Oṣere Nollywood nni, Ọlarenwaju Omiyinka, ti ọpọ mọ si Baba Ijesha, ni wọn ti da si’lẹ l’ọgba ewọn bayi tẹle idajọ ile-ẹjọ ko-tẹ-mi-lọrun eyi to yọ okun ẹbi ẹsun ṣiṣe ohun kotọ pẹlu majesin (sexual assault of a minor) kuro l’ọrun Baba Ijẹṣa.
Oṣere naa ni wọn fi kele ofin gbe ni ọdun 2021 ti ile-ẹjọ giga ipinlẹ Eko to n bẹ ni Ikẹja ninu oṣu keje ọdun 2022 (July 2022) si da l’ẹjọ ẹwọn ọdun mẹrindilogun (16 years jail term) fun jijẹbi ẹsun ṣiṣe aṣemaṣe pẹlu majesin ọmọ ọdun mẹrinla (14 years old) kan.
Ninu fọnran kan to n ja ranyin bayii la ti ri oṣere alawada naa to jokoo si’nu ọkọ kan lọgan lẹyin to bọ ni ọgba ẹwọn lat’ari idajọ ile-ẹjọ, ni Baba Ijẹṣa n pe oun nilo l’ati kọkọ m’ara le’lẹ, f’ara ni’sinmi.
Oṣere naa n sọ ọrọ yii ninu fọnran naa l’asiko to wa l’ori aago to n ba ẹni kan s’ọrọ the clip, laarin ipe naa ni ede Yoruba lo ti n pe, ”Apaṣẹ, mo ti ja’de o… Mo ṣẹṣẹ ja’de ni o.
Mo fẹ mu ara le’lẹ. Mo ṣẹṣẹ kuro n’ibi ni mo ni ki n bun yin gbọ. Ẹ ṣeun, ẹ ku aduroti mi o. Ma pe yin.”
Oṣere Nollywood miran to tun ajaf’ẹtọ, Yọmi Fabiyi, f’ara mọ idajọ ile-ẹjọ ko-tẹ-mi-lọrun naa ninu atẹjade kan to ṣe l’ori opo ikanni rẹ to ti pe, idajọ tuntun yii ti fi okodoro ọrọ han l’ori ẹjọ to ti kọkọ d’ojuru. Fabiyi idajọ ile-ẹjọ ko-tẹ-mi-lọrun yii ti wẹ Baba Ijẹṣa mọ l’ori ẹsun naa, to si tun rọ awọn eleto ati ara ilu lati maa fi ẹlẹ ṣe l’ori awọn ọrọ to ba gb’ẹgẹ bi iru eyi. Ọkunrin naa ni kii ṣe pe Baba Ijẹṣa dari de pada l’asan ṣugbọn to de daadaa si.
Awuyewuye ọrọ yii lo tun lọ ni’gboro bayii. Bi awọn kan ti yọ’nu si idajọ tuntun yii ni awọn miran n pe idajọ naa ko ba awọn rẹ. Gbogbo komi, Baba Ijẹṣa ti pada ri itusilẹ kuro l’ọgba ewọn lat’ari aṣẹ ile-ẹjọ.