Bi mama agbalagba naa ṣe n keboosi ‘ẹ ṣaaanu mi pẹlu omije loju, bẹẹ lo n ke tantan, to si ka boroboro pe ki i ṣe ohun tawọn reti pe ko ṣẹlẹ lo ṣẹlẹ yii, o lo ti le lọdun mẹwaa ti Olori Naomi ti n ṣe eto pinpin ẹbun ati iranwọ fawọn ọmọde, awọn opo, awọn alaini atawọn alaboyun bọ, ọpọ agbegbe lawọn si ti lọọ ṣeto ọhun kaakiri, afi bi ti Ibadan yii ṣe yiwọ, mama naa si kẹdun pẹlu awọn ti ọmọ wọn ku sinu iṣẹlẹ naa, amọ o rawọ ẹbẹ si gbogbo agbaye ati ijọba pe ki wọn gba oun, ki wọn ba oun tu Naomi silẹ ninu igbekun to ha si.
Ẹ o ranti pe Keresi ku ọla, iyẹn ọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ọjọ kẹrinlelogun, oṣu Kejila ọdun 2024 yii, ni ijọba foju Olori Wolii Naomi Ṣilẹkunọla, Ọgbẹni Oriyọmi Hamzat ti ileeṣẹ redio Agidigbo FM ati Ọgbẹni Fasasi Abdullahi Babatunde, to jọ Olukọ agba (Principal) ileewe Bashorun Islamic High School n’Ibadan ba ile-ẹjọ lori ẹsun oni-koko mẹrin ti wọn fi kan wọn.
Lara awọn ẹsun ọhun ni pe wọn gbimọ pọ lati huwa ibi, wọn huwa aibikita eyi to yọri si ipalara fun ọmọlakeji, wọn kuna lati ṣeto aabo to yẹ fun ẹmi ati dukia, ati pe wọn huwa to da ẹmi awọn ẹni ẹlẹni legbodo lọna aitọ.
Lẹyin tawọn olujẹjọ mẹtẹẹta ti sọ pe awọn ko jẹbi, Adajọ ileejọ majisireeti to fikalẹ si agbegbe Iyaganku, niluu Ibadan ọhun, Majisireeti Agba Ọlabisi Ogunkanmi paṣẹ pe ki wọn taari awọn olujẹjọ mẹtẹẹta si ọgba ẹwọn Agodi na, titi di ọjọ kẹtala, oṣu Kinni, ọdun 2025 ti igbẹjọ yoo maa tẹsiwaju.
Bakan naa lo paṣẹ fawọn ọlọpaa ki wọn tete fi iwe ẹsun wọn ṣọwọ si ẹka to n gba awọn adajọ lamọran, Directorate of Public Prosecution, fun amọran to yẹ.
Gbogbo eyi waye latari iṣẹlẹ ibanujẹ to ṣẹlẹ lọsẹ to ṣaaju, nibi ti awọn araalu ti wọn n haragaga lati gba ẹbun ounjẹ ati owo ti Olori Silẹkunọla fẹẹ ha gẹgẹ bii itọrẹ aanu to maa n ṣe lọdọọdun, ti tẹ awọn ọmọde bii marundinlogoji pa, ti ọpọ si tun farapa yanna-yanna, lasiko ti wọn n ti ara wọn. Eyi lo ṣokunfa bi awọn agbofinro ṣe lọọ fọwọ ṣinkun ofin mu awọn afurasi mẹjọ, titi kan Olori Ṣilẹkunọla ati Oriyọmi Hamzat, amọ wọn ti fi marun-un lara wọn silẹ, wọn ni wọn ko mọwọ mẹsẹ lori iṣẹlẹ naa.
Oriṣiiriṣii ọrọ ibanikẹdun ati aanu lawọn eeyan ti kọ sabẹ fidio gbajare ti Mama Olori ṣe yii, ọpọ lo si kaaanu mama naa ati ọmọ rẹ, ti wọn ṣadura pe Ọlọrun maa ko wọn yọ.
Hawanat Abiọla ni: “Oluwa dakun, ma jẹ ki ọmọ araye sọ oore di ibi mọ wa lọwọ o. Aa, ikunlẹ abiyamọ oo.”
Yetundetide ni: “Ki Ọlọrun jọwọ da si ọrọ yii ni o. Olori yii ko ni ero aidaa kankan lọkan, Ọlọrun aa si gbeja rẹ ja… Bi wọn ṣe sọ ọ sẹwọn ko tii pọ ju lasiko yii, ta a ba fi wera pẹlu awọn ọmọ ọlọmọ ti wọn o nii pada saye mọ… Wọn maa tu u silẹ laipẹ lagbara Ọlọrun.
Beautyradiance ni: “Ọlọrun maa duro ti ẹyin ati ọmọ yin Ma o.”
Oluchi Tianah ni: “Ki ni Ọba Ọọni n ṣe nipa ọrọ yii? Mo lero pe bi wọn ṣe gbajumọ tẹnu wọn ti tolẹ lawujọ, wọn gbọdọ ni iranwọ ti wọn maa ṣe. Ti Naomy ba ṣi wa nipo Olori laafin ni, ko sẹni to to bẹẹ lati fọlọpaa mu un. Ohun to ṣẹlẹ yii ko daa o, ka sododo ọrọ.”
Fash oluṣẹgun ni: “Wọn ṣi maa fi wọn silẹ, igbesẹ to yẹ lati gbe ni ijọba gbe yii.”
Mummygiohussein ni: “
Awọn alagbara lo wa lẹyin iṣẹlẹ aburu yii.”
Bosskid ni: “Ẹ gbọ na, ẹsun wo ni wọn fẹẹ ka sọrun awọn to ko ipọnju ati ebi yii ba araalu de ibi to de yii laarin ọdun meji?”
Abikẹ Oyinscoco ni: “Ẹkun abiyamọ ti ko lolugbeja leyi o.”
Xpensive: “Ẹyin tẹẹ n sọ pe o yẹ ki ọba ṣe tibi, o yẹ ko ṣe tọhun, ṣe ka tiẹ ni Ọọni n ṣe nnkan kan lori ọrọ naa, ẹ reti pe ko waa maa ṣalaye fun yin lori ẹrọ ayelujara ni, abi? O ga fẹyin ọmọ Naijiria o”
Ẹnikan tun sọ pe: “Aanu wọn ṣe mi o, mo ba wọn daro gidigidi” ati bẹẹ bẹẹ lọ.