Itafaaji

Ẹniọla Badmus tọrọ aforiji lọwọ Ọmọborty, eyi lohun to ṣẹlẹ

Eniola Badmus
Omoborty

Bo tilẹ jẹ pe ko sẹni to fura pe nnkan kan to le di ija nla nlọ laarin awọn oṣere tiata meji yii, sibẹ, gẹgẹ bi Yoruba ṣe maa n powe, wọn ni bi ẹlẹjọ ba ti mọ ẹjọ rẹ lẹbi, ki i pẹ lori ikunlẹ. Eyi lo ṣe rẹgi pẹlu bi gbajugbaja oṣere tiata to ti di oloṣelu nni, Ẹniọla Badmus, tawọn eeyan tun mọ si Wule Bantu tabi Gbogbo Bigi gẹẹz, ṣe tọrọ aforiji atọkanwa lọwọ ọrẹ rẹ toun naa jẹ ilumọ-ọn-ka onitiata, to kun niwaju kun lẹyin nni, Abilekọ Abiọdun Ọkẹowo, ti ọpọ awọn ololufẹ rẹ mọ si ỌmọBorty, Ẹniọla ni ki ỌmọBorty fori ji oun o, oun aa ṣatunṣe si iwa oun bo ṣe yẹ. 

Ohun to ṣẹlẹ ni pe ọjọ Abamẹta, Satide, ọjọ keje, oṣu Kẹsan-an ọdun 2024, iyẹn opin ọsẹ to kọja yii, ni Ẹniọla Badmus ṣe ayẹyẹ ọjọọbi rẹ, ọjọ naa lo pe ẹni ọdun tuntun loke eepẹ, gẹgẹ bawọn onitiata si ṣe maa n ṣe, gbogbo awọn ẹlẹgbẹ rẹ atawọn ololufẹ rẹ ni wọn ṣajọyọ ọmọ ọlọjọọbi yii lori ayelujara, bawọn kan ṣe n gbe fọto rẹ si i, bẹẹ lawọn mi-in n lo fidio rẹ, ti wọn si n kọ ọrọ adura, ọrọ idupẹ ati iwuri nipa obinrin arẹwa to lomi lara daadaa naa.

Ọmọborty naa ko gbẹyin, o gbe fọto ọrẹ rẹ yii soju opo ayelujara Instagiraamu rẹ, o si kọ ọrọ ikini ṣoki kan sabẹ fọtọ naa, o ni: “Ẹ kuu ayẹyẹ ọjọọbi o, Badoosky olufẹ mi titi aye, Ẹniọla Badmus”.

Omoborty

Ko pẹ ti Ẹniọla fesi to si tọrọ aforiji yii ni ọrẹ rẹ naa, Ọmọbọrty ti ka ọrọ rẹ, loun naa ba tun kọ ọrọ iwuri mi-in nipa ọlọọjọbi yii, lati fihan pe ajọṣe to gbamuṣe lo wa laarin awọn latẹyinwa, niṣe lo da ede oyinbo pọ mọ ti Yoruba lọtẹ yii, o ni: “Ọmọye mi ni ẹ, titi aye si ni”. Ede Ijẹbu lo n pe Ọmọọya mi ni Ọmọye mi.”

Gbogbo ọjọ keje, oṣu Kẹsan-an, lọdọọdun ni Ẹniọla Badmus maa n ṣayẹyẹ ọjọọbi rẹ. Ni ti ọdun yii, ko ṣẹṣẹ digba teeyan ba royin, o han gbangba pe inu arẹwa oṣere ti iwaju rẹ kun, ti akọyinsi rẹ naa ko kẹrẹ yii, dun dọba, tori inu ẹni ki i dun ka pa a mọra. 

Lati bii ọjọ meji ṣaaju ọjọọbi ọhun ni Wule Bantu ti n
kọ ọrọ soju opo Instagiraamu rẹ, bo ṣe n paṣamọ nipa ayẹyẹ ọjọọbi to n bọ, bẹẹ
lo n ṣadura fun ara rẹ, tawọn ololufẹ rẹ si n ki i kuu oju lọna.

Lọjọọbi ọhun gan-an, awọn ọrọ adura akanṣe lo kọ sabẹ
awọn fọto to jojunigbese to gbe sori ikanni rẹ. Lara ọrọ to kọ sibẹ ni: “
Loni-in,
mo n fi asiko yii dupẹ lori
irin-ajo aye mi, ibi giga ti mo ti de, ati ẹni ti mo di loni-in. Mo dupẹ lọwọ
Ọlọrun fun ẹbun wiwalaaye, ati fun ọpọlọpọ ẹbun aka-i-ka-tan to rọjo rẹ sori
mi, pẹlu okun to fun mi ti mo fi le dojukọ awọn ipenija to sọ mi di ẹni ti mo
jẹ.

Ni ọjọ akanṣe yii, mo gbe ọkan mi soke ninu ọpẹ ati
adura, mo gbadura fun alekun okun, nipa tẹmi ati tara, ki n le maa rin nibaamu
pẹlu ete ọkan mi ati kadara to wa niwaju mi. Ọlọrun jọọ fun mi lọgbọn ti mi o
fi ni i ṣiyan, suuru ti maa fi la asiko laasigbo kọja, ati ẹmi aanu ki n le
nifẹẹ awọn mi-in ki n si sin wọn.”

Bayii ni Ẹniọla ṣe daniyan fun ara rẹ lọjọọbi rẹ.

Leave a Comment

Your email address will not be published.

Start typing and press Enter to search