Yoruba bọ, wọn ni ọrọ ṣe’ni wo, ka le m’ẹni to f’ẹni. Ọrọ yii lo ṣe rẹgi pẹlu ohun to ṣẹlẹ si gbajumọ oṣere-binrin onitiata to rẹwa daadaa nni, Bimbọ Ademoye, pẹlu bo ṣe bu sẹkun ni gbangba,
lode ariya ayẹyẹ igbeyawo ọrẹ rẹ kan, o ni oju lo ro oun bi ọrẹ oun atata yii ṣe n lọọ ile ọkọ, oun si gbiyanju lati pa omije naa mọra, amọ ko r’ọgbọn ẹ da, afigba to ko oun sita bii ọmọ ọjọ mẹjọ poo.
Obinrin aṣerunloge kan, Valerie Okeke, lo jẹ ọrẹ timọtimọ pẹlu oṣere tiata ilẹ wa, Bimbọ Ademoye, ṣugbọn ogun ọmọde ko le ṣere f’ogun ọdun, laarin ọsẹ to lọ yii ni ọrẹ Bimbọ rele ọkọ, to di iyawo oloruka lọọdẹ ọkọ.
Ninu fidio kan to n ja ranyin lori ẹrọ ayelujara lọwọlọwọ, ibi ayẹyẹ igbeyawo Valerie yii ni Bimbọ Ademoye lọ, o si wa lara awọn ọrẹ iyawo ọjọ naa, ti wọn wọ aṣọ ‘ankoo’ alawọ buluu, ti wọn si mu ode ọjọ naa larinrin.
Nigba to di asiko ti wọn n pe awọn ọrẹ tọkọ-taya lati waa sọrọ nipa iyawo ọṣingin, atawọn to fẹẹ fi adura sin iyawo sọna, wọn pe Bimbọ Ademoye, o si bọ sori pepele lati sọrọ, amọ bo ṣe gboju soke, ti oju oun ati iyawo naa ṣe mẹrin, to si tun wo awọn ero rẹpẹtẹ ti wọn tẹti lati gbọ ọrọ rẹ, niṣe l’omije ayọ gbọn oṣere-binrin yii, o di maikirofoomu mu, o gbe e sẹnu lati sọrọ, amọ ko ṣee ṣe, ẹkun lo n gbọ ọn, bo ṣe n tiraka lati pa a mọra, bẹẹ lomije le roro s’oju rẹ.
Ọpẹlọpẹ ọkan lara awọn ọrẹ iyawo ẹlẹgbẹ rẹ to sare lọọ ba a lori pepele to wa, to si dọgbọn rẹ ẹ lẹkun, o fun un niṣiiri lati sọrọ, sibẹ naa, aaro to sọ Bimbọ Ademoye ko jẹ ko ri ri ọrọ gidi kan sọ to fi bọọlẹ, nigba tawọn ero naa bẹrẹ si i patẹwọ fun un.
Oriṣiiriṣii ọrọ lawọn ololufẹ Bimbọ ti sọ nipa iṣẹlẹ yii. Awọn kan ni o dara bi oṣere-binrin yii ṣe fi imọlara rẹ han, wọn niṣe lo fihan bo ṣe nifẹẹ ọrẹ rẹ to n re’le ọkọ to, o ṣetan, àsun-tọ̀nà lẹkun oge, bi Yoruba ṣe maa n sọ, ati pe ẹkun ayọ leyii, ki i ṣe ẹkun ibanujẹ.
Bankọle ni: Eleyii wọọyan lọkan o, o si mu ori ẹni wu.
Ṣakirati Adetunji ni: Eeyan bi temi ni Bimbọ Ademoye yii o, olori gaari ni wa, ori wa ki i pẹẹ wu, pẹlẹ o, ọrẹ iyawo.
Ẹlomi-in si tun sọ pe: “Mo n reti ohun to maa ṣẹlẹ nigba ti Bimbọ funra ẹ ba n rele-ọkọ, omije aa pe omije ranṣẹ lọjọ yẹn o, tori obinrin yii mọ ẹkun i sun. Amọ Bimbọ yii rẹwa lobinrin ṣa o.” Ati bẹẹ bẹẹ lọ.