Ṣaṣa eeyan ni yoo wo fidio ibi ti gbajumọ oṣere tiata, to tun maa n ṣiṣẹ aṣaraloge f’awọn oṣere (Make-up Artist) yii, Abilekọ Jumọkẹ George, ti n sunkun àsun-ùn-dá, to si n jẹ’rora gidi, bi o ṣe n ṣalaye ipọnju to n la kọja lọwọlọwọ, ti aanu abiyamọ ko nii ṣe onitọhun.
Ṣe Yooba bọ, wọn ni ibanujẹ nii dori agba kodò, ati pe ẹni ija ko ba nii pe ara rẹ lọkunrin, bẹẹ gan-an lọrọ ri ninu ifọrọwanilẹnuwo pajawiri kan ti oṣere tiata, to tun n ṣiṣẹ oniroyin ori ẹrọ ayelujara nni, Abiọla Adebayọ, ṣe fun Jumọkẹ, lori eto rẹ kan to pe ni “Talk to B” laipẹ yii
Lati ibẹrẹ ijiroro naa titi de ipari porongodo ni Jumọkẹ fi n sunkun, bẹẹ loo n laagun wọ̀rù, to si n kédàárò pe kawọn eeyan dide iranlọwọ si oun, ọrọ ti kọja ohun toun le mu mọra, oun ko si fẹẹ ku.
Biọla beere pe: “ki lo ṣẹlẹ gan-gan? Lati igba ti mo ti de, niṣe lẹ n sunkun, ki lo de?”
Niṣe lomije n da poroporo loju Jumọkẹ George bo ṣe n ṣalaye ara ẹ, o si han gbangba pe inu inira gidi lobinrin adumaadan tẹlẹri naa wa, o ni:
Adumaadan Jumọkẹ George ree, lasiko ọjọọbi rẹ lọdun 2024
Jumọkẹ ree lọsẹ to kọja nibi to ti n sunkun
Jumọkẹ ati Biọla
Jumọkẹ ree ati mama rẹ
“Lati January 2 lara mi o ti ya, ni mo ti n ṣàárẹ̀, mo dẹ ti gbiyanju gẹgẹ bii eniyan, mo ti sapa, ko s’ẹnikankan fun mi, gbogbo ayẹwo iṣegun pata ni mo ti ṣe.
Biọla tun beere pe: Kin ni nnkan to n ṣe yin gan-gan? Jumọkẹ si fesi pe: “Ti mo ba ni mo mọ ọn, irọ ni mo pa. Gbogbo ayẹwo ni mo ti ṣe. Tẹsiti (test) to tun kan ti mo fẹẹ ṣe nsinyii ni ti ọpọ ati ọkan (brain ati heart). Mi o kii sun, gbogbo ara maa n ni ọta mi ni, gbogbo nnkan lo n ṣe mi, ko ye mi mọ, ko ye mi. Ko dẹ sẹnikankan fun mi, ko si oluranlọwọ kan, mo ṣépè ẹ̀.
“Lati bii ọdun marun-un si mẹfa sẹyin, inu ṣọọṣi ni mo n gbe, ibẹ ni mo n sun, (lo ba nawọ si ẹgbẹ kan agbala ṣọọṣi Sẹlẹ ti wọn ti n sọrọ) wo o, ibi ti mo n gbe timutinu si lalẹ niyi, ti mo n sun! Nigba ti olufọrọwanilẹnuwo naa tun tọpa bọho lati mọ pato ibi ti ọrọ ti wọ wa ati ohun to ṣokunfa iriri buruku yii, Jumọkẹ ni: “Biọla, awọn nnkan kan wa to jẹ pe o maa n tiiyan loju lati sọ. Amọ mi o ni choice bayii, mo ni lati sọrọ, tori awọn eeyan naa aa da mi lẹbi pe ki lo de ti mio sọrọ sita.
“Lati bii ọdun marun-un si mẹfa sẹyin, inu ṣọọṣi ni mo n gbe, ibẹ ni mo n sun
“Ko si nnkan kan, mo n ṣiṣẹ loootọ, amọ iṣẹ yẹn ko da bii alara. Igba mi-in, o le jẹ ẹẹkan laaarin oṣu mẹrin, o si le jẹ ẹẹkan laarin oṣu mẹta, iyẹn ki n too ṣaisan. Nigba ti mo ti dubulẹ aisan yii, awọn eeyan ti pe mi si iṣẹ, amọ ilera mi o gbe e lati lọ, koda niṣe ni mo wa owo ya lati da owo awọn kan ti wọn ti san asansilẹ owo iṣẹ fun mi, ti mo si ti nawo sori aisan yii pada, nigba ti ko ṣee ṣe fun mi lati lọọ ṣiṣẹ wọn. Ara mi o ya.”
Iṣẹlẹ yii ya Biola Adebayọ lẹnu gidigidi
“Ẹyin abiyamọ aye, ẹ ṣadura fun mi, ẹ gba mi, mi o fẹẹ ku bayii, ko s’alaafia. Ọlọrun o, Ayeraye oo, ṣaaanu mi o.”
Nigba ti Biọla tun beere pe: “Aa, ki lo de tẹẹ sọrọ sita?” O ni itiju ni, oju lo n ti oun. O tun ṣalaye pe lati nnkan bii odun mẹrin loun ti n wa akọbi ọmọ oun obinrin, o ni oun ti nawo rẹpẹtẹ sori wiwa ọmọ to pe orukọ rẹ ni Adeola naa, ọdun yii lọmọ ọhun pe ẹni ọdun mọkanlelogoji. O loun ko mọ boya Libya tabi Malaysia lo wa. O ni gbese ti fẹrẹ gbe oun mi. Oun ti gbaawẹ titi, oun si ti gbadura titi gẹgẹ bii ọmọ Ijọ Sẹlẹ, oun si ti ṣe irapada titi, gbogbo ẹ ti waa fẹẹ su oun pata.
O ni “Ẹyin abiyamọ aye, ẹ ṣadura fun mi, ẹ gba mi, mi o fẹẹ ku bayii, ko s’alaafia. Ọlọrun o, Ayeraye oo, ṣaaanu mi o.” Bẹẹ ni Jumọkẹ George figbe bọnu pẹlu aṣọ Sutana Sẹlẹ to wa lọrun ẹ.