Purofẹsọ GehGeh De Pada Lẹyin Igbeyawo Ẹ! Ẹ Wa Gbọ Ohun To Sọ

Purofẹsọ GehGeh De Pada Lẹyin Igbeyawo Ẹ! Ẹ Wa Gbọ Ohun To Sọ

Ṣe wọn ni arambara ni aṣọ ọga, gẹlẹ bẹẹ gan-an ni ọrọ Purofẹsọ GehGeh ri.

Emmanuel Obruste ti gbogbo aye n pe ni GehGeh leyin igbeyawo onisọnu to ṣe, t’okiki rẹ kan ka’ye lo ti ja’de wa ba awọn ọmọ Naijiria s’ọrọ.

Ojumọ kan ara kan naa kuku ni ọrọ GehGeh, gbajumọ ori ayelujara naa tẹlẹ ṣugbọn t’ọtẹ yii tun le kanka.

Dide ti GehGeh de pada, ẹbẹ lo mu bọ’nu pe k’awọn aye darijin oun nitori igbeyawo to ṣe to si jẹ pe oun gan-an lo ma n kọ awọn ọkunrin lati ma jẹ ki wọn fi igbeyawo tan wọn wọ panpẹ abo.

Eeyan o ṣe bi ootọ ni ẹbẹ yii ni, amọ ṣa ọrọ ti f’oju han o, okodoro ọrọ si ti ja’de. GehGeh o ṣe igbeyawo kankan, gbogbo awọn aworan ati fọnran lo lu igboro pa to si da alaimọye awuyewuye silẹ lo pada f’oju han pe ere agbelewo l’asan ni GehGeh ati ọmọbinrin kan ti jọ n ṣe igbeyawo, kii ṣe ojuaye.

Ko wa tan si’bẹ, GehGeh ni, gbogbo awọn to bu ẹnu atẹ lu oun ni o lo’ye, bi bẹẹ kọ, wọn o ba fi oye gbe. O ni oun kii ṣe ẹlẹnu meji ẹda, bẹẹ ọrọ oun ati ihinrere ko yi pada pe k’awọn ọkunrin jinna si igbeyawo nitori ọgbọn ati sọ wọn d’ẹru abo ni. O tẹsiwaju wa bi ọkunrin kankan ba wa fẹ ṣe igbeyewo ni dandan, o gbọdọ jẹ oniyawo pupọ nitori ewu ki obinrin ma ja si ọlọpọn.

GehGeh o m’ẹnu duro rara, o ni kosi ohun t’eeyan le ṣe to ma tẹ ọmọ araye l’ọrun nitori tẹlẹ-tẹlẹ ariwo pe oun ko ṣe igbeyawo ri ko jẹ ko ni oye bi tii ri lo fi n ṣe awọn iponlogo pe ki akọ ṣọra l’ọdọ abo. GehGeh ni ṣi yẹ ki ọrọ d’ariwo nigba ti wọn gbọ iroyin igbeyawo ni’pa oun pe bo ba ṣe pe iriri igbeyawo ni oun fẹ fi wa nkọ.

O wa fi kun pe oun ko fi igba kankan sọ pe oun ko fẹran abo o, bi bẹẹ kọ, oun o ni ni awọn iya-ọmọ ìyẹn baby-mama mẹrin ati meji miiran to l’oyun si’nu. O ni oun ti oun mọ ni pe igbeyawo ko dara f’ọkunrin ṣugbọn ẹni ba fẹ ṣe o gbọdọ ṣetan ati di ọkọ alaya-pupọ lati lee daabobo ara rẹ l’ọwọ ọṣẹ obinrin.

Lo ba tun lo anfaani naa lati ni ki awọn akẹẹkọ ti oye wọn ko ba to lati gbe ẹkọ oun ni GehGeh University iyẹn fasiti ti GehGeh da silẹ lati tete yago.

Ni bayii, ọrọ ti pọ lọ ṣalalu nipa GehGeh ati dide pada rẹ. Awọn kan n pe aif’ẹlẹ ke’bosi lo n jẹ ki eeyan pe ẹyẹ oko n paate, wọn ni b’eeyan ba f’ara ba’lẹ gbọ ihinrere GehGeh, eeyan o ri pe o ṣe deede ọgbọn. Bẹẹ l’awọn miiran taku jalẹ tan pe aj’egbodo l’asan ni  Purofẹsọ GehGeh ti n wa ẹni kunra lati ṣi l’ọna, pe ika abamọ nla ni awọn to ba n ka ọrọ rẹ kun yoo pada ti bọ ẹnu.

Leave a Comment

Your email address will not be published.

Start typing and press Enter to search