Itafaaji

Ijo ọpẹ lẹsẹ ree Ṣọla Ṣobọwale, ọmọ rẹ n re’le ọkọ

B’eeyan ba pade gbajumọ oṣere-binrin ilẹ wa nni, Ṣọla Ṣobọwale nibi to ti n f’ẹsẹ ra’jo, tabi t’eeyan wo fidio rẹ nibi to ti n jijo ọpẹ lori ẹrọ ayelujara, ko gbọdọ yaayan lẹnu rara, ti Madam Ṣobọwale to bẹẹ, o ju bẹẹ lọ fun ti aṣeyọri to ṣẹlẹ si oun at’ọmọ rẹ obinrin lopin ọsẹ to kọja yii, ọmọ ọhun lo d’ẹni ile ọkọ, ti Ṣọla naa si di Iya Iyawo, ni inu gbogbo wọn ba n dun ṣinkin bii ẹni jẹ tẹtẹ oriire.

Ṣe lati oṣu to kọja, iyẹn Ọkitoba, oṣu Kẹwaa ọdun 2024 yii ni Ṣọla Ṣobọwale ti n sọ ọrọ ọhun bii owe, bii ẹna, pe oun naa maa too di Iya Iyawo o, tori ọmọ oun obinrin ti ri ẹni bii ọkan rẹ, o ti ri ololufẹ to fẹẹ gbe e n’iyawo, o si ti n palẹmọ ile ọkọ, o ni gbogbo eto ti n to lọ labẹnu wẹrẹwẹrẹ.

Amọ lọjọ Aiku, Sannde, ọjọ kẹta, oṣu Kọkanla, ọdun 2024, oṣere to jafafa l’oko ere yii gbe fidio ifọmọ-fọkọ naa sori ikanni Instagiraamu rẹ pẹlu oriṣiiriṣii fọto rirẹwa ti tọkọtaya naa ya, lati fihan pe ọmọ naa ti kuro lori igba, ko saaye fun abẹlẹjayan kankan mọ, ọkọọyawo ti mu iyawo rẹ, oruka ti d’ọwọ na.

Nibi ti inu Ṣọla dun de, o sọrọ iwuri nipa ọkọ ọmọ rẹ yii, ko tiẹ pe e ni ọkọ ọmọ oun tabi ana rẹ rara, o ni ọmọ oun ni ọkunrin naa, o lọmọkunrin ti ọjọ iwaju rẹ dara ni, o ṣ’ọmọluabi, o si dun-un-wo l’ọkunrin.

Nigba to n sọrọ nipa ayẹyẹ ọjọ naa f’awọn ololufẹ lori ayelujara, Ṣọla ni:

“O ti bọ si i, adehun ti pari! Ọpẹ ni fun Ọlọrun. Ẹ kuu oriire o, ọmọbinrin mi ati ọmọkunrin mi tuntun.”

Awọn oṣere tiata ẹlẹgbẹ ti n ki Ṣọla Ṣobọwale kuu idunnu ati oriire yii, wọn si n ba a dupẹ lọwọ Ọlọrun. Bẹẹ ni wọn tun n ṣ’adura fun tọkọ-tiyawo tuntun naa pe ayọ ni yoo gbẹyin igbeyawo wọn.

Mide Martins ni: “Ẹ kuu oriire o.

Yẹmi Ṣolade ni: “Olootọ ni Ọlọrun o”.

Folukẹ Daramọla kọ ọrọ tiẹ bayii: Maami, mo ba yin yọ. Inu mi dun fun yin o, Mọmi. Ẹ ẹ jere gbogbo wọn lorukọ Jesu, amin.”

Fathia Balogun ni: “Ẹ kuu oriire naa.

Adẹrin-in-poṣonu nni, Wale Akorede ti ọpọ eeyan mọ si Okunnu sọ pe: Ọlọrun tobi l’ọba. O maa n duro ti awọn tiẹ nigba gbogbo ni. Oun lo ni gbogbo ogo. Lẹẹkan si i, ẹ kuu oriire naa Ma.”

Bayii ni awọn ololufẹ Iya Iyawo tuntun yii n ki i, wọn ṣi ba a yọ.


Leave a Comment

Your email address will not be published.

Start typing and press Enter to search