Pẹlu iharagaga ati ayọ lawọn eeyan orileede Denmark fi kí aṣoju ijọba orileede Naijiria, Ambasadọ T. A. Elias Fatile, kaabọ lati ilu Stockholm, lorileede Sweden, lẹnu abẹwo mọ̀-mí-n-mọ̀-ọ́ rẹ si ilu Copenhagen, ni Denmark, lọjọ Abamẹta, Satide, ọjọ kẹrinlelogun, oṣu Karun-un, ọdun 2025 yii.
Aṣoju tuntun yii lo n ri si ọrọ ajọṣe iṣelu, okoowo ati igbaye-gbadun awọn eeyan ilẹ Naijiria lawọn orileede marun-un ti wọn wa lagbegbe Scandinavian Nordic, iyẹn awọn orileede bii Sweden, Denmark, Iceland, Finland ati Norway, amọ ilu Stockholm, ni Sweden ni ọfiisi aṣoju ijọba Naijiria ti wọn n pe ni Embassy wa.
Lasiko abẹwo rẹ lọjọ Satide, Ọgbẹni Fatile ba aṣoju ẹgbẹ awọn ọmọ Naijiria ti wọn n gbe lorileede Denmark, Nigerian Union in Denmark, sọrọ.
Ninu ifikunlukun wọn, awọn ọmọ Naijiria yii sọrọ nipa awọn aini wọn, ireti wọn, ati awọn afojusun ti wọn foju sọna fun latọdọ ijọba Naijiria, ti wọn si fẹ ki Fadile ba wọn ṣiṣẹ le lori.
Lẹyin to ti tẹti silẹ bẹ̀lẹ̀jẹ́ gbọ wọn lágbọ̀ọ́yé, Ambasadọ Fadile gboṣuba fun wọn gidigidi, o si fi da wọn loju pe lasiko toun yii, gbogbo aniyan ati erongba wọn loun yoo fi to Aarẹ Bọla Tinubu leti.
Asia orileede Denmark
Ambasadọ Tiwalade Elias-Fadile ati ẹgbẹ NID
Copenhagen, ni Denmark
Ẹmbasi Naijiria to wa ni Stockhom, Sweden
Ọkunrin naa waa fi asiko ọhun rọ awọn ọmọ Naijiria ti wọn ti ri jajẹ loke-okun lati gbe okoowo wọn wa si Naijiria, ki wọn si kopa lati mu ki ọrọ-aje orileede wa lagbara, ko si rugọgọ si i.
O ni ọrọ eto aabo ati ayipada oju-ọjọ wa lara nnkan ti ijọba to wa lode yii n ṣiṣẹ taakun-taakun le lori, ti ọsan si ti bẹrẹ sii so didun bayii.
O rọ awọn ọmọ ẹgbẹ Nigeria Union in Denmark lati maṣe kaarẹ ọkan, o ni ki wọn ma gbagbe ile, kaka bẹẹ ki wọn tubọ jẹ ki okùn ijumọsọrọpọ ati ajọṣe wọn pẹlu orileede abinibi wọn tubọ lagbara si i, tori ile labọ sinmi oko.
O fi da wọn loju pe ibaṣepọ to lárinrin, ti yoo si ṣanfaani daadaa lo maa bẹrẹ si i ṣẹlẹ laaarin Naijiria ati orileede Denmark ni sáà toun yii.