Bi wọn ba n beere ‘ọmọ ti wọn n sọ’ lasiko yii lagbo ere idaraya lorileede Naijiria ati nilẹ Afrika lapapọ, agaga bo ba jẹ nidii ere bọọlu alafẹsẹgba, ẹyẹ meji ki i jẹ adiẹ ni ti Ademọla Lookman, ọdọmọkunrin ẹni ọdun mẹtadinlọgbọn ti irawọ rẹ n ran bii oorun lọwọlọwọ. Ni bayii, wọn ti fun un ni awọọdu agbabọọlu ti mùṣèmúṣè rẹ dá múṣémúṣé julọ nilẹ Africa, wọn loun lo gbe ounjẹ f’ẹgbẹ to si tun gba àwo bọ̀ nidii ere bọọlu alafẹsẹgba.
Nibi ayẹyẹ pataki kan ti ajọ to n ṣakoso ere bọọlu alafẹsẹgba nilẹ Africa, Confederation of African Football, CAF, diidi ṣeto rẹ lati yan awọn elere idaraya to laami-laaka julọ nilẹ adulawọ, ti wọn yoo si fi ọkan-o-jọkan ẹbun da wọn lọla, eyi to waye laṣaalẹ ọjọ Aje, Mọnde, ọjọ kẹrindinlogun, oṣu Kejila, ọdun 2024 yii, niluu Marrakesh, lorileede Morocco ni wọn ti de ọdọmọkunrin naa lade.
Eyi ni igba akọkọ ti Lookman, ọmọ bibi orileede Naijiria, to n gba bọọlu agbabuta fun ẹgbẹ agbabọọlu Atalanta ninu idije líìgì Serie A niluu oyinbo, yoo gba ẹbun agbabọọlu to fakọyọ julọ nilẹ Africa, eyi si ni igba kẹfa ti ọmọ Naijiria yoo gba iru ẹbun banta-banta bẹẹ latigba ti wọn ti gbe eto naa kalẹ.
Lara awọn agbabọọlu ọmọ Naijiria to ti gba awọọdu yii sẹyin ni Emmanuel Amuneke, Oloogbe Rashidi Yẹkinni, Kanu Nwankwo gba a lẹẹmeji leralera, Victor Ikpeba ati Victor Osimhen to gba a ti ọdun 2023 to kọja yii.
Fun ti ọdun 2024 yii, ojubọrọ kọ laa fi gba ọmọ lọwọ ekurọ lọrọ ọhun jẹ fun Lookman Ademọla, nitori awọn ẹlẹsẹ ayo to lookọ, ti wọn si fakọyọ bii tiẹ lo ba figa-gbaga lasiko iyansipo rẹ. Lara orukọ tawọn onidaajọ ajọ CAF ranju mọ lati yẹ wọn wo finni-finni ki wọn too yan Lookman ni Ọgbẹni Achraf Hakimi, to da bii opomulero lọwọ ẹyin fun ikọ agbabọọlu orileede Morocco, Ọgbẹni Serhou Guirassy toun jẹ ẹlẹsẹ ayo fun ikọ orileede Guinea, Ọgbẹni Simon Adingra, ẹtu obeje ẹlẹsẹ ọwọ lori papa lati orileede Ivory Coast ati Ronwen Williams, aṣọle to peju owo fun ikọ agbabọọlu orileede South Africa.
Ṣe Yooba bọ, wọn ni bọmọ ẹni ba dara ka wi, bii ti ka fi i ṣaya kọ, ọdọmọkunrin to n fi bọọlu alafẹsẹgba da bira lori papa nile ati lẹyin odi ni Lookman Ademọla. Lara aṣeyọri rẹ ti ko ṣee gbagbe bọrọ ni ti bo ṣe gba bọọlu gbe-e-silẹ-gba-a, eyi tawọn eleebo n pe ni hat trick kan, fun ẹgbẹ agbabọọlu Atalanta rẹ, ninu idije liigi Europa, bo ṣe gba bọọlu ọhun sawọn lo mu ki ẹgbẹ agbabọọlu naa jawe olubori ifẹsẹwọnsẹ wọn pẹlu ẹgbẹ agbabọọlu Bayer Leverkusen pẹlu ami ayo mẹta si odo niluu Dublin, loṣu Karun-un ọdun 2024 yii. Eyi lo ta epo si aṣọ ala Bayer Leverkusen ti ko tii sẹni to le fidi wọn rẹmi ninu ifẹsẹwọnsẹ mọkanlelaaadọta ṣaaju asiko yẹn, bakan naa ni aṣeyọri ọjọ naa tun mu ki Atalanta gba ife ẹyẹ kilọọbu to peregede julọ ninu liigi ọhun, bẹẹ eyi ni igba akọkọ ti wọn maa jijo ayọ bẹẹ lati ọdun 1963 ti wọn ti n ja fitafita bọ. Ọpẹlọpẹ Lookman yii, ẹẹmẹjọ ọtọọtọ lo gba bọọlu sawọn lati ri i pe ẹgbẹ agbabọọlu rẹ goke agba, ti wọn fi le tente soke patapata laaarin awọn agbabọọlu liigi wọn ọhun.
Bakan naa ni ọdọmọkunrin to san-an-gun daadaa yii kopa to jọju ninu bi ikọ agbabọọlu Super Eagles ti orileede rẹ, Naijiria, ṣe peregede lati darapọ mọ awọn agbabọọlu to maa dije fun ife ẹyẹ to gbayi julọ nilẹ Africa, iyẹn Africa Cup of Nations, AFCON, ti ọdun 2025.
Tẹẹ o ba gbagbe, latari bi irawọ rẹ ṣe n ran bii oorun, ti okiki rẹ si n kan kaakiri, Lookman yii wa lara awọn agbabọọlu ti wọn ajọ to n ṣakoso ere bọọlu alafẹsẹgba lagbaye, iyẹn ajọ FIFA, ṣe ayẹwo orukọ wọn lati yan agbabọọlu to da-n-tọ julọ lagbaye lọdun 2024, oun nikan ṣoṣo si ni agbabọọlu ti wọn darukọ rẹ bẹẹ lati ilẹ Africa, bo tilẹ jẹ pe ipo kẹrinla lo papa bọ si lasiko ayẹwo ọhun, Huge Rodri lo gba ẹbun naa lọdun yii.