Ẹ kú u déédéé àkókò yí o gbogbo ẹ̀yin olólùfẹ́ wa káàkiri àgbáyé. Ṣé àlàáfíà léni kọ̀ọ̀kan wà? Àjíǹde ara ẹnìkọ̀ọkan wa á máa jẹ́ o. Abala òòye ayé yi máa jẹ́ abala kan tí a ó ti máa f’òòyé ayé yéraawa. Onírúurú àwọn ǹkan tí a lè maa fi ṣòdiwọ̀n ìgbésí ayé wa la ó maa múwa sójú ìríkà yín lóòrèkóòrè. Ẹ jẹ́ ká bẹ̀rẹ̀ báyìí. Kí Olódùmarè ọba àdáni wáyé ó ṣe e nírọ̀rùn f’ẹ́nì kọ̀ọ̀kan wa. Àṣẹ.
Àkòrí òòye ayé toni la ó pè ní " Kíyẹ̀ síi"
Lẹ́yìn ọ̀pọ̀lọpọ̀ àròyé tá a bá ṣe, wọ́n lè fúnwa lọ́ṣẹ ká fi wẹ̀ láti lè mú ọwọ́ kọ́wọ́ kúrò lára wa. Púpọ̀ nínú wa la ma n padà fẹnu yẹ̀gẹ̀rẹ̀ àwọn ǹkan tí wọn ní ká fi wẹ̀ yí, ìyẹn ọṣẹ. Nítorí a máa ń padà rí i bí i ohun tí kò ṣiṣẹ́, bẹ́ẹ̀ kẹ̀dẹ̀rèé ọṣẹ náà ṣiṣẹ́ àmọ́ àwa fúnrawa là ń bàájẹ́ lákòókò tí à ń wẹ̀ ẹ́. Ẹ jẹ́ kí n ṣàlàyé. Àwọn nkànkan wà tí a ò gbọdọ̀ maa ṣe tí a bá ń wẹ irú àwọn ọṣẹ yí. Lákọ̀ọ́kọ́, kò dáa rárá láti máa tutọ́ lákòókò tí a bá ń wẹ àwọn ọṣẹ tó nííṣe pẹ̀lú ìtúsílẹ̀. Tàbí ká ní wípé ọṣẹ aájò lápapọ̀. Ká máa tutọ́ lákòókò táabá wẹ ọṣẹ aájò máa ń ba ọṣẹ náà jẹ́ ni.
Ìkejì, ní gbogbo ìgbà tí a bá ń wẹ ọṣẹ aájò, kò dáa rárá láti tọ̀ sí ibi tí a ti wẹ ọṣẹ náà. Nítorí irú nkan bẹ́ẹ̀ máa ń ba ọṣẹ náà jẹ́ ni. Tí a bá sì wò ó dáada, à á rí i pé irú àkókò yí ni ìtọ̀ máa ń fẹ́ẹ́ gbọ̀n wá. Tí ó bá rí bẹ́ẹ̀, ẹ rí í dájú pé ibòmín ìn lẹ tọ̀ sí kí ó má jẹ ibi tí ẹ ti wẹ̀ yẹn gan-an gan.
Ẹ̀ẹ̀kẹta, kì í ṣohun tó dáa rárá láti máa fi kàìn-kàìn tí a fi ń fọ ẹlẹda wa fọ àtẹ́lẹ́ẹsẹ̀ wa. Irú ǹkan báyìí náà máa ń ba ọṣẹ aájò jẹ́. Ó sàn kí á fi ọwọ́ wa gbo àtẹ́lẹ́ẹsẹ̀ wa ju kàìn-kàìn tí a fi ń wẹ orí wa lọ. Ẹlẹ́ẹ̀kẹrin, má ṣe máa yán kàìn-kàìn tí o bá fi wẹ ọṣẹ aájò. Ó sunwọ̀n kí omi gbẹ mọ́ ara kàìn-kàìn náà ju kí á yán án lọ. Nítorí èyí náà wà lára ǹkan tí ó máa ń ba ọṣẹ aájò jẹ́.
Nítorí náà, kí o tó ó bú àwọn tí wọn ń ṣaájò fún ẹ wípé ǹkan tí wọ́n ń ṣe fún ẹ ò ṣiṣẹ́, ṣe ìwọ náà ò kí ń ṣe ọ̀kan tàbí méjì nínú àwọn ǹkan wọ̀nyí?
Èdùmàrè kó gbàdúrà kálukú wa o. Títí dìgbà mín ìn tí a ó tún pàdé, Fàtáì Bántálẹ́ loókọ mi o.