Lalude binu tan: Aa! Ti mo ba fi la’nu ṣẹ́ èpè fun Tinubu ati Sanwo-Olu…  

Niṣe ni ẹnu ya ọpọ awọn ololufẹ ilumọ-ọn-ka oṣere tiata to saaba maa n kopa oloogun ninu sinima nni, Fatai Adekunle Adetayọ, ti ọpọ eeyan mọ si Lalude, nigba ti wọn gbọ ọrọ to sọ nipa Aarẹ orileede wa, Aṣiwaju Bọla Ahmed Tinubu ati gomina ipinlẹ Eko, Babajide Oluṣọla Sanwo-Olu, ati awọn abẹṣinkawọ wọn, latari bi wọn ṣe ja ọgọọrọ awọn oṣere tiata ti wọn kampeeni fun wọn lati wọle ibo kulẹ, bi ọpọ eeyan ṣe n ṣe kayeefi pe ibo la tun ja si yii, bẹẹ lọrọ naa n bi awọn kan ninu gidigidi.

Eyi ko ṣẹyin bi ọkunrin onitiata ti wọn tun maa n pe ni Oodua yii ṣe tu pẹrẹpẹrẹ ọrọ lasiko ifọrọwanilẹnuwo kan to ṣe laipẹ eyi, eyi gba oju opo ayelujara kan lọjọ Abamẹta, Satide, ọjọ kejidinlọgbọn, oṣu Kẹfa yii, nibẹ ni Lalude ti fi aidunnu ati ẹdun-ọkan rẹ han si ijakulẹ ti Aarẹ Tinubu ati Gomina Sanwo-Olu mu ba oun ati awọn onitiata ẹlẹgbẹ rẹ, bẹẹ lo tun darukọ MC Oluọmọ, atawọn mi-in ti wọn ṣeleri asan fun wọn.

Ṣe ọrọ nii ba ‘mo ko mo ro’ wa, Lalude ṣalaye pe gbogbo ileri ti wọn ṣe fawọn oṣere lati ri ojuure ati atilẹyin wọn ni ko wa si imuṣẹ, ati pe awọn oloṣelu naa ti gbagbe wọn.

Bayii lo ṣe sọrọ naa, o ni: “Lẹyin ta a ṣe ipolongo ibo fun Tinubu ati Sanwo-Olu ti wọn fi wọle tan, wọn ko fun wa ni eepinni. Oṣu kan ati ọsẹ mẹta la fi ṣe kampeeni yẹn. Ta a ba fi le lanu ṣẹ epe fun wọn, wọn o nii bọ ninu ẹ ti wọn maa fi ku, titi aye ni epe naa yoo maa ja wọn. MC Oluọmọ (Musiliu Ayinde Akinsanya) lo ko awa oṣere jọ pe ka bẹrẹ si i ṣe ipolongo. Ni tododo, oun gan-gan alara lo diidi sọ fun Alapinni Ooṣa ati emi pe ka beere ohunkohun ta a ba fẹẹ gba. A si sọ ohun taa fẹ fun un, amọ ko mu ileri rẹ ṣẹ. Odidi oṣu meji la fi ṣe kampeeni tọsan-an toru pẹlu oogun oju wa. Gbogbo awọn ti ko jẹ ka ri owo gba titi doni, epe maa maa ja wọn titi aye ni o. Ofofo nii pa ẹru, epe nii pa ole, ilẹ dida nii pa ọrẹ, alajọbi ni pa iyekan ẹni to ba ṣe ibi. Gbogbo awọn ti wọn ba wa nidi ẹ ta a fi rowo gba, ta a dẹ ṣiṣẹ oṣu kan ati ọsẹ mẹta yẹn, taa fi kampeeni fun fun Tinubu ati Sanwo-Olu, wọn nii jeeyan titi wọn maa fi ku” Ati bẹẹ bẹẹ lọ.

Ọrọ ti Lalude sọ yii ti mu kawọn eeyan bẹrẹ si i sọko ọrọ kobakungbe gidigidi si oun atawọn onitiata ẹlẹgbẹ rẹ lori ẹrọ ayelujara. Oluwarotimi Olumide ni: “Ẹyin alatẹnujẹ lasan lasan yii, o da yin lara, oju yii aa fẹẹ bo”.

Mylone_fragraces ni: “Gbogbo yin ko nii bọ nbẹ, ẹyin onijẹkuujẹ wọnyi.”

Awosunle ni: “Aa, wọn tun gbe babalawo ni handicap niyẹn o.

Ọmọọla ni: “Ki lo de too fẹẹ gba owo latari pe o ṣe kampeeni fun ẹni to wu ọ. Ole ni yin. Ki lo ṣẹlẹ tẹẹ fi fẹẹ gba owo nitori eto idibo. Ole ni yin, ẹ ko ni ojuti rara o”.

Tẹẹ o ba gbagbe, ọsẹ to lọ lọhun-un ni agba-ọjẹ onitiata ti wọn n pe ni Alapini Ooṣa, iyẹn Alagba Ganiu Nofiu, naa sọ ohun to jọra pẹlu aroye ti Lalude ṣe yii, ọkunrin naa sọ ọ pe niṣe ni Tinubu ati ọmọ rẹ, Ṣeyi Tinubu tan awọn onitiata lati ṣe kampeeni ibo fun wọn, pẹlu ileri ofo, latari bawọn mejeeji ko ṣe mu adehun ti wọn ṣe ṣẹ nigba ti Aarẹ wọle ti ọwọ rẹ si ba eeku ida tan.

Ohun to ṣe kedere ninu ọrọ yii ni pe inu ọpọlọpọ awọn to ṣatilẹyin ibo fun Tinubu lati de ipo aarẹ ko dun rara lasiko yii, ọpọ lo si ti n leri leka pe ibo gbogbogboo ti ọdun 2027 ko nii ri bii eyi to kọja, pẹlu ijakulẹ tawọn n koju rẹ lọwọlọwọ. 

Leave a Comment

Your email address will not be published.

Start typing and press Enter to search