Yoruba bọ, wọn ni ebi nii pa’ni bakan naa, amọ ọrọ ki i dun’ni bakan naa. Owe yii lo ṣe gẹgẹ iṣẹlẹ aburu kan to waye lagbegbe kan lorileede Gabon nigba ti ojo arọọda fa akunya omi fawọn araalu ọhun, eyi to mu ki Aarẹ orileede wọn, Ọgagun Brice Oligui Nguema ṣabẹwo sagbegbe naa.
Amọ ko sohun toju ko ri ri ninu ki aarẹ orileede ṣabẹwo ibanikẹdun sibi ti ijamba ba ti waye lorileede rẹ, ohun to jọni loju ninu ọrọ ti Aarẹ orileede Gabon yii ni pe, nigba ti ojo naa ṣi n rọ lọwọ, ti ọgbara ojo si ṣi n ko ṣibaṣibo ba awọn araalu, asiko naa gan-an ni Aarẹ Nguema ko awọn isọmọgbe rẹ lẹyin, ti wọn ko sinu ọkọ ayọkẹlẹ ni waranṣeṣa, ti wọn si lọọ ṣabẹwo sibi iṣẹlẹ naa.
Aarẹ orileede Gabon lo n f'ẹsẹ̀ wọ́ ọ̀gbàrá ati ẹrọfọ yii
Awọn minisita ati oṣiṣẹ Aarẹ naa kò gbẹ́yìn
Bi wọn ṣe n bọọlẹ, wọn ri ọgọọrọ awọn arugbo, gende, ọkunrin ati obinrin ti omiyale ti pọn loju, awọn kan gori orule ile, bẹẹ lawọn mi n du ọna ati sa asala lọwọ, niṣe ni Aarẹ yii ko sinu ọgbara naa taaanu-taaanu, bẹẹ lo n rin lọ, bi ọgbara ti n wọ ọ lẹsẹ, loun naa n dura, awọn ẹṣọ alaabo ti wọn wa lẹyin rẹ paapaa gba tẹle, koowa wọn ni wọn ko sinu alagbalugbu ẹrọfọ ti ọgbara naa n ṣan kọja, wọn si n ba ara wọn sọrọ lati wo ṣakun bi wọn yoo ṣe dena iru ajalu buruku bẹẹ.
Ohun kan to ṣeni laaanu ni ti ọmọ kekere jojolo kan ti ọkan lara awọn minisita Aarẹ gbe jade ninu omiyale naa, kia ni Aarẹ Nguema gba ọmọ naa lọwọ minisita rẹ, o gbe ọmọ ọhun mọra, bo ṣe n fẹ ẹ loju lo n fẹ ẹ nimu, o si ṣaajo rẹ, bo tilẹ jẹ pe aarin ọgbara ni wọn wa, gbogbo bata ati ṣokoto wọn ni omi ati ẹrọfọ ti rin gbingbin.
O han pe inu awọn araalu naa dun fun ẹmi ibanikẹdun ti Olori ilu wọn fi han yii. Ọpọ awọn eeyan ti wọn ri fidio iṣẹlẹ yii lori ẹrọ ayelujara ni wọn ti n kan saara si aarẹ orileede naa, wọn ni ẹlẹyinju aanu ati eeyan to lẹmi-in ifara-ẹni-rubọ gbaa ni.
Awọn kan si tun sọ pe ara idi to fi yẹ kawọn orileede ilẹ adulawọ, iyẹn ilẹ Afrika ṣagbatẹru fawọn ọdọ lati de ipo aṣẹ niyi, wọn ni bi Olori orileede tọjọ ori rẹ wa lẹni aadọta ọdun yii ṣe n ta pọun-pọun laaarin omiyale lati ṣaajo awọn eeyan rẹ fihan pe okun ati agbara awọn ọdọ ran an lọwọ, ko si le rọrun fun arugbo lati ṣe iru akitiyan bẹẹ.
Ṣa, wọn ni apẹẹrẹ atata ni ohun ti Aarẹ Nguema ṣe yii jẹ fawọn olori gbogbo kari aye, bo tilẹ jẹ pe oju ọtọ lawọn mi-in fi wo o, wọn ni orileede kekere ni Gabon, a o si le fohun to n ṣẹlẹ nibẹ wera pẹlu Naijiria, nitori ‘agba l’ẹtù, ọmọde l’awó’.