Itafaaji

Tori ọmọ tuntun Dayọ Amusa, awọn aye wọle adura fun Mo Bimpe

Pẹlu bi idunnu ati orin ọpẹ ṣe gba ẹnu gbajugbaja oṣere-binrin ilẹ wa to rẹwa daadaa nni, Dayọ Amusa kan, latari bi o ṣe kuro lawujọ awọn ‘a-n-bẹ’lọrun’ lọjọ Aje, Mọnde, ọjọ kejidinlogun, oṣu Kọkanla, ọdun 2024 yii, ti Eledua fi ọmọ tuntun jojolo, ọmọ kulumbu ta a lọrẹ, to si bimọ ọhun nirọwọ-irọsẹ, afaimọ lawọn eeyan ko ti ko aarẹ ọkan ati ironu ba oṣere-binrin onitiata ẹlẹgbẹ rẹ kan, Adebimpe Oyebade, iyawo eekan oṣere tiata nni, Lateef Adedimeji, pẹlu bi ọpọ awọn ololufẹ rẹ ṣe bẹrẹ si i rọ’jo adura fun un, wọn loun lo ku t’awọn n duro de, awọn fẹẹ gbọ igbe ayọ lọọdẹ rẹ, awọn kan tiẹ da’jọ si i pẹlu, wọn ni niwonyi amọdun, iyẹn 2025 to wọle de tan yii, awọn fẹẹ wa ba oun naa ṣe ikomọ, ọmọ meji lawọn si tọrọ lọwọ Ọlọrun fun un, Taye-Kẹyin, Ẹdunjọbi ọba ọmọ.

Ṣe lati ọjọ Mọnde ti olobo iroyin ayọ ti ta s’awọn eeyan leti, pe Dayọ Amusa ti bimọ ọkunrin lanti-lanti siluu Amẹrika lawọn oṣere at’awọn ololufẹ obinrin naa ti n rojọ ikini sori ikanni ayelujara Instagiraamu rẹ, agaga nigba ti Iya ikoko naa gbe fọto ọmọ tuntun naa sibẹ, to si fi tayọ-tayọ kéde pe: “Allihamudulilahi. Iṣura iyebiye mi ti de o. Ọmọkunrin ni o”.

Adebimpe, t’awọn eeyan tun n pe ni Mo Bimpe wa lara ọgọọrọ onitiata to kọkọ ki Dayọ kuu oriire, o ni: “Yaay, Oluwa ṣeun, ẹ kuu oriire nla yii o, Mama,” bẹẹ lo fi ami ijo, idupẹ, ati ifẹ si i.

Ikini yii lawọn eeyan kan tẹba ti, ti wọn bẹrẹ si i fi ọkan-o-jọkan ọrọ adura ranṣẹ si iyawo Lateef Adedimeji.

Tọpẹfad ni: “Mo Bimpe, iwọ lo kan lagbara Oluwa. Mo ki ẹ kuu oriire ṣaaju o, mai dia.”

Herrwwabeddings ni: “Mo Bimpe, awọn ibeji ẹ ti n bọ lọna o, Bisimilahi, a maa wa ba ẹ dáwọ̀ọ́ idunnu laipẹ”.

Oluyinkasolution ni: “Mo Bimpe, iwọ ni ọrọ yi kan, a gbọdọ ki ẹ kuu oriire laipẹ.”

Princess Ade Ọmọọba ni: Mo Bimpe, iwọ naa a dawọọ idunnu tiẹ laipẹ o.

Semzeez sọ pe: Mo Bimpe, o maa ri awọn ibeji rẹ ni 2025 insha Allah bijahi rosululahi.

Ojofeitimifunmi naa kọ ọrọ tiẹ pe: Mo Bimpe, iwọ lo kan o, olufẹ mi. Gbogbo aye maa ba ẹ yọ, wọn si maa ki ẹ kuu oriire laipẹ.

Amọ ṣa o, gbogbo b’awọn eeyan ṣe darukọ Mo Bimpe ti wọn si n rọjo adura fun ní mesan-an mẹwaa yii ko dun mọ awọn kan ninu, oju to yatọ si ni wọn fi wo ọrọ naa. Ẹnikan sọ lori ikanni ọhun pe: “Ṣe ẹ tun ti bẹrẹ iwa were yin?”

 Ẹlomi-in tun ni: “Abẹẹ ri wọn bayii? Aya Mo Bimpe gan-an aa maa ja lati ki-i-yan kuu oriire bayii ni o, nitori gbogbo awọn amẹbọ ti wọn kii ṣọ’gba wọn.

Bẹẹ lawọn kan ti n ta’hun si ara wọn lori ikini ati adura ti n rọ’jo rẹ fun Mo Bimpe.


Leave a Comment

Your email address will not be published.

Start typing and press Enter to search