Itafaaji

Oṣu kan lẹyin iku iyawo rẹ, agbabọọlu yii fo ṣanlẹ, o ku!

Agbo ere idaraya nilẹ wa, paapaa ti bọọlu alafẹsẹgba ko daraya lasiko yii, inu ibanujẹ ati idaro ni ọpọ awọn ololufẹ ere naa wa bayii, latari iku ojiji to mu ọkan lara awọn ẹlẹsẹ ayò to ṣẹṣẹ n goke agba bọ, Ọgbẹni Gift Atulewa lọ laaarin wọn, bẹẹ kò tii ju oṣu kan pere lọ ti Oloogbe, ẹni ọdun mejidinlogoji (38) yii padanu iyawo rẹ, niṣe lobinrin naa ku lairoti.

Gẹgẹ bi Ọgbẹni Azuka Chiemeka, tii ṣe agbẹnusọ fun ẹgbẹ agbabọọlu alafẹsẹgba ni ipinlẹ Delta (Delta State Football Association) ṣe fidi rẹ mulẹ, Atulewa, to figba kan wa lara ikọ agbabọọlu Naijiria tọjọ-ori wọn ko ju ẹni ogun ọdun lọ, ta teru nipaa laṣaalẹ ọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ọjọ kejila, oṣu Kọkanla, ọdun 2024 yii latari aisan ẹjẹ riru to ti n ba a finra fun igba pipẹ.

Azuka ṣalaye ninu atẹjade kan pe: “O ma ṣe o, oṣu to kọja yii la ṣẹṣẹ sinku iyawo rẹ, afaimọ ni kii ṣe iku aya rẹ yii lo tubọ ṣakoba fun ọkunrin naa. Loootọ lo ni aisan ẹjẹ riru, amọ o n mọju to o daadaa, afi bi aarẹ naa ṣe legbakan si i lọjọ to ṣaaju ọjọ iku rẹ, a si du ẹmi rẹ o, a gbe e de’le iwosan, wọn lo ni aisan ibà, sibẹ ifunpa rẹ ga, gbogbo b’awọn dokita ṣe gbiyanju to, o papa ja si iku ni.”

Azuka fikun un pe: “Ba a ṣe n sọrọ yii, idije awọn agbabọọlu agbaye tẹlẹri kan n lọ lọwọ nipinlẹ Delta, Oloogbe yii si wa lara awọn agbabọọlu to n kopa ninu rẹ, o n ṣoju agbegbe Uwei to ti wa, tiyanu-tiyanu lọ sì fi gba bọọlu akọkọ s’áwọ̀n nigba to lanfaani bọọlu gbe-e-silẹ-gba-a gẹgẹ bii iṣẹ rẹ. Ko tii ju ọsẹ mẹta lọ to gba bọọlu ọhun s’áwọ̀n lo ku yii.”

ITAFAAJI tun fidi rẹ mulẹ pe aipẹ yii l’Oloogbe naa dari wale lati orileede Cote d’Ivoire, nibi to ti lọọ kẹkọọ iṣẹ akọni-mọ-ọn-gba, to si gba iwe-ẹri.

Ọgọọrọ awọn alakooso ere bọọlu alafẹsẹgba at’awọn ololufẹ ọkunrin naa ni wọn ti n ṣedaro rẹ.

Ọgbẹni Ṣina Oludare, gbajumọ akọroyin ere idaraya sọ lori ikanni rẹ pe: O ba mi l’ọkan jẹ lati gbọ ti iku Gift Atulewa. Gift wa lara ikọ agbabọọlu tọjọ-ori wọn ko ju ogun ọdun lọ, to kopa ti wọn si gba ẹbun ipo keji ninu idije fun ife-ẹyẹ agbaye eyi ti ajọ FIFA ṣeto rẹ lọdun 2005 lorileede Netherlands (2005 FIFA U-20 World Cup). O dun mi pe ko tun raaye fakọyọ mọ lati igba yẹn”.

Ololufẹ ere bọọlu mi-in, Abele Onuwa sọ pe: “Iku Atulewa yii dun-un-yan gan-an. Ẹni ti mo mọ daadaa ni, o ṣ’ọmọluabi, o si lawọ.”

Iku Gift Atulewa yii ni eni kẹta lara ikọ Flying Eagles igba yẹn to ti doloogbe, lẹyin Isaac Promise ati Olufẹmi Adebayọ ti wọn ku lọjọsi.

 

 

Leave a Comment

Your email address will not be published.

Start typing and press Enter to search