Agbefọnranjade l’ori ayelujara Habeeb Hamzat ti ọpọ eeyan mọ si Peller lo ti f’oruka s’ọwọ ọrẹbinrin ati agbefọnranjade l’ori ayelujara ẹgbẹ rẹ Amadou Elizabeth Aminata ti inagijẹ rẹ n jẹ Jarvis pẹlu bi awọn kan ṣe n sọ lọrọ ẹyin pe o ti loyun.
Nigba to n fi fọnran ayẹyẹ ifuniloruka to waye lorilẹede Ghana naa sori itakun ibanidọrẹ Instagram rẹ lo ti yan firi pe igbeyawo awọn ku dẹdẹ.
Nibi awile fọnran naa lo ti ni bayi l’oun ati Jarvis o ṣe bẹrẹ irin-ajo titi laye nitori o ti gba lati fẹ oun gẹgẹ bi ọkọ. O ṣapejuwe Jarvis gẹgẹ bii aanu to tobi ju laye rẹ ati ibi isadi fun.
Ni awọn ọsẹ diẹ sẹyin ni Peller fi fọnran kan sita to n ṣafihan Jarvis nibi to ti n ṣe ayẹwo inu to si n yan firi pe awọn n reti ọmọ tuntun laipẹ yii.
Awọn agbefọnranjade l’ori ayelujara mejeeji ni wọn bẹrẹ irin-ajo ifẹ wọn lori itakun ibanidọrẹ Tiktok ni ọdun 2024 bi o tilẹ jẹ pe ọpọ igba ni ija ti bẹẹ lẹ laarin wọn.
Ti ẹ o ba gbagbe, inu oṣu kini ọdun yii ni awọn mejeeji ja ajatuka kan leyi to tan kiri lori ayelujara ko to di pe wọn pari rẹ lẹyin igba diẹ.
Ni bayi, ọpọ awọn ololufẹ wọn lori ayelujara ni wọn ti b’awọn dawọ idunnu ti wọn si n gba l’adura pe ifẹ wọn a dalẹ.