Kii ṣe iroyin tuntun mọ bayii pe Igbakeji Aarẹ orileede Naijiria tẹlẹri, Alaaji Atiku Abubakar ti pin gaari pẹlu ẹgbẹ oṣelu rẹ, Peoples Democratic Party, PDD, o si ti kọwe pataki kan si wọn lati sọ lati sọ fun wọn pe oun ṣe ẹgbẹ naa mọ, oun si ti yọ ara oun kuro lara ọmọ ẹgbẹ oṣelu wọn.
Ṣe ọmọ tuntun kii ṣe àkọ́pa àjẹ́, eyi ni igba kẹta ti Atiku yoo kọ iru lẹta ‘ẹ maa gbe kẹ̀kẹ́ yin lọ, mi o ba yin ṣere mọ’ bii eyi si ẹgbẹ oṣelu ọhun, ohun to si n ṣe ọpọ eeyan ni kayeefi ree, ti wọn fi n beere idi ti baba agbalagba naa ko fi ri idi jokoo bii ọmọri igba sinu ẹgbẹ oṣelu kan.
Lọtẹ yii, ninu lẹta to kọ ni ọjọ kẹrinla, oṣu Keje, ọdun 2025 yii, eyi ti ẹda rẹ tẹ iweeroyin ITAFAAJI lọwọ, Waziri Adamawa, iyẹn oye pataki ti Atiku jẹ nipinlẹ Adamawa to ti wa, o sọ pe idi toun fi di igba di agbọn oun kuro lẹgbẹ oṣelu PDP ni pe ẹgbẹ oṣelu naa ti bẹrẹ si i gbe igbesẹ kan bayii to tako igbagbọ ati erongba oun, bẹẹ si ni oun ko nifẹẹ si awọn ilapa ọna ti ẹgbẹ naa n fẹẹ gun le lasiko yii.
Ṣe ko kuku sẹni ti ko mọ pe ọkan gbogi ninu ifẹ-ọkan ọkọ Titilayọ, ana wọn niluu Ileṣa, ipinlẹ Ọṣun, ni lati di Aarẹ orileede yii, o si ti wa lẹnu ijija-dupo Aarẹ ọhun fungba pipẹ, koda o fẹrẹ jẹ oun ni oloṣelu torukọ rẹ ṣi wa lakọọlẹ itan orileede gẹgẹ bii ẹni to tii dije-dupo aarẹ julọ, o ṣetan, Yoruba bọ, wọn ni ohun to ba n dun’ni nii pọ lọrọ ẹni, ologun ẹru ku, aṣọ rẹ jẹ ọkan ṣoṣo.
Amọ yatọ si ti ọrọ didi olori orileede, ITAFAAJI fidi rẹ mulẹ pe idi miiran ti Alaaji Atiku Abubakar tun fi dagbere fun ẹgbẹ oṣelu PDP ni pe, oun ati awọn eekan eekan alẹnulọrọ ninu oṣelu lapa Oke-Ọya ilẹ wa ti pinnu lati sopanpa de Aarẹ Bọla Ahmed Tinubu, ki wọn si gbegi dina fun un lati wọle sipo aarẹ fun saa keji rẹ ninu eto idibo ti yoo waye lọdun 2027.
Wọn ni gbogbo eto iṣejọba Bọla Tinubu lo tako ifẹ-ọkan awọn eeyan Oke-Ọya, wọn ko si fẹ ki baba naa lo kọja ọdun mẹrin to ti lo meji ninu rẹ yii, pẹlu ibẹru pe niṣe ni nnkan yoo tubọ buru si i ti Tinubu ba fi raaye ṣe saa keji.
Amọ ṣa o, awọn to mọ bo ṣe n lo lagbo oṣelu ti n sọ pe ko sohun ti yoo pọn Atiku le ju ko ṣe Baba Isalẹ fun ẹgbẹ oṣelu yoowu to ba pinnu lati darapọ mọ lọ, dipo didupo aarẹ, nitori ọjọ-ori ati kadara rẹ. Sibẹ awọn mi-in, paapaa awọn to fẹran baba naa sọ pe asiko yii gan-an lo maa larinrin ju fun un lati dupo aarẹ, nitori Aarẹ ana, Ajagunfẹyinti Muhammadu Buhari tero pọ lẹyin rẹ bii iyanrin nilẹ Hausa ti ku, ko si tun sẹni to laami laaka lagbo oṣelu to Alaaji Atiku, ba a ba ti yọwọ ti Buhari kuro, gẹgẹ bi wọn ṣe wi.