Itafaaji

Fìlà: Àlékún ẹwà ati oge awọn ọkunrin nilẹ Yoruba (Apa Kinni)

Yoruba ko kẹrẹ to ba dọrọ imura, itunraṣe, oge ṣiṣe, ṣiṣe ẹwa lọṣọọ ati irisi. Ko le ma ri bẹẹ, latigba ìwáṣẹ̀ ni iran Yoruba ti maa n ṣalekun ẹwa ati irisi wọn, wọn ko fi ọwọ kekere mu ọrọ imura, iwọṣọ, nitori igbagbọ wọn ni pe ti wọn ba pe eeyan kan ni ọmọluabi, o ni iru iwa, ọrọ, irisi, imura ati iṣesi ti wọn gbọdọ ba lọwọ onitọhun.

Bo tilẹ jẹ pe awọn obinrin ni wọn kundun oge ṣiṣe ati imura ju, ti awọn nnkan eelo wọn si pọ ju ti ọkunrin lọ, sibẹ ọrọ imura lọna to yẹ nilẹ Yoruba ko yọ awọn ọkunrin ati ọmọde naa silẹ. Ọkan pataki ninu imura awọn ọkunrin laye ọjọun titi di ode oni ni fila jẹ.

Fila ni wọn n pe ibori tawọn ọkunrin maa n de si ori nigba ti wọn ba n mura. Laye ọjọun, ko wọpọ ki ọkunrin ṣi ori rẹ silẹ ni gbangba, ayafi bo ba jẹ ẹru, tabi ti o wa lẹnu iṣẹ ọba, ti iṣẹ ọhun ko si faaye gba dide fila. Yoruba gbagbọ pe, laika ipo teeyan wa tabi iṣẹ teeyan n ṣe, o ni iru fila, iyẹn ibori, to yẹ fun ọkunrin naa lati de, lẹyin to ba ti wọ aṣọ to yẹ tan.

Idi ree to fi jẹ pe bi awọn ọdẹ ṣe ni fila tiwọn, bẹẹ lawọn agbẹ, akọpẹ, alagbẹdẹ, oloye, ọlọla, baalẹ, ọmọde ati agba ṣe maa n de fila sori. Ṣe irinisi ni iṣenilọjọ, ba a ṣe rin la a koni, gẹgẹ bii owe Yoruba ṣe sọ.

Bi fila tawọn ọkunrin maa n de yii ṣe jẹ oriṣiiriṣii, bẹẹ ni ọna ti wọn n gba ṣe e yatọ si ara wọn, o si ni iru aṣọ tabi nnkan eelo ti wọn maa n lo lati ṣe awọn fila wọnyi, ati iru ode ti wọn maa n de fila naa lọ. Ohun mi-in to tun ṣe pataki ni pe awọn ọkunrin ki i wulẹ de fila ṣakala bo ba ṣe wu wọn ṣaa, o ni ọna ti wọn maa n gba de e. Dide fila yii, nigba teeyan ba n mura ode, ni wọn n pe ni gigẹ fila, tabi keeyan gẹ fila. Bẹẹ si ree, gigẹ fila ni itumọ, o si pin si oriṣiiriṣii ọna. Beeyan ba gẹ fila rẹ sọtun-un, o ni ohun to tumọ si, beeyan ba si gẹ ẹ sapa osi, eyi naa ni itumọ tirẹ, ati bẹẹ bẹẹ lọ.

Lara oniruuru fila to wa nilẹ Yoruba ni akẹtẹ, fila gọbi, fila abeti aja, fila ẹtù, fila Kufi, Gberi-ọdẹ, Gberi-agbẹ, fila ẹlẹmu, fila Ìkòrì, fila onídẹ, àdìrọ̀, ati bẹẹ bẹẹ lọ.

Ni apa keji apilẹkọ yii, a o maa sọ bi wọn ṣe n ṣe ọkọọkan awọn fila yii, bẹẹ la o tun sọrọ nipa ibi to tọna lati gẹ fila si.

Lẹyin eyi, a o mẹnu ba awọn owe ilẹ Yoruba diẹ to ba fila ati imura mu.

Leave a Comment

Your email address will not be published.

Start typing and press Enter to search