Agbefọnranjade l’ori ayelujara, Habeeb Hamzat ti gbogbo eeyan mọ si Peller lo ti sọrọ nipa erongba rẹ lati pada si’le-iwe ati idi to ṣe fẹ pada.
Ninu fọnran kan to n tan ka lori itakun ibanidọrẹ Instagram, Peller ṣalaye pe kii ṣe nitori paali nikan l’oun ṣe fẹ lo si’le-iwe.
O ni oun fẹ fi ara oun s’awọn ibi to ṣe pataki k’oun le r’aye ri ati joko pẹlu awọn eekan ti wọn l’owo julọ l’orilẹ-ede Naijiria bii Femi Otedola ati Aliko Dangote.
Agbefọnranjade naa ni owo awọn olowo ti wọn kawe bii Dangote ati Otedola l’oun fẹ maa na bayi, ki wọn le fi ifẹ han s’oun.
O ni awọn olowo ti wọn ba kawe maa n fẹ ṣiṣẹ pẹlu awọn ti wọn kawe nitori naa oun fẹ pada si’le-iwe k’oun le maa wa pẹlu awọn olowo ilẹ yii.
Peller fi akoko ti Dangote ṣe ifilọlẹ tita awọn ipin owo ile-iṣẹ rẹ, awọn ti wọn kawe bii Enioluwa ati Tobe lo pe fun ipolowo.
O wa ke si Dangote, Otedola ati Tony Elumelu lati da oun naa mọ ọmọ tọ nitori oun naa kawe.
Ọpọ awọn eeyan ni wọn ti bu ẹnu atẹ lu Peller latẹyin wa nitori ile-iwe ti ko lọ ati bi o ṣe ti ṣe yẹyẹ awọn ti wọn kawe tẹlẹ.
Ti ẹ o ba gbagbe ọjọ kẹrinlelogun oṣu kini ọdun yii ni Peller kede pe oun ti wọ ile-iwe giga fasiti kan nipinlẹ Eko, ko to di pe o fi ile-iwe silẹ p’oun o ṣe mọ ni ọjọ kẹtadinlọgbọn oṣu kan-naa.