Gbajugbaja onkọrin lati Colombia, Shakira ti ṣalaye idi to ṣe jẹ onkọrin orilẹ-ede Naijiria to ti gba ami-ẹyẹ agbaye Grammy, Burnaboy lo yan lati jọ kọrin pọ fun ẹyẹ ligii agbaye FIFA ti ọdun yii.
Nigba to n ṣalaye idi nibi ifọrọwanilẹnuwo kan, o ni oun nilo ohun ọkunrin lori orin naa, ohun Burnaboy gan dẹ lo ba nkan t’oun fẹ lọ.
O fi kun pe o ti pẹ t’oun ti nifẹ Burnaboy, o si ti wa l’okun aya oun lati kọrin pẹlu rẹ l’oun ṣe pe si orin naa.
Onkọrin naa ni oun o le ronu ẹlomii lori orin naa yatọ si Burna.
Orin naa ti akori rẹ jẹ Dai Dai lo ti fọ ọpọlọpọ awọn akọsilẹ agbaye latigba ti wọn ti fi sita. Eyi ti jẹ ki Burnaboy jẹ onkọrin alakọkọ lati ilẹ Afrika lati lewaju lori atẹ orin Apple l’agbaye ati awọn ọpọ awọn idamọ mii.
Orin yii kan-naa lo jẹ ki Burnaboy jẹ onkọrin ilẹ Afrika akọkọ lati kọrin nibi ẹyẹ ligii agbaye FIFA.