Itafaaji

Iyabọ Ojo ni oṣere to mura daadaa ju lọ

Bi wọn ba beere ‘ọmọ ti wọn n sọ’, ọmọ to ta lẹnu lasiko yii, ẹnikan ti ọpọ n ki kuu oriire fun ti ẹwa ati oge ṣiṣe to peju owo, ti imura ati iwọṣọ rẹ sí ‘ja’wo’ gẹgẹ bíi aṣa to gbode ni gbajumọ oṣere-binrin onitiata tọrọ da ṣaka lẹnu rẹ nni, Iyabọ Ojo, arẹwa obinrin naa ti gba ẹbun ẹni to mọ ara i mu julọ, pẹlu ọpọlọpọ owo ti wọn fi ta a lọrẹ.

Oṣere-binrin ẹlẹgbẹ rẹ kan toun naa gbajumọ daadaa, amọ to jẹ ere elede oyinbo lo maa n ṣe ni tiẹ, Omoni Oboli, lo kede orukọ Iyabọ Ojo laṣaalẹ ọjọ Ẹti, Furaidee ọsẹ yii, gẹgẹ bii oṣere ti imura rẹ fakọyọ ju lọ nibi ayẹyẹ afihan fiimu rẹ tuntun ti wọn pe akọle rẹ ni: “Wives on Strike: The Uprising”.

Lori ikanni Instagiraamu rẹ to gbe to gbe ikede naa si, Oboli gbe aworan Iyabọ Ojo to wọ aṣọ t’awọn eleebo n pe ni gown sibẹ, alawọ dudu ni lat’oke delẹ, ti wọn fi awọ mere-mere ṣe l’ọṣọọ lapa ibadi, pẹlu fila obinrin dudu, wọn la igbaaya aṣọ naa, eyi to mu ki apakan orombo Iyabọ mejeeji raaye gbatẹgun alaafia, pẹlu bata to dọgba wẹku.

Labẹ fọto naa, Oboli ṣalaye pe: “Awọn afaṣọ-dárà ilẹ Naijiria ti ṣe bẹbẹ o, Iyabọ Ojo lo ja’we olubori ẹni tí imura rẹ dara julọ, ni ipele t’awọn obinrin. Ogbonkangi lori imura ni ẹ nitootọ. Kuu oriire o, Queen Mother. O fi oyin si ayẹyẹ afihan fiimu wa l’ọna to ṣara-ọtọ.”

Yatọ si awọn ololufẹ Oboli ati Iyabọ ti wọn kọ oniruuru ọrọ oriyin ati apọnle lati ba Iyabọ Ojo yọ ayọ ami ẹyẹ yii, awọn onitiata ẹlẹgbẹ rẹ naa ko gbẹyin, ọpọ ninu wọn ni wọn kọ ọrọ imọriri, awọn kan ko si kọ ọrọ lasan, wọn tun gbe ami ifẹ ati apọnle sabẹ orukọ wọn, wọn si ṣe ami lati fihan pe Iyabọ lawọn dari gbogbo ẹ si.

iyabo new1

Iyabọ Ojo naa ti fesi si ọrọ yii, o fi imọriri rẹ han ninu ọrọ kan to kọ s’ori Instagiraamu naa, o ni: O mu inu mi dun jọjọ bi ẹ ṣe bu kun mi lọna yii, ti ẹ si mọyi mi o.”
Bakan naa ni Oboli tun kede awọn mi-in ti wọn gba oriṣiiriṣii ẹbun lọjọ afihan sinima ọhun.

Leave a Comment

Your email address will not be published.

Start typing and press Enter to search