Haaa, O Ma Ṣe O, Ṣẹ Ti Gbọ Ohun Ti Wọn Lo Ṣẹlẹ S’Ogogo Onitiata, Kini Naa O Da Rara

Haaa, O Ma Ṣe O, Ṣẹ Ti Gbọ Ohun Ti Wọn Lo Ṣẹlẹ S'Ogogo Onitiata, Kini Naa O Da Rara

Koda bi eniyan ba jẹ ori ahun, ẹkun a gbọn onitọhun bo ba ri fọnran iyẹn fidio ti ọmọ ogbontarigi oṣere Taiwo Hassan ti ọpọ mọ si Ogogo ṣe, to si tun fi si’ta l’ori ayelujara.

Ọkan ninu awọn ọmọ Ogogo l’obinrin ti wọn n pe ni Kira, t’oun naa jẹ irawọ amuludun t’ogo rẹ ti n bu yọ lo ma fi iroyin agbọyọ’mul’oju si’ta ni’pa baba rẹ.

Pẹlu omije to le roro s’oju ti ẹ naa l’oun naa fi s’ọrọ naa f’aye gbọ. Kira ni baba oun iyẹn Ogogo ọmọ Kulodo lo ma ni aisan jẹjẹrẹ iyẹn ‘cancer’ ti kini naa si ti wọ ọ l’ara gidigidi, koda ipele kẹrin iyẹn ‘stage 4’ to fẹ pelemọ julọ ni baba awọn wa.

Kira ni ko tii ju bi ọsẹ mẹta lọ bayii t’awọn ti ẹ mọ pe nnkan kan n ṣe gbajumọ oṣere naa to jẹ baba awọn, t’oun si ri l’oju Ogogo pe ko ṣetan lati ku bayii.

O ṣ’alaye pe itọju ni awọn n wa l’oju mejeeji bayii ni’bikibi t’awọn ba ri si, i ba ṣe ti oloyinbo abi ti ibilẹ, ki baba awọn ṣa ti gbadun. K’ara Ogogo sa ti ya.

O ni awọn o fi Ogogo tọrọ owo rara nitori awọn n ri bukata naa gbọ ati pe Aṣofin-Agba iyẹn ‘Senator’ Ọlamilekan Adeọla Yayi lati ipinlẹ Ogun lo ti n k’owo ka’lẹ lati igba yi, to si tun ṣetan lati na’wo na’ra si. Fun idi eyi, iwosan lasan l’awọn nilo t’awọn si n beere fun, ẹni ba le ṣaanu awọn.

Kira tun tẹsiwaju pe, kii ṣe iku Ogogo gan-an l’oun ba oun l’ẹru bi ko ṣe pe baba oun fun’ra rẹ si n fẹ lati gb’aye. Ogogo o ti fẹ lọ!

Lati igba ti fọnran ọmọ Ogogo yii ti ja’de, n ṣe ni ọgọrọ awọn eniyan kan n ka ọrọ naa s’ara. Aladura n ṣe ti ẹ, awọn olowo ni bo ba s’owo ni, awọn ṣetan, ko tun mọ t’awọn alaanu to kan n kẹdun latọọkan pe o ṣe wa le jẹ pe Ogogo ti Oluwa ti lo lati mu inu araye dun lo n la asiko idanwo nla yii kọja. K’ori jẹ ki a tun pada gburo ayọ n’ipa Ogogo, k’aburu ma dẹ ṣe ẹnikọọkan wa.

 

Leave a Comment

Your email address will not be published.

Start typing and press Enter to search