Lẹyin ọjọ kẹẹdogun ni akata awọn ajinigbe lati ọjọ kẹẹdogun oṣu karun-un ọdun 2026, Abilekọ Alamu to jẹ ọkan ninu awọn olukọ ti awọn ẹlẹkẹru agbesunmọmi jigbe pẹlu awọn akẹẹkọ ni ijọba ibilẹ Oriire ni agbegbe Ogbomoṣọ ni ipinlẹ Ọyọ lo n bẹbẹ fun idasi ẹmi wọn, pe kii ijọba o tete wa doola wọn lai ba awọn ẹlẹkẹru naa fa wahala rara nitori aabo ẹmi wọn.
Ninu fọnran kan to ti lu ori ayelujara pa ni obìnrin naa ti n bẹ ijọba pẹlu omije kikoro pe ki wọn tete wa gba awọn silẹ nipa ṣiṣe ohunkohun ti awọn ajinigbe-agbesunmọmi naa ba beere fun.
“At’agba at’ọmọde, oju kan la wa, at’ojo at’oorun lo n pa wa pọ.” O ṣ’aleye ipo ti wọn wa
Fọnran eyi ni yoo jẹ ẹẹkeji iru rẹ ti awọn agbesunmọmi naa yoo lo obinrin naa lati bẹbẹ pe ki ijọba o tete pẹtu si awọn agbesunmọmi naa l’ọkan.
Ninu fọnran naa o kesi Aarẹ Bọla Tinubu, Gomina Ṣeyi Makinde ati awọn ajọ eleto aabo gbogbo lati wa gba wọn silẹ ṣugbọn ni ilana pẹlẹ kutu ti ko ni bi awọn ajinigbe naa ninu, ki wọn o ma ba da ẹmi wọn legbodo.
“Ẹ ma jẹ ki wọn o pa wa. Wọn ti n binu pe oun pẹ. Ẹ ran wa lọwọ. Ẹ ma gbagbe wa si inu igbo.” O ṣo eyi pẹlu omije loju.