Maami ni nko Le gbe bukata si’le gẹgẹ bii Iyawo – Chike

Irawọ olorin takasufe olohun arinkinkin nni, Chike-Ezekpeazu Osebuka ti ọpọ mọ si Chike lo ti ni, laye, oun ko le fẹ obinrin ti ko ba mọ arobọ – iyẹn ni pe obinrin ti ko le ṣ’owo jere.

Chike sọ eyi mọ ọrọ l’asiko ifọrọwọrọ kan to ṣe laipẹ yii l’ori eto kan ti akọle rẹ n jẹ “Ada’s Room’ ni ile-iṣẹ redio Flow 98.7 fm ni’lu Toronto ni orilẹ-ede Canada.

Ni’bẹ lo ti jẹ ko di mimọ pe oun ko le fẹ obinrin ti ko ba le sọ ogun dogoji nidi owo ṣiṣe. Alaye Chike ni pe, oni la ri, ko s’ẹda to mọ’la, bi nnkan ba safẹrẹ lọjọ iwaju abi bi ọlọjọ ba de, obinrin to mọ arobọ, to mọ bi eniyan ti n ko ọrọ jọ nipasẹ okoowo ṣiṣe ni yoo le ṣe aduroti to yẹ.

Olorin ẹni ọdun mẹtalelọgbọn (33) naa tẹsiwaju lati sọ asọye pe, iya oun ti da oun lamọran lati ma fẹ akuṣẹ abi ni ana to ma da bukuta pa. Bẹẹ lo tun ni oun gan-an na ti kuro ni ipo wiwa obinrin ṣa lasan to jẹ pe afẹ aye lai ro ti ọla ni wọn kundun, ṣugbọn to jẹ pe obinrin to le sọ ohun kekere di pupọ ni oun l’ero lati ni l’ẹgbẹ.

Leave a Comment

Your email address will not be published.

Start typing and press Enter to search