DON JAZZY: EMI KII S’ỌMỌ O, KODA “AGEGE” L’AWỌN KAN N PE MI

Gbajugbaja olokoowo orin (Music Executive) to tun jẹ apo-orin-pọ (Music Producer) ati olorin (Music Artiste) Michael Collins Ajerah ti ọpọ mọ si Don Jazzy lo n da apara pẹlu ẹnikan l’ori ayelujara l’oju opo ikanni Instagram rẹ.

Don Jazzy ẹni to lọ si ibi ode ere Johnny Drille to jẹ ọkan ninu awọn olorin to wa labẹ ile-iṣẹ Mavin Records iyẹn ile-iṣẹ agborinjade (Record Label) ti Don Jazzy. Orin ifẹ ni aye mọ Johnny Drille mọ, ti awọn ololufẹ si kun ibi ode ere to ṣe laipẹ yii.

Eyi lo fa ọrọ ti Don Jazzy kọ s’ori ikanni Instagram rẹ pe “Ni aṣalẹ anaa ta wa ni’bi ipatẹ orin Johnny Drille, oju mi kan n wo kiri ni pẹlu bi awọn olulufẹ to pọ ni’bẹ ṣe n di mọ ara wọn, fi ẹnu ko ara wọn, ba ara wọn jo pọ.”

Ẹ ranti pe l’ara oun ti Don Jazzy gbajumọ fun yatọ si orin ni pe ko si ninu igbeyawo kankan lat’ari pe igbeyawo rẹ akọkọ to ṣe ni ijinji aye rẹ ti f’ori san’pọn. Eyi lo mu ki ọkunrin kan l’ori Instagram @Jerry22 o da Don Jazzy l’ohun pe “Gbogbo wa la mọ pe oun (Don Jazzy) n s’ọmọ l’abẹlẹ”

Ni Don Jazzy gẹgẹ bi iṣẹ rẹ lati kan ma ba eniyan taku’rọ sọ l’ori ayelujara ṣe f’esi pada fun ọkunrin naa niyẹn pe “Irọ ni o? Emi kii ṣe iru rẹ, abi o ko gbọ pe wọn ni mo n ṣe “agege” (Ibalopọ akọ-s’akọ). Don Jazzy sọ eyi bi apara ṣugbọn ko tan si’bẹ.

Ẹlomiran to’n jẹ @sirSeun l’ori Instagram ba pe “Nibo??? Iwọ to kundun awọn “nnkan nlanla” Ni Don Jazzy ba tun ni l’atijọ lo n nifẹ si awọn obinrin nlanla ṣugbọn l’ọwọ yi lẹpa ati awọn to rọra l’omi l’ara fẹrẹfẹ l’aye tun ta si.

Leave a Comment

Your email address will not be published.

Start typing and press Enter to search