Foju inu wo aye kan to jẹ pe beeyan ṣe n fi owo pamọ fun ọjọ-ọla rere, bẹẹ ni onitọhun tun n jẹ ẹbun owo tabua si i, ti owo si n wọle lọtun-un losi! Iru anfaani bẹẹ ni ileefowopamọ Stanbic IBTC mu wa bayii pẹlu ipolongo Reward4Saving to gbode. Eyi fakiki, o dara ju, o si kun fun ọpọ anfaani ti yoo jẹ kawọn to n fowo pamọ ri ere ati ẹbun to jojunigbese lori owo wọn.
Ka sọ ododo ọrọ, Reward4Saving 4.0 yii kii wulẹ ṣe ọrọ ipolowo ọja, eto pataki kan lati fi owo ro awọn ọmọ Naijiria lagbara, ko le maa wu wọn lati tun tu owo jọ fun ọjọ-ọla ni. Teeyan ba ti le fi, o kere tan, ẹgbẹrun mẹwaa naira (N10,000) pamọ sinu akaunti Savings tabi @ease Wallet rẹ ni banki Stanbic IBTC, ti ko si jẹ ki owo naa din kọja iye yii laaarin oṣu kan gbako, ẹni naa ti tootun lẹsẹkẹsẹ lati jẹ anfaani ẹbun owo tabua, loṣooṣu, loṣu mẹta-mẹta, ati lasiko aṣekagba eto yii.
Ki lanfaani ibẹ? Loṣooṣu, ọkọọkan awọn oloriire aadọrin (70) maa jẹ ẹbun ẹgbẹrun lọna ọgọrun-un (N100,000). To ba tun di oṣu mẹta, ọkọọkan onibaara Banki Stanbic IBTC kan lati ẹkun okoowo meje yoo fi ẹbun miliọnu kan ṣe’fa jẹ, ẹnikan yoo tun lọ sile pẹlu ẹbun miliọnu meji (N2m) loṣo mẹta-mẹta, ko too waa kan aṣekagba, nibi ti kọsitọma meji yoo ti fi owo tabua, ẹbun miliọnu marun-un marun-un naira ṣara rindin.
Lati bii ọdun mẹta sẹyin, o ti fẹrẹ to ẹgbẹrun meji (1,900) awọn oloriire, ti banki Stanbic IBTC ti fi ẹbun owo ti aropọ rẹ jẹ miliọnu lọna ọọdunrun naira, o le mejidinlogun (N318m) da lọla. Lọtẹ yii, ọpọn ti sun siwaju, pẹlu odidi miliọnu lọna aadoje naira (N130m) ta a ti ya sọtọ fawọn oloriire ọrinlelẹgbẹrin din mẹfa (874) ti yoo jẹ ẹbun. Lọpọ igba, ojuṣe pataki lo jẹ lati maa lọ fowo wa pamọ si banki. Njẹ ko waa nii larinrin bi fifowo pamọ ba di nnkan to n mu owo pọ si i, to si dabi igba teeyan n ṣere, to di nnkan faaji? Ohun ti ipolongo Reward4Saving Promo 4.0 yii wa fun gẹlẹ niyẹn. Banki Stanbic IBTC fẹẹ fi owo ro awọn eeyan lagbara, amọ ju bẹẹ lọ, a fẹ ki ri eto ifowopamọ bii nnkan faaji, ki inu wọn maa dun, ki ọkan wọn si balẹ lori owo wọn.
Bawo leeyan ṣe le kopa? Ko le rara. Bẹrẹ latori ṣiṣi akaunti Savings tabi @ease Wallets si banki Stanbic IBTC, fi ẹgbẹrun mẹwaa naira (N10,000) pamọ sinu rẹ fun ọgbọn ọjọ. O tan, o ti wa lara awọn ti yoo kopa ninu idije niyẹn. Awọn to ti ni akaunti pẹlu wa tẹlẹ naa ko gbẹyin, bi wọn ba ti fi ẹgbẹrun mẹwaa (N10,000) naira sibẹ lai yingin fun oṣu kan gbako. Beeyan ba ṣe n fowo pamọ si i to, bẹẹ lonitọhun yoo ṣe lanfaani lati jẹ ẹbun to, iba jẹ ti oloṣooṣu, oloṣu mẹta-mẹta tabi ti aṣekagba. Ki lo tun n duro wo? A ke si ọ lati tete gba anfaani yii mu ko o le ṣakoso eto inawo rẹ, ki ọjọ-ọla rẹ si daju. Ṣi akaunti kan loni-in, bẹrẹ si i fowo pamọ sibẹ, ko o si jẹ ẹbun kabiti laipẹ!
O tun le darapọ mọ Stanbic IBTC lori ikanni ayelujara wa gbogbo. Tele wa nibẹ, ko o le maa foju ara rẹ ri, waa si feti ara rẹ gbọ bawọn eeyan to jẹ ẹbun ṣe n kọrin ọpẹ, ti wọn n dawọọ idunnu, eyi ti yoo mori tiẹ naa wu. Lo oju opo yii: www.stanbicibtcbank.com lati mọ pupọ si i, tabi o le tẹle wa ni #Reward4Saving lori awọn ikanni ayelujara gbogbo.