MI O FẸ L’OKIKI MỌ TI N BA TUN AYE WA – NASBOI PARIWO

Gbajugbaja onifọnran alawada l’ori ayelujara (comedy skit maker) ati olorin takasufe, Nasboi lo ti fi ero rẹ han laipẹ yii l’ori ikanni X rẹ nipa jijẹ olokiki. Ọkunrin naa lo kan n fi ero rẹ han l’ori ayelujara pe bi oun ba tun aye wa, oun ko fẹ yan ori okiki. Oun ti olorin yii ri gan-an ni pato ati okunfa ọrọ naa ni ko ye ẹnikan.

“N o mu owo nini dipo okiki… N ko le dan iru eyi wo mọ bi mo ba tun aye. Ki n kan l’owo ki ẹnikẹni ma mọ mi”

Oriṣiriṣi ni awọn eniyan n sọ nipa iwoye Nasboi, awọn kan ti ẹ n ṣe kayefi pe o n fẹ lati tun aye wa, bẹ ni awọn kan n pe ko pa oun to sọ di olokiki ti, bẹẹ ni awọn miran n beere pe ṣe ọkunrin naa gba pe olokiki ni oun lootọ.

Gbogbo komi, Nasboi pe owo nini san, o pe ju okiki lọ.

Leave a Comment

Your email address will not be published.

Start typing and press Enter to search