Mi O Lero Pe Mo Le Ye, Eemi Mi Lo Ti Lọ Yẹn’ – Niniola Sọrọ Lẹyin Iku Ọkọ Rẹ

Gbajugbaja olorin Niniola Apata ti fi oriyin bantabanta lede lẹyin ipapoda ọkọ rẹ, Michael Ndika to si n sọ pe ibanujẹ ọkan ni iku rẹ jẹ f’oun.

Lori ikanni ibanidọrẹ Instagram rẹ lo ti sọrọ nipa bi nkan ṣe ti ri ni kikẹdun ọkọ oun lẹyin t’oun fi iroyin iku rẹ lede.

O ṣapejuwe ọkọ rẹ naa gẹgẹ bii opo t’oun fẹyinti, ọrẹ korikosun, alaṣiri, ẹgbọn, apanilẹrin,veemi t’oun n mi ati bẹẹ bẹẹ lọ.

O tẹsiwaju pe niṣe l’oun ṣi n reti pe yoo pada wọle wa. O ni o sọrọ f’oun lati gba pe ọkọ oun o si mọ.

O tẹsiwaju pe n ṣe l’oun ṣi n reti pe yoo pada wọle wa. O ni o ṣoro f’oun lati gba pe ọkọ oun o si mọ.

Niniola ni oun o lero pe oun le ye adojukọ yii nitori gbogbo igba l’awọn jọ maa n wa koda ninu ile gan nitori kii fẹ k’oun jina rara.

O ṣapejuwe ara rẹ gẹgẹ bii ẹni to maa n da wa ni gbogbo igba ti Michael si n ṣe aduroti to nilo ni ọna gbogbo. O fikun pe o ni ipa rere ni ile aye oun ṣugbọn Ọlọrun ti gba lọwọ oun bayi.

Ogunjọ oṣu ta wa yii ni Niniola fi lede pe oun padanu ọkọ oun lẹyin ọdun mẹtala ti wọn ti jọ wa papọ leyi to mu ki awọn ara, ọrẹ ati ojulumọ maa ba kẹdun ọkọ rẹ to lọ.

Leave a Comment

Your email address will not be published.

Start typing and press Enter to search