Orin ti Alaaji Ṣẹfiu Alao, JJC Ọmọ Oko kọ nigba kan pe, “wọn n gbe e bọ o, owo inu ọra, owo tabua,” o jọ pe orin naa lawọn ọjẹwẹwẹ obinrin agbabọọlu ilẹ wa bẹrẹ si i jo si lasiko yii, inu wọn si n dun bi wọn ṣe n yiraa ninu owo, tori bi ẹbun owo ṣe n wọle lọtun-un, bẹẹ lo n wọle losi fun wọn.
Eyi ko ṣẹyin bi awọn obinrin agbabọọlu ti ọjọ-ori wọn ko ju ọmọọdun mẹtadinlogun lọ, Nigeria Under-17 women’s team, ti wọn n pe ni Flamingos of Nigeria ṣe gbo ewuro soju awọn akẹgbẹ wọn lati orileede Algeria pẹlu ami-ayo mẹrin si òdo (4-0), ninu ifẹsẹwọnsẹ to waye lopin ọsẹ, ọjọ Abamẹta, Satide, ọjọ kọkandinlogun, oṣu Kẹrin ta a wa yii, ni papa iṣere Rẹmọ Stars Stadium, niluu Ikẹnnẹ, ipinlẹ Ogun.
Ifẹsẹwọnsẹ ọhun wa lara eyi ti wọn yoo fi mọ ẹgbẹ agbabọọlu ti yoo peregede lati kopa ninu idije fun ife-ẹyẹ agbaye FIFA U-17 Women’s World Cup, eyi ti ajọ FIFA ṣeto rẹ ti yoo waye lorileede Morocco ni ipari ọdun 2025 yii.
Afi bii pe ki rẹfiri fọn feere lawọn ọmọbinrin naa n duro de ni, ko tii pe iṣẹju kan ti ifẹsẹwọnsẹ bẹrẹ ni ọkan lara wọn, Philomena Isaiah gba bọọlu lati igun papa, eyi tawọn eleebo n pe ni corner kick, ẹsẹ Queen Joseph lo balẹ si, afi jua ninu awọn, o gba bọọlu naa kọja ọlọwọ ẹmu Algeria, Amelia Yahiaoui, n ni inu awọn ero iworan atawọn alatilẹyin ba n dun bi wọn ṣe n kọrin “ayo ayo ayo, ayo ayo!
Ko tun ju iṣẹju mejila lọ lẹyin naa, Shakirat Moshood gba bọọlu kan sọwọ iwaju, o de ọdọ Zainab Raji, ọmọbinrin naa si ge ege ara kọja awọn opomulero ọmọ Algeria meji, koloju si too ṣẹ ẹ, ami ayo keji ti duro.
Iṣẹju mẹrin lẹyin eyi, bọọlu kan de ọdọ Queen Joseph, ọmọbinrin yii si fi tagbara-tagbara gba a debi pe awọn ile Algeria mi titi fun goolu kẹta. Eyi ni wọn fi pari ipele akọkọ, ti wọn si fi bẹrẹ ipele keji lẹyin isinmi ranpẹ, bo tilẹ jẹ pe awọn agbabọọlu Algeria naa ta biọ-biọ, wọn fẹẹ da gbese yii pada, sibẹ igbiyanju wọn ko seso rere pẹẹ, nitori bo ṣe ku dẹdẹ ki ifẹsẹwọnsẹ ọjọ naa pari, ọdọmọbinrin ẹlẹsẹ ayo kan, Aishat Animashawun gba bọọlu kẹrin sawọn, lo ba di 4-0, rẹfiri si fọn feere pe ere ti pari.
Aṣeyọri yii wọ Alaga ajọ to n ri si ere bọọlu alafẹsẹgba nilẹ wa, Nigeria Football Federation, NFF, Oloye Ibrahim Gusau lọkan, o si mori rẹ wu debi pe ẹbun owo miliọnu meji naira lo kede rẹ fawọn Flamingos.
Amọ ọkunrin to fẹran bọọlu alafẹsẹgba gidi nni, to jẹ oludasilẹ ati alakooso ikanni Bet9ja, Ọgbẹni Kunle Soname, ni miliọnu meji kere, o kede pe oun fi miliọnu mẹrin kun un fawọn agbabọọlu naa, tori ẹni amuyangan ni wọn.
Bayii lawọn ọmọbinrin naa n fo fayọ bi wọn ti n gbọ itasansan miliọnu mẹfa nairah, ti wọn si n gbaradi fawọn ifẹsẹwọnsẹ yooku.