Itafaaji

Eguavoen di akọni-mọ-ọn-gba tuntun fun Super Eagles

Ni bayii, ẹni moju ogun ni yoo bẹrẹ si i pabi n’Ire fun ikọ agbabọọlu agba ilẹ wa, Super Eagles, pẹlu bi ajọ to n ri si ọrọ bọọlu alafẹsẹgba, Nigeria Football Federation, NFF, ṣe yan akọni-mọ-ọn-gba Augustine Eguavoen sipo adari ti yoo lewaju awọn agbabọọlu naa lọ si idije ati ifẹsẹwọnsẹ fun ife-ẹyẹ ilẹ adulawọ, Africa Cup of Nations, eyi ti yoo waye lorileede Morocco, lọdun 2025. 

Ajọ NFF ṣe ikede yii ninu atẹjade kan ti wọn fi lede laṣalẹ ọjọ Ẹti, Furaidee, ọgbọjọ, oṣu Kẹjọ, ọdun 2024 yii niluu Abuja, olu-ilu ilẹ wa. 
Atẹjade ọhun, eyi ti adari ẹka ibanisọrọ fun NFF, Ọgbẹni Ibrahim Musa Gusau buwọ lu, ṣalaye pe fun odidi ọjọ mẹta ni ajọ NFF ti n fori-kori pẹlu akọni-mọ-ọn-gba tuntun, Ọgbẹni Bruno Lambaddia, ti wọn fẹẹ yan sipo adari Super Eagles amọ awọn ko ri ọrọ naa sọ, niṣe ni gbogbo ẹ ta koko, latari eto sisan owo-ori akọni-mọ-ọn-gba ọmọ bibi orileede Germany ọhun.

Gusau ni awọn tiẹ ti kọkọ n ba ọrọ naa bọ wẹrẹwẹrẹ, ti gbogbo eto si ti n to bọ, afi bi ọrọ sisan owo-ori ṣe wọ ọ, ibẹ si ni ijiroro wọn ti dẹnu kọlẹ bii igba ti agbẹ f’ọkọ kọ ebe.
Gusau tun sọ pe: “Ọjọ kẹta ree ta a ti wa lẹnu ijiroro lori ọrọ sisan owo-ori, a si ti jẹ ki alejo wa mọ pe ko si ba a ṣe fẹẹ ṣe e, ajọ NFF ko le tọwọ bọwe adehun lati maa san owo rọgun-rọgun ti ofin orileede Germany n beere fun gẹgẹ bii owo-ori, agbara wa ko gbe e, a ko si lẹmi rẹ. 

Ko ṣee ṣe fun wa lati tun maa yọ nnkan bii ida mejilelọgbọn ninu ọgọrun-un (32%) si ida ogoji ninu ọgọrun-un (40%) owo-oṣu kooṣi naa, lati san an gẹgẹ owo-ori ilẹ Germany, lẹyin ta a ti gba lati san owo-oṣu rẹ pe perepere. 

Ajọ NFF ti pari gbogbo adehun pẹlu Ọgbẹni Labbadia, eyi lo si jẹ ka kede rẹ pe oun ni yoo bẹrẹ iṣẹ akọni-mọ-ọn-gba fun Super Eagles, ko si ọrọ owo-ori yii ninu ajọsọ wa lati ibẹrẹ, nigba ti ọrọ naa si jẹ jade, a gbiyanju lati fori ikooko ṣọọdun nipa ẹ, amọ ko ṣee ṣe, nitori ọkunrin naa taku jalẹ ni, o ni dandan ni ka san owo-ori toun n beere fun, agbara wa ko si gbe iru ẹ, ko sohun to jọ ọ.”
Pọrọ ọhun ṣe ri, ajọ NFF ti kede pe adele akọni-mọ-ọn-gba fun Super Eagles tẹlẹ, Augustine Eguavoen ni yoo bọ sipo adele taara bayii, ti yoo si maa dari ikọ agbabọọlu naa. 

Bi ọrọ ko ba yi pada, Eguavoen ni yoo ko awọn agbabọọlu naa lọọ koju ẹlẹgbẹ wọn lati orileede olominira Bẹnẹ (Benin Republic) ninu ifẹsẹwọnsẹ to maa waye ni papa iṣere Akwa-Ibom, niluu Uyo, lọjọ keje, oṣu Kẹsan-an ọdun yii. Ọjọ mẹta lẹyin ẹ, gbogbo wọn yoo ko digba-dagbọn wọn, ilu Kigali, lorileede Rwanda ni wọn yoo kọri si, lọjọ kẹwaa, oṣu Kẹsan-an yii kan naa, ti wọn yoo lọọ gba igbesẹ keji ifẹsẹwọnsẹ ọhun, Eguavoen ni yoo si tukọ wọn lọ, lẹyin naa ni wọn yoo kọri sorileede Morocco, lọdun 2025 fun idije ife-ẹyẹ to laami-laaka ju lọ nilẹ Africa ọhun.
Ọmọ bibi ilu Sapẹlẹ, nipinlẹ Delta ni Augustine Eguavoen, ẹni ọdun mọkandinlọgọta si ni lọdun yii. Lati ọdun 1999 lo ti n ṣiṣẹ akọni-mọ-ọn-gba fun awọn ẹgbẹ agbabọọlu bii, Sliema Wanderers ati Bendel Insurance, ko too di kooṣi ikọ ti Naijiria, iyẹn awọn ọjẹwẹwẹ agbabọọlu tọjọ ori wọn ko ju ogun ọdun lọ (Under 20) lọdun 2020, o tun ṣe tawọn tọjọ ori wọn ko ti i pe ọdun mẹtalelogun (Under 23), ati bẹẹ bẹẹ lọ.
Eguavoen wa lara ikọ agbabọọlu to ṣoju Naijiria lasiko idije fun ife ẹyẹ agbaye (FIFA World Cup) to waye lọdun 1994, iyẹn si ni igba akọkọ ti Naijiria maa kopa ninu aṣekagba idije to larinrin ọhun. 

Leave a Comment

Your email address will not be published.

Start typing and press Enter to search