Itafaaji

Eyi nidi ti mo ṣe fa ori mi kodoro – Yvonne Jẹgẹdẹ

King Wasiu Ayinde, KWAM 1, lo d’aṣa ninu awo orin rẹ kan pe ‘ṣe o da a mọ too ba ri i, Ayinde?’ Bo tilẹ jẹ pe ọtọ lẹni ti Oluaye Fuji n fi aṣa naa pọn le nigba yẹn, amọ ibeere t’awọn ololufẹ gbajumọ oṣere-binrin onitiata nni, Yvonne Jẹgẹdẹ n beere lọwọ ara wọn lasiko yii niyẹn: ṣoo da a mọ too ba ri Jẹgẹdẹ?

Ohun to fa ibeere isọnu yii ni pe ẹni ba ri Jẹgẹdẹ lanaa tabi ijẹta, ti onitọhun ba ri irisi rẹ tuntun gẹgẹ bo ṣe fihan ninu awọn fọto ati fidio to gbe sori ikanni ayelujara Instagiraamu rẹ, tọhun aa ṣi oṣere-binrin adumaadan yii mọ, niṣe lo fa ori rẹ kodoro, gbogbo irun rẹ dudu minijọ to fi n ṣoge, to ṣalekun ẹwa rẹ lo ti ge danu, o pọn’mi fun baabaa (barber) patapata ni, afi bii t’awọn ilari Alaafin Ọyọ aye ọjọun, ti wọn maa n fa ori wọn kodoro.

Ohun to tun mu ki bi Yvonne Jẹgẹdẹ ṣe sọ ara rẹ di ‘adanri ọkọ iya alamala’ yii, gẹgẹ bii ẹfẹ t’awọn ọmọde fi maa n bu ẹni to ba fari kodoro, tubọ yaayan lẹnu ni pe, yatọ si iṣẹ tiata, obinrin yii tun maa n ṣiṣẹ afẹwa-pa’wo, ti wọn n pe ni Model tabi modelling lede oyinbo, o si lero lẹyin daadaa lori intanẹẹti. 

Eyi lo fi jẹ pe b’awọn eeyan ṣe ri irisi rẹ tuntun yii, to ṣe wọn ni kayeefi, niṣe ni kaluku n ṣe atare fọto Yvonne si ara wọn, ti ori ẹrọ ayelujara si n ho ṣọ̀ṣọ̀ fun ọrọ ati ero koowa wọn.

 

Ṣugbọn Yoruba bọ, wọn ni ti ko ba nidii, obinrin kii jẹ Kumolu. Jẹgẹdẹ funra rẹ ti sọ ohun to ṣokunfa ori fifa kodoro rẹ yii. Ninu ọrọ to kọ sabẹ fọto rẹ, o ni: 

“Mo nifẹẹ iṣẹ mi gidigidi, mi o fẹẹ dẹjaa pẹlu rẹ… Mo ri ara mi gẹgẹ bii irinṣẹ to gbọdọ gbe ero to yẹ jade. Bi ipa ti mo fẹẹ ko ninu fiimu gẹgẹ bi wọn ṣe ṣakọọlẹ rẹ ba gba ki n ṣe nnkan kan, ma a ṣe e ki ere naa le dun ko si wuyi. Yatọ si ti irisi mi to ṣara-ọtọ yii, mo tun ti n kẹkọọ bi sisọ ede Yoruba mi yoo ṣe tubọ dan mọran si i.”

Igba t’awọn ololufẹ Yvonne Jẹgẹdẹ ka ọrọ to kọ yii l’ọkan wọn ṣẹṣẹ balẹ pe ki I ṣe pe aburu kan de ba oṣere-binrin yii lo fi fa ori rẹ kodoro, ko saisan, aarẹ ko mu un, bẹẹ ni ko wọ ẹgbẹ awo, iṣẹ aje rẹ to yan laayo lo tori ẹ fa irun rẹ, o ṣetan, idi iṣẹ ẹni la a tii mọ’ni l’ọlẹ.

Yvonne Jẹgẹdẹ ati 2Face Idibia
Fathia Balogun
Iyabọ Ojo

Tẹẹ o ba gbagbe, ti Yvonne Jẹgẹdẹ yii kọ ni igba akọkọ ti iṣẹ tiata tabi orin kikọ yoo mu ki oṣere-binrin kan fa ori rẹ kodoro. Iyabọ Ojo, gbajumọ oṣere-binrin to mu lẹnu bii abẹ nni, ati Fathia Balogun, irawọ oṣere ilẹ Yoruba ti figba kan fa ori wọn kodoro lati le kopa to jọju ninu awọn fiimu agbelewo kan. Ẹ o tun ranti pe Yvonne yii naa ti fa ori rẹ ri ninu awo orin African Queen, iyẹn orin ololufẹ ti gbajumọ onkọrin taka-sufee nni, Innocent Ujah Idibia, t’awọn eeyan mọ si 2Face Idibia tabi 2Baba kọ l’ọdun 2004.

Leave a Comment

Your email address will not be published.

Start typing and press Enter to search