Itafaaji

Nitori MohBad, Yọmi Fabiyi ti sa kuro ni Naija, o ni wọn fẹẹ pa oun

Yọmi Fabiyi, gbajumọ oṣere tiata ilẹ wa, to tun n ṣiṣẹ ajafẹtọọ-ọmọniyan, ti wọn tun n pe ni Araba lagbo tiata ti kuro lorileede Naijiria, o ti lọọ fara sinko sibi t'ẹnikan kò mọ. O sọ gbogbo bi ọrọ naa ṣe sẹlẹ ninu fọran fidio kan to ju sori afẹfẹ laipẹ yii

Lasiko yii, toju-tiyẹ laparo fi n riran lọrọ di fun ilumọ-ọn-ka oṣere tiata ilẹ wa, to tun n ṣiṣẹ ajafẹtọọ ọmọniyan nni, Ọgbẹni Yọmi Fabiyi, latari bi ọkunrin naa ṣe kegbajare pe awọn agbenipa kan n dọdẹ ẹmi oun, o ni wọn fẹẹ ṣe oun ni ṣuta, nitori ẹ, o ti sa kuro lorileede yii lọsan-an kan oru kan.

Ṣe ole ki i ja agba ko ma ṣe e loju firi, Yọmi ni ara to fu oun nipa ibi ti awọn afurasi apaayan naa ti dọdẹ oun wa ko kọja ọrọ iṣẹ ajafẹtọọ toun n ṣe nipa iwadii iku ojiji to pa ọdọmọde gbajumọ onkọrin hipọọpu nni, Ilerioluwa Ọladimeji Alọba, ti ọpọ eeyan mọ si MohBad, o ni tori iwọde toun atawọn ọdọ n ṣe leralera lati beere fun iwadii ijinlẹ ti yoo tan imọlẹ si ibi ti iku rẹ ti wa lo mu ki awọn kan maa lepa ẹmi oun kiri.

Ninu fọran fidio kan to gbe soju opo ayelujara Instagiraamu rẹ, Yọmi ṣalaye bọrọ naa ṣe ṣẹlẹ, o ni:

“Oni ni ọgbọnjọ oṣu Kẹsan-an, ọdun 2024, aago kan ọsan kọja iṣẹju mẹrindinlọgbọn ni mo n sọrọ yii, awọn to n ja fun idajọ ododo, ti wọn n pe fun idajọ ododo lori ọrọ MohBad ṣẹṣẹ n kuro nibi iwọde ti wọn ṣe nileegbimọ aṣofin Eko ni. Harefah, Onile, Madam Grace, Bintin-laye, gbogbo yin, ẹ ṣeun o. O yẹ ki n wa pẹlu yin, mo ti wa l’Ekoo lati ana, bi mo ṣe mura naa niyii pẹlu erongba lati kopa ninu iwọde yii, amọ o ṣeni laaanu pe mo ni lati wa gbogbo ọna lati sa kuro ni Naijiria loju-ẹsẹ, oun lo jẹ ki n ta mọ baaluu eyikeyi to fẹẹ gbera bayii, tori wọn ti pari eto lati pa mi. Bẹẹ ni mo sọ, mi o ṣi ọrọ sọ. Fun igba akọkọ laye mi, mo ri i pe awọn kan pinnu lati gbẹmi mi.

“Mo ti ko gbogbo ẹri to wa lọwọ mi le awọn ọlọpaa lọwọ, wọn si ti n ṣiṣẹ lori ẹ. Mo kan fẹẹ bẹ wọn ni pe nnkan kan ko gbọdọ ṣe awọn afurasi ti mo darukọ wọn. Wọn gbọdọ ṣewadii ẹrọ kamẹra olofofo to wa nile MohBad yẹn, dandan ni ayẹwo ijinlẹ si awọn ẹrọ ibanisọrọ wọnyẹn. Ki i ṣe pe boya mi o fẹ ki wọn pa mi o, to ba jẹ ti iyẹn ni, mi o nii sa lọ sibikibi, amọ nitori mo mọ pe ti wọn ba pa mi bayii, o le jẹ ki wọn gbe ọrọ gba ibomi-in, ati pe awọn ọrọ kan wa ti wọn maa fẹ gbọ latẹnu mi.

“Ẹyin ọmọ Naijiria, loootọ mi o tii mọ ibi ti mo n lọ pato bayii, amọ mo mọ pe ẹmi mi de daadaa nibi ti mo wa yii. Mo mọ pe o maa maa ya wọn lẹnu pe bawo ni mo ṣe mọ pe wọn fẹẹ wa pa mi.”

Papakọ ofurufu kan ti ki i ṣe ti Naijiria ni Yọmi Fabiyi wa to ti n ṣe fidio naa, aṣọ ankara olomi aro kan lo si wọ lori awọtẹlẹ ti wọn ya aworan MohBad si, eyi to ni lọkan lati wọ nibi iwọde ti wọn ṣeto pe yoo waye nileegbimọ aṣofin Eko lọjọ Aje, Mọnde, ọgbọnjọ, oṣu Ṣẹtẹmba.

Ẹ o ranti pe ṣaaju ni Yọmi atawọn ọdọ ti wọn n pe fun idajọ ododo lori iku onkọrin ọhun ti kọkọ ṣe iwọde kan niluu Ikorodu, lọjọ kọkanla, oṣu Kẹsan-an yii, eyi to ṣe kongẹ ajọdun ọdun kan ti MohBad ku.

 

Leave a Comment

Your email address will not be published.

Start typing and press Enter to search