Haa! Awọn janduku kọlu Pasuma n’Ikire, wọn ba mọto ẹ jẹ!

Owe Yoruba kan sọ pe iku ti i ba pa’ni, bo ba ṣi ni fila, ka maa dupẹ ni o. Owe yii lo wọ bi iku aitọjọ ati ipalara ṣe fo ori ilumọ-ọn-ka onkọrin Fuji to lero lẹyin bii eegun Olóòlù nni, Alaaji Wasiu Alabi Ọdetọla, ti gbogbo aye mọ si Pasuma tabi Paso, lopin ọsẹ to kọja yii, niṣe lawọn ololufẹ ọkunrin naa n kii kuu ewu, ti wọn si n ṣepe buruku buruku fawọn to fẹ pana ẹṣọ Iba Baraka lojiji yii.

Ṣe Yooba bọ, wọn ni òwò ti àdá mọ ọn ṣe nii ka àdá léyín, Ọmọ Iyawo Anọbi ko kuku ṣadeede rode ijangbọn, ọkunrin naa ko si si lara awọn olorin to fẹran rogbodiyan, iṣẹ orin kikọ lo gbe Alabi Pasuma lọọ ilu Ikire, nipinlẹ Ọṣun lọjọ Satide, ọjọ kẹtadinlogun, oṣu Karun-un, ọdun 2025 yii, eto ayẹyẹ ifinijoye pataki kan ni olorin naa tori ẹ tẹkọ leti.

Lati irọlẹ ọjọ Satide naa titi di aṣalẹ gbẹ̀n ni Ọganla Fuji yii forin aladun da awọn ololufẹ rẹ lara ya, ni Gbọngan ayẹyẹ GT Events Centre to wa niluu Ikire, nibi ti ayẹyẹ ifinijoye Oloye Wasiu Ademọla Abdulsalam Ajanaku to joye Mọgbẹ̀dẹ̀ ti ilẹ Ikire ti waye.

ITAFAAJI gbọ pe ko si wahala kankan titi ti ere fi pari, ti kaluku si ti n kọri si ile rẹ lafẹmọju. Owurọ kutu ọjọ Sannde ọhun ni Pasuma ati awọn ọmọọṣẹ rẹ gbera lati maa pada bọ ni Eko ti wọn ti wa, asiko yii lawọn janduku kan lọọ dena de ọkọ ayọkẹlẹ ati awọn ọkọ ti wọn fi ko irinṣẹ ati ọmọọṣẹ olorin naa, wọn da wọn lọna, wọn n beere owo, koloju si too ṣẹ ẹ, ija ti di jagidi-jagan, nigba tawọn ọmọ ẹruuku naa fa ibọn yọ, tawọn kan lara wọn si n ju oko lu ọkọ ayọkẹlẹ Baa Wasi.

Ninu fọran fidio kan to gori afẹfẹ lẹyin iṣẹlẹ naa, ariwo nla lo n lọ labẹlẹ, bẹẹ ni ẹnikan to n ya fidio ọhun n fi ede gẹẹsi adamọdi ti wọn n pe ni pidgin sọrọ nibẹ, o ni: “Kasala ti bẹ niluu Ikire yii o, wọn ti kọlu wa o, ẹ wo mọto Paso, ọkọ Pasuma ree, wọn ti yinbọn lu wa, ẹ wo jiipu Pasuma, ẹ wo bi wọn ṣe ba mọto jẹ, awọn ara Ikire yii ti fa ijangbọn lẹsẹ o, amọ a dupẹ, Ọlọrun wa ṣa o…” ati bẹẹ bẹẹ lọ, bẹẹ lo n yaworan bọọsi ti wọn ya fọto Alabi Pasuma sara rẹ ọhun, ati ọkọ ayọkẹlẹ bọginni Hummer Jeep funfun to jẹ ti Pasuma, atawọn ọkọ mi-in, ati ibi ti wọn ti jùkò ba gilaasi ọkọ.

Gẹgẹ ba a ṣe gbọ, ko si ipalara kankan to ṣẹlẹ si Ọganla Fuji funra rẹ, oun atawọn ọmọọṣẹ rẹ si ti de ibugbe wọn pada ni Eko lalẹ ọjọ Sannde ọhun.

ITAFAAJI gbiyanju lati ba Pasuma sọrọ, amọ ko gbe aago rẹ, bẹẹ ni ko tii ṣee ṣe lati gbọ ọrọ lẹnu awọn ọmọọṣẹ rẹ.

Titi di ba a ṣe n sọ yii, ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ọṣun ko tii sọrọ lori iṣẹlẹ aburu yii.

Leave a Comment

Your email address will not be published.

Start typing and press Enter to search