Loootọ ni mo fibinu fọ Afeez Ọwọ leti – Yẹmi Ṣolade

Loootọ ni Yoruba n sọ pe bi ẹlẹjọ ba ti mọ ẹjọ rẹ lẹbi, ko nii pẹ lori ikunlẹ, amọ boya eekan oṣere tiata ilẹ wa yii, Alagba Yẹmi Ṣolade, yoo pẹ lori ikunlẹ abi bẹẹkọ ni ko tii daju, latari bi ọkunrin naa ṣe rawọ ẹbẹ ni gbangba pe oun tọrọ aforiji fun bi inu ṣe ṣi oun bi, toun fi di igbaju ru oṣere tiata ẹlẹgbẹ oun, Afeez Abiọdun, ti ọpọ eeyan n pe ni Afeez Ọwọ, tabi Seriki Ọlọpọlọ lagbo tiata.

Yẹmi Ṣolade rawọ ẹbẹ yii lasiko ifọrọwanilẹnuwo kan to ṣe pẹlu oniroyin ori-ẹrọ ayelujara lori eto Bahind the Fame African A-List laipẹ yii.

Nigba ti wọn bi ọkunrin naa leere pe njẹ iṣẹlẹ kan ti waye ri ninu iriri rẹ lẹnu iṣẹ oṣere to yan laayo, eyi to dun un wọra, to si kabaamọ rẹ, Yẹmi Ṣolade ko ronu jinna to fi sọ pe bẹẹ ni, o ni oun iṣẹlẹ kan toun ko le gbagbe ni boun ṣe fibinu gba Alagba Afeez Ọwọ leti nibi tawọn ti lọọ ya fiimu lọdun diẹ sẹyin.

Ṣolade ṣalaye pe lọjọ naa, agbegbe kan layiika ilu Ibadan, nipinlẹ Ọyọ lawọn wa, awọn ti ya fiimu tan, o si ti bọ si ọwọ alẹ patapata, lojiji ni ina mọnamọna lọ laaarin ilu, okunkun birimu birimu ba gbode.

O ni Afeez Ọwọ lo wa nipo Manija Agbe-fiimu-jade, eyi ti wọn n pe ni Production Manager lede oyinbo fun iṣẹ naa, apakan ojuṣe rẹ si ni lati pese ina ẹlẹntiriiki tawọn akopa nilo.     

Yẹmi Ṣolade ni: “Gẹgẹ bii Production Manager, oun la lọọ ṣaroye fun pe a nilo ina ẹlẹntiriiki, amọ ọkunrin naa mu inu bi mi pẹlu bi ko ṣe ka ọrọ wa kun, niṣe lo n fi aroye wa ṣe awada, nigba ti mo si da si i, ko tori ẹ yi pada, 

Ṣolade ni laaarọ kutu ọjọ keji ni Afeez Abiọdun ti kuro ni lokeṣan yẹn, awọn ko si raaye jọ sọrọ ko too lọ, o ni lati igba naa ni ẹri-ọkan oun ti maa n da oun lẹbi fun iwa toun hu lọjọ naa, ko si sigba toun ri Afeez Ọwọ toun ki i ranti iṣẹlẹ buruku ọhun.

“…mi o mọ igba ti ibinu mi ru soke, ti mo fi la a ni igbaju, mi o tiẹ mo ibi ti ifọti naa ti wa lojiji pẹlu.”

O kadii ọrọ rẹ, o ni: “Afeez, jọọ ma binu, mo tọrọ aforiji o. Ma binu si mi. O ti pẹ o, boya aa ti fẹrẹ to bii ogun ọdun si asiko yii, mo ti sọrọ nipa ẹdun ọkan mi yii fawọn eeyan tẹlẹ, amọ ẹ jẹ ki n kuku sọ ọ jade fun Afeez alara ni taarata bayii. Mi o nifẹẹ si keeyan tabuku si mi, mo si ro pe ọkan lara iku-diẹ-kaato mi niyẹn, jọọ ma binu o.”

Yẹmi Ṣolade lo n bẹ Afeez Ọwọ bẹẹ.

Leave a Comment

Your email address will not be published.

Start typing and press Enter to search