gbogbo ẹ ṣe ṣẹlẹ, niṣe lo da bii fiimu loju mi, niṣe lo ṣe mi bii pe, iru sinima wo ni n wo yii kẹ. Ran mi lẹwọn latari pe mo na owo mi bo ṣe wu mi, owo mi la n sọ o, ki i ṣe owo ẹnikẹni o, mi o jiiyan gbe o, mi o fipa baayan lo pọ o, mi o dẹ paayan, mo na owo oogun oju mi ni o, wọn dẹ tori ẹ ran mi lọ saarin awọn apaayan, awọn ọdaran paraku ti wọn wa lẹwọn yẹn, awọn ajinigbe, awọn afipabanilopọ… Amọ o gẹgẹ bi mo ṣe sọ, ohunkohun to ba ṣẹlẹ si mi ninu irin ajo igbesi aye ti mo yan yii, mo ti gbaradi fun un.”
Wọn tun beere lọwọ Bobrisky boya loootọ lo ṣẹwọn ninu ọgba ẹwọn ti awọn ọdaran yooku wa, abi wọn fun un lanfaani si ẹwọn awọn ọlọla, niṣe lo taku, o loun ko ni i sọrọ nipa iyẹn, tori oun mọ ohun tawọn eeyan fẹẹ gbọ, oun ko si ṣetan lati sọ gbogbo ohun to ṣẹlẹ lọhun-un lori afẹfẹ. Bobrisky ni oun ko ni i yee fọn owo loju agbo, amọ lọtẹ yii, oun ko ni i fọn owo naira, owo dọla ati pọun, awọn owo ilẹ okeere loun maa maa fi dara bo ṣe wu oun lati asiko yii lọ.
Tẹ o ba gbagbe, ọjọ kejila, oṣu Kẹrin, ọdun 2024 yii ni Onidaajọ Abimbọla Awogbọrọ, ti ile-ẹjọ giga apapọ kan l’Erekuṣu Eko, juwe ọna ọgba ẹwọn fun Idris Okunẹyẹ, latari bo ṣe jẹwọ pe loootọ loun jẹbi ẹsun ṣiṣe owo naira ilẹ wa baṣubaṣu, wọn lo fabuku kan naira ni pati, ati pe o lufin ijọba lori ọrọ naa.
Ọjọ Aiku, Sannde, ọjọ kẹẹẹdọgbọn, oṣu Karun-un, ọdun 2024 yii, nibi ayẹyẹ nla kan ti wọn ti n ṣe afihan ati ikojade fiimu tuntun ti gbajumọ oṣere tiata nni, Ẹniọla Ajao, ṣe, to pe akọle rẹ ni Ajakaju ni wọn ti kede Bobrisky gege bii obinrin ti imura rẹ peju owo ju lọ, bo tilẹ jẹ pe ikede yii, ati awọọdu ti wọn fun un lọjọ naa pada da awuyewuye nla silẹ lori ẹrọ ayelujara, ibi ayẹyẹ yii ni Bobrisky ti nawo bii ẹlẹda, to n fọn bọndu naira loju agbo, tawọn ololufẹ rẹ si n kokiki rẹ.
Kete ti fọran fidio ayẹyẹ ọhun ti gori afẹfẹ, lawọn agbofinro, awọn ẹṣọ ajọ to n gbogun ti iwa ajẹbanu ati jibiti lilu nilẹ wa, Economic and Financial Crimes Commission, EFCC, ti lọọ fi pampẹ ofin gbe ọmọkunrin naa nile rẹ, wọn mu un lọ sọfiisi wọn, wọn fi ibeere po o nifun pọ, lẹyin naa ni wọn foju rẹ bale-ẹjọ, ti adajọ si ṣa a mẹwọn oṣu mẹfa.
Amọ ni bayii, Bobrisky ti loun nifẹẹ ẹwọn toun lọ o, ati pe oun yoo tun ṣi pada sibẹ, oun o kan fẹẹ pẹ nibẹ ni.