Nigba ti Ọbasanjọ, Atiku, Adeleke, Oyetọla ati Arẹgbẹṣọla pade n’Ileṣa…

Bi wọn ba n beere ibi ti ajọṣe ẹda eeyan ti kun fun ọrẹ loni-in, ọta lọla, ati ọrọ tawọn eeyan maa n sọ pe ‘ko si bara ẹ da sọhun nidii oṣelu, bara ẹ da sibi lo wa, agbo oṣelu ilẹ wa jẹ apẹẹrẹ ibi tiru awọn ọrọ wọnyi ti n ṣẹlẹ.
Ọkan lara iṣẹlẹ pataki bẹẹ ni ti ayẹyẹ igbade ọba tuntun to n lọ lọwọ niluu Ileṣa, nipinlẹ Ọṣun, nibi ti Ọwa Obokun ti ilẹ Ijẹṣa, Ọba Clement Adesuyi Haastrup, Ajimọkọ kẹta, ti n gba awọn eekan eekan lalejo fun ti igbade rẹ.

Nitori ipo pataki ti Ọba naa wa nilẹ Yoruba, gẹgẹ bii ọba onipo kinni nipinlẹ Ọṣun, ayẹyẹ to hẹrẹntẹ, ni ti igbade yii, eyi to jẹ igba kọkanlelogoji iru rẹ ti Ọwa ti n gori apere nilẹ Ijẹṣa.

Odidi ọsẹ kan gbako ni eto naa ti bẹrẹ, amọ lọjọ Ẹti, Furaidee, ọjọ kẹtalelogun, oṣu Karun-un, ọdun 2025 yii ni ayẹyẹ igbade ati gbigba ọpa aṣẹ waye, tawọn alejo pataki pataki peju pesẹ, ti Gomina ipinlẹ Ọṣun si ṣojuṣe rẹ lati fi Ọwa tuntun jẹ.

Ohun to gbafiyesi ni ti awọn alejo pataki kan ti wọn ọta nidii oṣelu ti wọn dabii ata ati oju, ti wọn ko gba ti ara wọn bi ekute ko ṣe fẹran ologbo, ti wọn si ti wọ ara wọn lọọ kootu ri nitori agbara iṣejọba ati ipo oṣelu, amọ ti wọn foju rinju lọjọ naa.

Lara wọn ni Oloye Oluṣẹgun Ọbasanjọ, Aarẹ orileede wa tẹlẹri, ati igbakeji rẹ nigba naa, Alaaji Atiku Abubakar, ti aarin wọn ko figba kan gun rege titi ti wọn fi pari iṣejọba lọdun 2007 ati lẹyin naa. Ko sẹni ti ko mọ bi Ọbasanjọ ṣe gbegi dina fun Atiku to lati depo aarẹ, ko si tii ṣee ṣe fun ọmọ bibi ipinlẹ Adamawa naa lati depo ọhun titi doni. Ninu agbada nla, aṣọ oye, ati fila ti wọn kọ akọle oye Ọtunba Atayeṣe ti Alaaji Atiku ati Iyawo rẹ, Titilayọ Abubakar to jẹ ọmọ bibi ilu Ijẹṣa ti wọn fi jẹ oye Yeye Atayeṣe ilẹ Ijẹṣa, lawọn mejeeji wọ.

Bakan naa ni Gomina ipinlẹ Ọṣun nigba kan, Alaaji Rauf Arẹgbẹṣọla, to fa ọpa iṣakoso le Alaaji Adegboyega Oyetọla lọwọ, amọ ti wọn pada waa di ọta ọrun o gbẹbọ lasiko yii, titi kan Gomina Adeleke to fẹyin Oyetọla janlẹ lasiko ibo, toun ati Arẹgbẹṣọla ti wọn ti jẹ ọta nigba kan tun pada di ọrẹ ti wọn fi taari Oyetọla kuro nipo, gbogbo wọn ni wọn pẹsẹ sibi ayẹyẹ naa.

Ninu awọn fọran fidio to gori afẹfẹ, Gomina Adeleke ki gbogbo awọn oloṣelu to wa nikalẹ, o bọ wọn lọwọ lọkọọkan, o si ki Ọba awọn ọba nipinlẹ naa, Ọọnirinṣa, Ẹnitan Ogunwusi pẹlu apọnle.

Bi ITAFAAJI ṣe gbọ, lati owurọ ọjọ Furaidee ọhun ni Atiku ati Iyawo rẹ ti de si ile Alaaji Arẹgbẹṣọla, ibẹ ni wọn ti jẹun owurọ, tawọn onilu ati olorin si n da wọn laraya ki wọn too kọri si aafin Ọba tuntun.

Ọba Hastruup yii ti figba kan jẹ Igbakeji gomina ipinlẹ Ọṣun, ki ori too de e lade.

Leave a Comment

Your email address will not be published.

Start typing and press Enter to search