Bukunmi ya ọrọ nla lulẹ fawọn oṣere-binrin ẹlẹgbẹ ẹ!

Ọrọ ṣunnukun, oju ṣunnukun laa fi i wo o, gẹgẹ bi Yoruba ṣe maa n sọ. Iru ọrọ kabiti bẹẹ ni eyi ti gbajumọ oṣere-binrin onitiata nni, Bukunmi Oluwaṣina sọ lati tan imọlẹ si ohun to n fa ifasẹyin ati aiṣedeede laaarin awọn obinrin ẹlẹgbẹ rẹ ti wọn jọ n ṣiṣẹ ere ori itage, o ni ko si nnkan mi-in to n da iṣoro silẹ fawọn obinrin ju owu jijẹ, ilara ati aisi ifẹ tootọ laaarin awọn, bẹẹ ọrọ ko ri bẹẹ laaarin awọn ọkunrin onitiata, idi eyi si ni ina itẹsiwaju ati ajọṣepọ wọn ṣe dan mọran ju tawọn obinrin lọ.

Arẹwa oṣere adumaadan yii tun fi bi ọrọ ọhun ṣe ka a lara to han pẹlu bo ṣe n beere awọn apola ibeere lọwọ awọn oṣere-binrin ẹlẹgbẹ rẹ, lati le mu ki wọn ronu jinlẹ lori ọrọ akiyesi ati amọran oun, ki nnkan le sunwọn si i lagbo ere sinima ti wọn yan laayo.

Ki i ṣe pe ẹnikan fọrọ wa Bukunmi lẹnu wo o, bẹẹ ni oṣere to tun fẹran lati maa kọ ori ololufẹ yii ko kopa lori eto tẹlifiṣan tabi redio to fi sọrọ naa, niṣe lobinrin to maa n rẹrin ẹyẹ yii kanlẹ ronu arojinlẹ, to si gba ori ikanni instagiraamu rẹ lọ lọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ọjọ kẹtadinlogun, oṣu Kejila, ọdun 2024 yii, lati fi ẹdun ọkan rẹ ati ọrọ amọran ọhun lede fawọn ẹlẹgbẹ rẹ.

Bayii ni Bukunmi ṣe kọ ọrọ rẹ, o ni:

“Mo jowu awọn ọkunrin o. Ẹyin ẹ tiẹ wo wọn na, bi wọn ṣe maa n faaye gba ara wọn, ti wọn n ti ara wọn lẹyin, ti wọn si n tẹsiwaju papọ…

“Itẹsiwaju wọn han ninu bi wọn ṣe maa n pọn ara wọn le, ti wọn si maa n fun ara wọn ni iṣiri, bẹẹ afojusun kan naa ni wọn ni o. Mi o le sọ bi inu mi ṣe dun to nigba ti mo ri ipolowo fiimu oṣerekunrin ti mo fẹran kan lori ikanni oludari ere mi-in ti mo fẹran, ti mo ri bi oṣere yii ṣe sọrọ apọnle nipa adari ere naa lẹyin rẹ, bẹẹ oun naa n ṣiṣẹ adari ere o.

Mo gbadura ki n ri iru nnkan bii eyi laaarin awọn oṣerebinrin ẹlẹgbẹ mi lọjọ kan ṣa. Niṣe lawa mu ile aye le koko, ti a le fẹran ara wa denu. Ki lo na wa?… Ki lo n ṣe wa? Bawo la ṣe ba ara wa nibi yii na?

Bẹẹ naa lawọn ololufẹ wa ti wọn lero to daa maa n fa iyapa, ti wọn aa bẹrẹ si i sọrọ mo gba ti ẹ, mi o gba tiẹ lẹnu. O daa o, mo beere ni o, ki la n ja fun gan-an? Ṣe ade ni, abi owo, abi ipo? Eyi o wu ko jẹ, ewo ninu iwọnyi la fẹẹ mu lọ ti iku ba de? Mi o tiẹ fi bẹẹ ni ọrọ lati sọ nipa awọn fansi wa wọnyẹn to jẹ pe ẹlomi-in ko mọ nipa ifẹ lati ile to ti wa. Bo ṣe ri lara wọn ni wọn fi n huwa ni tiwọn.

“Ni temi o, mi o ni olodi kankan, tori ifẹ lo kun inu ọkan temi bamu. Ko si ẹni ti mo n ba ja, ko si idi fun mi lati ṣe bẹẹ, afi ti idi naa ba waa wa lọla o.

Ni temi, mi o gba pe eeyan kan ni ayọ to ba jẹ niṣe lo n fi n ba ẹlomi-in ninu jẹ, mi o si gba pe ẹnikan ni ifẹ tootọ ti ko ba fi ifẹ ọhun han sawọn teeyan ko tiẹ lero pe o yẹ keeyan sun mọ.

“Fun ẹyin tẹẹ maa n sọ pe yẹn yẹn yẹn, pẹpẹsi, ifẹ ori ahọn lasan lawọn ọkunrin ni si ara wọn, emi mọ o, pe awọn temi ko nifẹẹ ẹtan si ara wọn.  Ẹyin gan-an lẹ n da wahala silẹ. Beeyan ba tiẹ ni ifẹ ṣakala si ẹnikan, ka dupẹ pe o ṣakala, ko ṣakala, o sa tiẹ ṣi fi ifẹ kan han. Ifẹ ki i ṣe nnkan teeyan n gbe pamọ fun ẹni to ba ni in. Ọkan awa eeyan tobi, o si gbooro to lati fẹran gbogbo aye. A kan le ma fi iru ifẹ kan naa si gbogbo eeyan lọgbọọgba ni. Amọ bo ba jẹ fọ mi loju kemi naa fọ tiẹ san la n ba kiri, ko nii pẹ ti gbogbo aye yoo fi di afọju o. Ẹ jẹ ka sinmi aidaa. Iwọ ni koo kọkọ pinnu lati fi ifẹ han. Ẹ fi ifẹ si atẹni to ti yin lẹyin atẹni ti ko ṣe bẹẹ. Eyi lo maa sọ ẹni to ba ṣe bẹẹ di eeyan pataki, ẹni nla gidi.”

Bayii ni Bukunmu Oluwaṣina kadii ọrọ rẹ. O ni kawọn oṣerebinrin fi tawọn ọkunrin ṣe arikọgbọn, ki wọn sinmi wiwa ile aye maya, ki wọn si fi ifẹ aiṣẹtan han si ara wọn yika.

Leave a Comment

Your email address will not be published.

Start typing and press Enter to search