Itafaaji

Gbanjo! Owo Ata ati Tomato Lulẹ L’Oke-Ọya

Ṣinkin bii ẹni jẹ tẹtẹ oriire ni inu awọn araalu kan lagbegbe Oke-Ọya ilẹ Naijiria n dun bayii, latari bi owo tomato ṣe lulẹ, ti eroja isebẹ naa si di pọntọ lọja wọn.

Agbegbe Bula, ni ijọba ibilẹ Akko, nipinlẹ Gombe ati ayika rẹ ni iroyin ayọ naa ti ṣẹlẹ, niṣe lawọn agbẹ atawọn olokoowo tomato patẹ ọja naa rẹrẹẹrẹ, ti koowa wọn si n parọwa sawọn onibaara lati ba wọn ra a.

Aita ọja yii ni ITAFAAJI gbọ pe o ṣokunfa ẹdinwo tomato, lati ida ọgọrun-un si ida mẹwaa ninu ọgọrun-un laarin ọsẹ kan aabọ pere. Apẹrẹ tomato kan ti wọn ti n ta ni ẹgbẹrun mẹwaa naira (N10,000) lọsẹ meji sẹyin ti ja walẹ si ẹgbẹrun kan naira (N1,000) pere, ọrọ naa si kan ata pẹlu, tori arun tii ṣe ogoji ni i ṣe ọọdunrun, apẹrẹ ata ti wọn ti n ta ni ẹgbẹrun lọna aadọta naira (N50,000) ti ja walẹ si ẹgbẹrun lọna mẹrindinlogun (N16,000) ti i ṣe ida mejidinlaaadọrin lori ọgọrun-un.

Ipinlẹ Gombe

Ṣe Yoruba bọ, wọn ni ọrọ to n pa oloko lẹkun, oun laparo fi n rẹrin-in, bi adinku to ba owo tomato ati ata yii ti ṣe mu ki inu awọn araalu atawọn oniṣowo kan maa dun, ọrọ ko ri bẹẹ fawọn agbẹ rara, niṣe ni ọpọlọpọ wọn fajuro, ti ẹrin si jinna ṣẹẹkẹ wọn, wọn ni kinni naa ko pe awọn rara.

L’Ọjọbọ, Tọsidee, ọjọ kejila oṣu Kẹsan-an yii, Alaaji Saleh Maikudi, ti i ṣe alaga 

Alaaji Saleh Maikudi

 

ẹgbẹ awọn agbẹ to n ṣe ọgbin tomato (Tomato Farmers Association) lagbegbe Bula, nipinlẹ ọhun sọ fawọn oniroyin Ajọ Akoroyinjọ ilẹ wa, News Agency of Nigeria, NAN, pe owo tomato ati ata to ja walẹ lojiji yii ti fa ẹdun ọkan ati ipaya fun ọpọlọpọ awọn agbẹ lagbegbe naa, nitori adanu nla lo jẹ fun wọn, ko si ọna lati ri owo rẹpẹtẹ ti wọn na sori oko wọn pada, debi ti wọn yoo ri ere lori rẹ.

 

O ni ẹgbẹrun mẹsan-an Naira ni wọn n padanu lori apẹrẹ tomato kan, ẹgbẹrun lọna ọgbọn naira lo n poora lori apo atarodo ati tataṣe kọọkan.

O ni “ọrọ yii kọja afarada o, pẹlu bi owo ọja yii ṣe ja walẹ to, sibẹ niṣe lawọn agbẹ n rawọ ẹbẹ sawọn onibaara ki wọn too ri ọja wọn ta, tori awọn ọja yii ko ṣe e tọju pamọ fun akoko pipẹ, o maa bajẹ.

Bakan naa ni Kaifa Bello, Alaga ẹgbẹ awọn to n ṣọgbin ewebẹ (Vegetables Sellers Association) lagbegbe naa sọrọ, o ni ki ijọba apapọ ati ti ipinlẹ dide iranwọ fawọn agbẹ, nipa ipese ileeṣẹ ti yoo maa ṣe awọn eroja isebẹ yii lọ́jọ̀, ti yoo fi ṣee ṣe lati tọju rẹ lasiko ọpọ, ki awọn araalu le ri i lo nigba ti ọwọngogo rẹ ba de.

 

Tẹ o ba gbagbe, lasiko kan ninu oṣu Karun-un ọdun 2024 yii, ọwọngogo ata ati tomato gbode kan debi pe apẹrẹ tomato kan di ẹgbẹrun lọna aadọjọ naira (N150,000) lawọn ọja kan lorileede yii.

Leave a Comment

Your email address will not be published.

Start typing and press Enter to search