Gbajugbaja alufaa to gbajumọ fun sisọ asọtẹlẹ nipa oṣelu orilẹ-ede Naijiria, Primate Elijah Ayọdele ti sọ bi nnkan yo ṣe ri fun Aarẹ orilẹ-ede Naijiria, Bọla Ahmed Tinubu ati Adebayọ Adelabu to jẹ alakoso tẹlẹ ri fun ọrọ ohun amuṣagbara ninu eto idibo ọdun 2027.
Ninu ọrọ rẹ, Primate Ayọdele ni Adelabu ko ni wọle ibo ayafi to ba ṣe awọn ipese ti oun ka si’lẹ fun-un.
Ẹ ranti pe ni ọdun 2025 to kọja ni awuyewuye kan ku igboro pa pe Alufa Ayọdele n wa oju Adelabu pe oun fẹẹ ṣe aajo fun-un minisita tẹlẹ naa pẹlu awọn eroja bi fere (trumpet) lati le de ipo gomina ipinlẹ Ọyọ ṣugbọn ti Adelabu taku to si fi ẹjọ alufa naa sun awọn agbofinro ki ọrọ naa to di iṣu-ata-yan-an-yan-an ti gbogbo aye gbọ.
L’ọwọ yii, Primate Ayọdele ti pada sori asọtẹlẹ rẹ atijọ pe bi Adelabu ba kọ, ti ko jẹ oun ni ho lati wa ṣe aajo to sọ, ko ni ri ọna lọ lati di gomina ipinlẹ Ọyọ.
Ni ti Tinubu, Primate Ayọdele ni a fi ti awọn ẹgbẹ oṣelu alatako ba pa’wọ pọ ki wọn to le fẹyin Tinubu bẹ’lẹ bibẹẹkọ Tinubu yoo wọ’le ẹlẹẹkeji gẹgẹ bii aarẹ orilẹ-ede Naijiria.
Ẹwẹ, Adelabu ati Tinubu ni ko ti fọ esi kankan si asọtẹlẹ yii ṣugbọn ti iwoye wa pe o ṣeeṣe ki idahun o jade si asọtẹlẹ naa.