Ijọba ma tun fẹẹ yọ Alaafin Ọyọ tuntun nipo!

Alaafin Ọyọ, Ọba Akeem Abimbola Ọwọade

Awuyewuye to ti n ja ranyin labẹlẹ eyi to n ṣe gbogbo eti to n gbọ nipa rẹ ni kayeefi lo ti n rugbo bọ nipinlẹ Ọyọ ati ilẹ Yoruba bayii, agaga laaarin awujọ awọn lọbalọba ati awọn oloṣelu, latari igbesẹ abẹnu kan to n lọ lọwọ lati paarọ ipo Alaafin Ọyọ laarin awọn ọba ipinlẹ Ọyọ.

Bi atẹgun ọrọ ọhun ṣe n fẹ fin-in bii iso buruku, bẹẹ lo ti n da omi tutu sọkan awọn araalu, ti ọpọ eeyan si ti n beere pe iru igbesẹ buruku wo ni ijọba Ọyọ tun fẹẹ rawọ le yii, wọn ni ṣe kii ṣe wahala tuntun lo n bọ yii o.

Alaafin tuntun

Ọrọ ọhun ko ṣẹyin abadofin kan to ti wa niwaju ileegbimọ aṣofin ipinlẹ Ọyọ bayii, ninu eyi ti wọn ti fẹẹ da ofin to to ti wa nilẹ lati ọjọ pipẹ nu bii omi iṣanwọ, eyi to fidi ipo Alaafin Ọyọ mulẹ gẹgẹ bii Ọba kan ṣoṣo ti yoo maa ṣe alaga gbogbo awujọ awọn ladelade porongodo nilẹ Yoruba, ti ko si si ọba mi-in to tun gbọdọ wa nipo Alaga naa yatọ si Alaafin nikan.

Wọn ni wọn ti peelo abadofin tuntun ti yoo wọgile ipo ati agbara Alaafin yii, ti yoo si ṣi anfaani silẹ fawọn ọba miiran lati wa ṣe alaga apero awọn ori-ade gbogbo ọhun.

… wọn ti pèèlò àbádòfin tuntun ti yoo wọ́gilé ipo ati agbara Alaafin yii,…

Bi ITAFAAJI ṣe gbọ, abadofin tuntun yii eyi ti wọn pe akọle rẹ ni Abadofin Igbimọ awọn Ọba ati awọn Oloye ti a ti ṣatunṣe si lọdun 2025 (Council of Obas and Chiefs – further Ammendment Bill 2025) ti wa niwaju ileegbimọ aṣofin Ọyọ, awọn aṣofin marun-un ọtọọtọ ni wọn ṣagbatẹru abadofin naa, Olori ileegbimọ aṣofin Ọyọ, Abẹnugan Adebọ Ogundoyin, si wa lara wọn.

Apero awọn ori-ade Ọyọ
Alaafin, Olubadan, Ṣọun

“Nigbakuugba ti Igbimọ lọbalọba Ọyọ ba n ṣe ipade, Alaafin Ọyọ ni yoo jẹ alaga ti yoo si maa dari ipade naa, amọ ti Alaafin ko ba si nikalẹ, Olubadan ti ilẹ Ibadan yoo rọpo rẹ, yoo bọ si ipo alaga, yoo si dari ipade, bo ba si jẹ Alaafin ati Olubadan ni ko si nipade, amọ ti Ṣọun ti ilẹ Ogbomọṣọ wa nibẹ, Ṣọun ni yoo ṣe Alaga apero awọn lọbalọba.”

Ninu abadofin naa ni wọn ti petepero rẹ pe: “Nigbakuugba ti Igbimọ lọbalọba Ọyọ ba n ṣe ipade, Alaafin Ọyọ ni yoo jẹ alaga ti yoo si maa dari ipade naa, amọ ti Alaafin ko ba si nikalẹ, Olubadan ti ilẹ Ibadan yoo rọpo rẹ, yoo bọ si ipo alaga, yoo si dari ipade, bo ba si jẹ Alaafin ati Olubadan ni ko si nipade, amọ ti Ṣọun ti ilẹ Ogbomọṣọ wa nibẹ, Ṣọun ni yoo ṣe Alaga apero awọn lọbalọba.”

Ohun ti abadofin yii tumọ si ni pe ipo ati agbara Iku Baba Yeye, iyẹn Alaafin Ọyọ lati jẹ Alaga kan ṣoṣo titi gbere fun awọn lọbalọba ipinlẹ Ọyọ yoo di pinpin sọna mẹta ni gbara ti wọn ba ti gba abadofin naa wọle ti wọn si sọ ọ di ofin, ipo ati agbara naa yoo si maa wa laaarin Alaafin, Olubadan ati Ṣọun. 

Alaafin Ọyọ, Iku Baba Yeye
Ṣọ̀ún tilu Ogbomọṣọ
Olubadan ilẹ Ibadan
Awujọ awọn lade-lade Ọyọ

Amọ ṣa o, bo tilẹ jẹ pe awọn aṣofin ṣẹṣẹ fẹẹ bẹrẹ ijiroro lori abadofin naa ni, amọ olobo ọrọ ọhun to ta awọn ori ade kọọkan, paapaa awọn awujọ awọn Ọba agbegbe Oke-Ogun, awọn loyeloye ati awọn alẹnulọrọ ti fihan pe afaimọ ni ọrọ yii ko ni i fa lọgbọlọgbọ pupọ laaarin awọn lọbalọba atawọn araalu bi abadofin naa bo di ofin.

Leave a Comment

Your email address will not be published.

Start typing and press Enter to search