Itafaaji

Iku Baba Suwe: Yọmi Fabiyi sọ’ko ọrọ!

Owe Yoruba lo sọ pe: Arokan, arokan, ni i mu ẹkun asun-un-da wa. Eyi lo difa fun ogulutu ọrọ ti gbajugbaja oṣere tiata nni, to tun maa n ṣiṣẹ ajafẹtọọ-ọmọniyan, Yọmi Fabiyi, Araba gbogbo awọn onitiata, ṣẹṣẹ ju sode nipa iku ọga rẹ, toun naa jẹ gbajumọ adẹrin-in poṣonu ati eekan lagboole ere ori itage, paapaa julọ, ni ilẹ Yoruba, Oloogbe Babatunde Omidina, ti ọpọ eeyan mọ si Baba Suwe, ọkọ Mọladun Kẹnkẹlẹwu. 

Lori ikanni ayelujara rẹ, loju opo Instagiraamu, ni Yọmi Fabiyi gba lọ l’Ọjọruu, Wẹsidee, ọjọ kẹrin, oṣu Kejila, ọdun 2024 yii, lati sọ ero ọkan rẹ jade, niṣe lo sọrọ ọhun bii amọran, amọ ọrọ to kẹnu ni, ọpọ awọn to si ka ohun to kọ nipa iku Baba Suwe ati ohun toju rẹ ri ko too dẹni akọlẹbo, ni wọn sọ pe ọrọ ọhun gba arojinlẹ gidi, wọn ni oko ọrọ nla ni.

Yọmi Fabiyi gbe fidio ifọrọwanilẹwo kan to ṣe nigba ti Baba Suwe wa ninu aarẹ, latari bawọn ajọ to n gbogun ti gbigbe ati ilo egboogi oloro nilẹ wa, National Drug Law Enforcement Agency, NDLEA, ṣe mu un sahaamọ wọn, ti wọn si fooro ẹmi rẹ lori ẹsun gbigbe egboogi oloro, ti wọn lo gbọdọ ‘ṣu dundun’ bii itan ijapa ọkẹrẹ aye ọjọun, ti wọn si foju rẹ ri mabo, ati fidio ibi ti Baba Suwe ti sọrọ nipa Yọmi Fabiyi, to ni ọmọọṣẹ oun gidi nidii iṣẹ tiata ni.

Labẹ awọn fidio yii ni Yọmi kọ ọrọ rẹ si, ọrọ ọhun lọ bayii:

“Oloogbe Alaaji Babatunde Omidina, ti ọpọ eeyan mọ si Baba Suwe jẹ ọkan lara awọn eeyan to kagbako fifi ẹtọ ẹni duni ati aiṣe idajọ-ododo. Ọpọ ẹkọ ni mo kọ nipa igbe aye wọn ati wahala to de ba wọn. Ẹni ba wa laye, to n jaye ẹ laisi wahala ati aisan, ki tọhun maṣe ro lae pe oun ni ọrẹ ati alajọṣiṣẹ ti wọn nifẹẹ ẹ denu o.

“O digba ti iṣẹ ẹ ko ba lọ deede mọ tabi ti wahala ba fẹẹ pin ẹ lẹmi, igba yẹn ni waa mọ pe ko si awọn ọrẹ kan nibi kan. Tori ẹ, o san keeyan ma ṣe aye ẹ ni dodo-n-dawa.

“Ki n sododo ọrọ, ẹ tete lọ maa fi kọra lati maa ṣe aye yin lẹyin nikan o. Mi o ni keeyan ma lọrẹẹ ati ojulumọ, amọ keeyan maa ronu lemọlemọ nipa boun ṣe le da rin nigba ti ko ba sẹnikan mọ. Ki i ṣe ti igberaga o, koda ọna teeyan fi le di alagbara niyẹn o”. O si kọ orukọ ara rẹ sabẹ ọrọ naa.

Ọpọ eeyan lo fesi si ohun ti Yọmi Fabiyi kọ yii. Ẹnikan to pe orukọ ara ẹ ni Dare Adedeji ni: “Baba Suwe ko si pampẹ ni, o si baayan lọkan jẹ pe ko si aladuroti gidi kan fun un laarin awọn onitiata ẹlẹgbẹ rẹ. O ma ṣe o! Ọlọrun aa bu kun fun ẹ, Yọmi Fabiyi, fun iṣẹ rere too n ṣe.

“Hype_Frosh_Jago ni: “Ko kuku sẹni to maa faye yii silẹ lai gba ẹsan iṣẹ to ba ṣe. Ki Ọlọrun fun ẹmi rẹ ni isinmi o. Mo gboṣuba fun ẹ o, Yọmi Fabiyi.

Kẹmi Ọlajide ni: “Iwa wa ni orileede Naijiria yii toju su mi. Ko daa rara.”

Bẹẹ lẹnikan tun sọ pe: “K’Ọlọrun ma jẹ ki eeyan ri ohun ti wọn n pe ni Naijiria ni o. Sun ire o, Baba Suwe. Iṣẹ ọwọ rẹ ko le parun, o ṣi wa sibẹ.

Ẹlomi-in tun ni: Awọn NDLEA ni wọn da ẹmi Baba Suwe legbodo. Oro nla ni wọn da o. Idajọ ododo ko le fidi mulẹ lorileede yii laelae. Gbogbo nnkan lo ti wọ!”

Bayii lawọn eeyan sọ.

 

 

Leave a Comment

Your email address will not be published.

Start typing and press Enter to search