Yatọ fun jijẹ olokiki nidi iṣẹ orin ati amuludun, David Adeleke ti ọpọ tun mọ si Davido lo tun gbajumọ fun jijẹ baba ọlọmọ yọyọ fun iya ọtọtọ. Yatọ fun awọn ọmọ ti aya ile rẹ iyẹn Chioma Adeleke bi fun, ọpọ awọn obinrin miran lo jẹ iya-ọmọ iyẹn (Baby Mama) fun Davido. Ọkan pataki l’ara wọn ni Imade Adeleke, ti iya rẹ n jẹ Sophia Momodu, ẹni ti nnkan ko rọgbọ l’aarin rẹ ati Davido ṣugbọn to gba Imade gẹgẹ bii ọmọ.
Imade yii ni ọpọ gba pe o jẹ igi-akọ-ṣẹ (akọbi) Davido ṣugbọn ti oun jọ pe ọrọ ko ri bẹẹ mọ. Majesin ọmọ ọdun mẹẹdogun kan ti orukọ rẹ n jẹ Aanu Adeleke lo ti kọ iwe j’iṣẹ fun baba rẹ l’ori ayelujara. Ọmọ naa ni ki Davido o wa ṣe ayẹwo boya oun jẹ ọmọ rẹ nitootọ nitori ọpọ ẹgbin ati idunkoko ni oun ti koju l’ọwọ awọn eniyan nigbakugba ti oun ba ti pe Davido ni baba oun.
Diẹ ninu orọ Aanu lọ bayii pe: “O ti pẹ ti iya mi ati iya-iya mi ti gba mi l’amọran l’ati ma k’ẹgbẹ-k’ẹgbẹ abi hu iwa buburu bii lilo oogun oloro abi mu imukumu. L’oni mo wa kọ iwe yii lati inu ọkan mi wa lai ni idasi mọlẹbi kankan. O wumi lati mọ bi mo ṣe jẹ. Oniruuru oun ni mo ti la kọja, wọn ti n ko mi l’aya jẹ nigba lati nnkan ọmọ ọdun mẹfa ti n o si sunkun wa’le. Mo nilo lati maa ri oludamọran ọpọlọ t’ori ilera ọpọlọ mi ṣugbọn ti eyi ko di mi l’ọwọ lati t’ayọ l’ẹnu ẹkọ mi, ti mo fi gba ọga. Emi kii s’ọrọ ni’pa ẹbi mi mọ ṣugbọn mo ti n to’ju bọ gẹgẹ bi ọmọbinrin, to si wu mi l’ati mọ bi ọrọ mi ṣe jẹ ni pato. Mo fi t’ọwọ-t’ọwọ kesi Arakunrin David Adeleke lati wa ṣe ayẹwo DNA 🧬 lati fi idi ọrọ mu’lẹ pe ọmọ wọn ni mo jẹ. Mo wa dupẹ l’ọwọ awọn ọmọ Naija fun aduroti wọn lati bi ọdun meje sẹyin. Ayẹwo DNA naa ṣe pataki, oun ti mo l’ero pe o tọ ni. Ki Oluwa bukun fun yin Arakunrin Adeleke.”
Bi lẹta naa ti ja’de l’ori ikanni Instagram @aanuadeleke001 ti wọn Dr Kẹmi Olunlọyọ ṣi l’orukọ ọmọ naa ni nnkan ọdun diẹ s’ẹyin ni ariwo ta gee l’ori ayelujara, bi awọn ti n gba Davido niyanju lati ṣe ẹtọ l’ori ọmọ naa ni awọn kan tun ṣe eemọ pe Imade gan-an kọ ni akọbi ọmọ Davido, bẹẹ l’awọn miran n kaanu Aanu pe igbadun awọn obi rẹ nigba aimọ lo wa di iyọnu fun ọmọde ara rẹ.