Akojọpọ ẹwà, aṣa ati oge ilẹ Yoruba lagbo ere idaraya l’Abẹokuta

Titi di ba a ṣe n sọ yii, ojumọ kan, ara kan, ere idaraya oriṣiiriṣii lo n lọ lọwọ ni papa iṣere Moshood Abiola Stadium to wa niluu Abẹokuta, ni ipinlẹ Ogun.

Ẹ o ranti pe lati ọjọ kẹrindinlogun, oṣu Karun-un, ọdun 2025 yii ni idije ọlọkan-o-jọkan ti n waye niluu Abẹokuta, ni papa iṣere ti wọn fi ṣe ojuko ere idaraya apapọ ilẹ wa, eyi ti wọn n pe ni National Sports Festival lede gẹẹsi. Ipinlẹ Ogun lo gbalejo awọn ipinlẹ yooku ti wọn n kopa ninu idije ọlọdọọdun naa, lọdun yii, ọsẹ meji si ni wọn yoo fi dabira loriṣiiriṣii nibẹ.

Lati ọjọ kẹrindinlogun ti wọn ti ṣide eto naa ni bẹbẹ ti n waye ni papa iṣere nla ọhun ati ayika rẹ, koda igboro ilu Abẹokuta paapaa mọ ọn lara pe awọn alejo wọlu, nitori ọrọ aje ati karakata ru gọgọ si i, ka ma ṣẹṣẹ sọ ti lilọ bibọ ọkọ ati oniruuru iran, aṣa, oge ati ẹwa to n ṣẹlẹ layiika sitediọmu naa.

Gomina ipinlẹ Ogun, Ọmọọba Dapọ Abiọdun lo gba gbogbo awọn ololufẹ ere idaraya, atawọn eeyan pataki pataki nipinlẹ Ogun ati kaakiri orileede yii titi kan awọn ti wọn wale lati oke okun lalejo.

Diẹ lara awọn iran arimaleelọ to ti waye nibẹ ni ti titan ina iṣọkan, Unity Torch, ti wọn fi ṣide ajọdun naa, aṣọ ẹgbẹjọda ti wọn sami ajọdun ere idaraya si tawọn gomina ilẹ Yoruba ati igbakeji aarẹ ilẹ wa, Kashim Shettima wọ, Davido olorin hipọọpu taye n fẹ to ṣere lọjọ akọkọ, awọn onilu, awọn olorin ibilẹ, awọn ẹlẹgbẹjẹgbẹ ati afẹwapawo gbogbo, ti wọn da bira lati ọjọ kinni titi di ba a ṣe n sọ yii.

Awọn ọlọja naa ko gbẹyin, o fẹrẹ ma si nnkan ibilẹ nipinlẹ Ogun ti ko si layiika gbọngan naa, eegun jo, agere ṣere, imura ati iwọṣọ loniran-iran, awọn to n ta aṣọ adirẹ, kampala, aṣọ ofi, ilẹkẹ, fila ati nnkan ọṣọ loriṣiiriṣii.

Ara ọtọ ni bi wọn ṣe pa ilu Abẹokuta laro tuntun, ti wọn ku awọn ọna ati ayika sitediọmu naa lọda, ti wọn si ṣe ọṣọ ati ẹwa si i.

O daju pe manigbagbe ni eto ajọdun ere idaraya to n lọ lọwọ yii lasiko iṣejọba Dapọ Abiọdun, ayẹyẹ to fitan balẹ gbaa ni! 

Leave a Comment

Your email address will not be published.

Start typing and press Enter to search