Ẹ Fi T’emi Kọ’gbọn, Idi Ṣiṣe (BBL) Lasan O L’ere – Olaide Oyedeji

Ẹ Fi T'emi Kọ'gbọn, Idi Ṣiṣe (BBL) Lasan O L'ere - Olaide Oyedeji

Irawọ oṣere tiata l’ede Yoruba, Olaide Oyedeji to ti fi oke-okun ṣe ile lati bi ọdun diẹ s’ẹyin lo ti ja’de si gbangba wa sọ f’awọn obinrin pe ki wọn fi ọrọ oun ṣe arikọgbọn lati ma lọ fi owo ṣe idi atọwọda ti wọn n pe ni BBL, eleyi t’ọpọ awọn obinrin isẹyin ti k’aṣa rẹ, to si ti di aarun to fọnka’ye.

Ninu fọnran kan ti oṣere yii, Olaide ju si’ta l’ori ayelujara lo ti ni bi obinrin kankan ba lọ fi kun idi rẹ abi to tun-un mọ ko le wọ’ju, ko arimaleelọ pẹlu erongba pe awọn ọkunrin yoo ma ku le l’ori, ti wọn yoo si ma k’owo le, Ọlaide ni iroyin ijakulẹ ni oun ni fun iru wọn nitori ko ni pẹ ti onitọhun yoo fi ki ika abamọ b’ẹnu.

O tẹsiwaju pe o san ki wọn fi t’oun ṣe arikọgbọn nitori oun naa ṣe idi ṣugbọn to jẹ pe oun ṣe tan k’oye to ye oun pe ohun to n bẹ lẹyin’kule obinrin nikan kọ lo nilo lati ṣ’aye l’aṣeye.

Ọlaide ni lootọ bi obinrin ba ṣe idi a ma mu ẹwa obinrin ja’de daadaa, a si tun ma a fa awọn ọkunrin l’oju mọ’ra daadaa ṣugbọn ti gbogbo nnkan o pin si’bẹ yẹn.

 

O ṣ’alaye siwaju pe bo ba ṣe pe idi nikan ni obinrin gb’oju le lai ni ohunkohun bi ẹbun abi ọpọlọ, o ni awọn ọmọ yahuu to le fi’yan gun’ṣẹ ọla at’awọn alainikan ṣe miiran ni yoo kun iwaju rẹ ti wọn yoo ma yọ ọ l’ẹnu, ti wọn a si fi ti’bi su daadaa ṣugbọn ti ko ni si ohun gidi kan ti yoo ti ibẹ ja’de wa.

O wa fi ara rẹ ṣ’apẹrẹ pe lati bi ọdun meta sẹyin l’oun ti da wa, ti kii dẹ ṣe pe oun o r’eeyan pe oun ṣugbọn to jẹ pe awọn alainikanṣe lo pọju. O ni awọn ara iṣaaju ti ṣi awọn l’ọna pe onidi lo l’aye ṣugbọn t’oun gba awọn to n bọ l’ẹyin pe ọrọ aye ju idi l’asan lọ. O wa yan pe bi obinrin ba ṣe igbelarugẹ ẹwa rẹ, boya o ṣe idi abi ọna miiran, to tun wa ni ọpọlọ kun pe ko ni pẹ ti yoo fi go’ke, ti yoo si r’ọwọ mu. O l’oun ti Kọ’gbọn pe ṣiṣe igbelarugẹ ẹwa kan jẹ igbesẹ kan l’oju ọna ati la ni kii ṣe pe ori rẹ lo pin si.

Leave a Comment

Your email address will not be published.

Start typing and press Enter to search