Eyi Ni Bi VeryDarkMan Se Di Oloye Lafin Oluwo Iwo

Eyi Ni Bi VeryDarkMan Se Di Oloye Lafin Oluwo Iwo

Bi eeyan ba gun ẹṣin ninu awọn ti wọn pe ni “Ratel” iyẹn ẹgbẹ awọn alatẹle abi ọmọlẹyin gbajugbaja ajafẹtọ to tun jẹ irawọ ori ayelujara, Martin Vincent Otse ti gbogbo aye mọ si VDM abi VeryDarkMan, ẹṣin naa ko ni kọsẹ rara. Kosi ohun to fa eyi ju ẹbun oore rabantẹ kan to wọ’le wẹrẹ fun ọga wọn, VDM lọ.

 

Ṣebi ṣadede la kan gburo pe ọkunrin VDM yii ti wa ni igboro ilẹ Iwo ni ipinlẹ Ọṣun, eyi gan-an kuku kọ ni kayefi ibẹ nitori ọkunrin VDM yii ko ṣẹ ma rin irin-ajo kiri nitori iṣẹ ijangbara ati ijafẹtọ to n ṣe. Amọ ṣa, lojiji la ba tun gbọ pe VDM ti wa ni aafin Oluwọ ti ilẹ Iwo, l’ọdọ Ọba Abdulrasheed Adewale Akanbi, Telu Keji, ni gbogbo aye ba bẹrẹ si ni m’efo. VDM to jẹ ilumọọka pẹlu Ọba Oluwo t’oun naa jẹ ilumọọka ati wọkilumọ ọba, dajudaju ọrọ naa gbọdọ l’apẹẹrẹ.

Ka to ṣẹ’ju pẹ, wọn ni oye ni VDM wa jẹ l’ọdọ Oluwo, bi ere bi awada, ọrọ naa ma di ootọ, l’oju gbogbo aye, ni’waju ero to lọ bi esu, ni Ọba Adewale Akanbi, Oluwo ti ilẹ Iwo ti fi VeryDarkMan jẹ oye Atayeṣe gbogbo Naijiria.

Ninu ọrọ Oluwo, kabiesi ni “Mo fẹ kẹ mọ pe ẹ ti ni ọba alaye kan l’aarin yin, nitori emi naa ti di ara yin ni ninu ẹgbẹ Ratel Movement tẹ n ṣe yẹn. VDM awọn iṣẹ takuntakun lati fọ awujọ mọ to n ṣe lo wu mi l’ori. Mo wa fẹ gbe iṣẹ fun ọ lati ba wa ṣa ẹṣa ninu awọn iwa ati aṣa wa, l’ojuna ati ṣa awọn eyi to ba buru kuro ninu wọn.”

Oluwo tun tẹsiwaju pe “iṣẹ atunloto tẹ kuku n ṣe dara gidi gan, bẹẹ ti n ja f’ẹtọ awọn eeyan ati fun idajọ ododo, gbogbo rẹ lo dara lootọ. Amọ ṣa, mo tun fẹ kẹ mu oṣelu mọ, kẹ ma kan ṣe gbogbo igbiyanju yin l’ofo, nitori iṣẹ itunluto nilo agbara, ẹni ti yoo ba fọ ilu mọ nilo agbara pẹlu, fun idi eyi mo fẹ kẹ mu oṣelu mọ ohun tẹ n ṣe.”

Ni’gba ti VDM yoo ma s’ọrọ, ọga ẹgbẹ Ratel Movement gb’oṣuba fun Oluwo lo f’esi pe “kabiesi, kẹ to wi, awa naa ma ti n d’ọgbọn wọ’nu oṣelu diẹ diẹ, bẹẹni, amọ o, pẹlẹpẹlẹ bayii la wa n mu. To ba ya, a o ko ẹgbẹ oṣelu wa jọ, ta o si gbe l’arugẹ de’bi ti o ti ma fa awọn oludije ti wọn ṣe e f’ọkan tan ninu wa si’lẹ fun ipo oṣelu. Amọ ṣa, ẹ fun wa l’akoko diẹ si.”

Ẹwẹ, VDM o ṣai tọ’ka si pe ni t’oun, oun o l’ero lati di ipo oṣelu kankan mu ni pato ṣugbọn ti oun yoo tunbọ fi ọrọ naa ṣe iṣẹ ṣe.

Bẹẹ o ba gbagbe VDM ni Oluwo kesi bi ẹnu ijọ mẹta kan pe ọba yoo n’ifẹ lati gbalejo rẹ, ki gbogbo eyi to wa’ye yii o to tẹle.

Leave a Comment

Your email address will not be published.

Start typing and press Enter to search